Iṣe Apo 10:1-2
Iṣe Apo 10:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
ỌKUNRIN kan si wà ni Kesarea ti a npè ni Korneliu, balogun ọrún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ti a npè ni ti Itali, Olufọkansìn, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹniti o nṣe itọrẹ-ãnu pipọ fun awọn enia, ti o si ngbadura sọdọ Ọlọrun nigbagbogbo.
Iṣe Apo 10:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ọkunrin kan wà ní Kesaria tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọniliu. Ó jẹ́ balogun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ tí à ń pè ní Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Itali. Olùfọkànsìn ni. Òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rù Ọlọrun. A máa ṣàánú àwọn eniyan lọpọlọpọ, a sì máa gbadura sí Ọlọrun nígbà gbogbo.
Iṣe Apo 10:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo.