Iṣe Apo 1:6-11
Iṣe Apo 1:6-11 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina nigbati nwọn si pejọ, nwọn bi i lere pe, Oluwa, lati igbayi lọ iwọ ó ha mu ijọba pada fun Israeli bi? O si wi fun wọn pe, Kì iṣe ti nyin lati mọ̀ akoko tabi ìgba, ti Baba ti yàn nipa agbara on tikararẹ̀. Ṣugbọn ẹnyin ó gbà agbara, nigbati Ẹmí Mimọ́ ba bà le nyin: ẹ o si ma ṣe ẹlẹri mi ni Jerusalemu, ati ni gbogbo Judea, ati ni Samaria, ati titi de opin ilẹ aiye. Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, bi nwọn ti nwò, a gbé e soke; awọsanma si gbà a kuro li oju wọn. Bi nwọn si ti tẹ̀jumọ́ oju ọrun bi o ti nrè oke, kiyesi i, awọn ọkunrin meji alaṣọ àla duro leti ọdọ wọn; Ti nwọn si wipe, Ẹnyin ará Galili, ẽṣe ti ẹ fi duro ti ẹ nwò oju ọrun? Jesu na yi, ti a gbà soke ọrun kuro lọwọ nyin, yio pada bẹ̃ gẹgẹ bi ẹ ti ri i ti o nlọ si ọrun.
Iṣe Apo 1:6-11 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan tí gbogbo wọn péjọ, wọ́n bi í pé, “Oluwa, ṣé àkókò tó nisinsinyii tí ìwọ yóo gba ìjọba pada fún Israẹli?” Ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe tiyín láti mọ àkókò tabi ìgbà tí Baba ti fi sí ìkáwọ́ ara rẹ̀ nìkan ṣoṣo. Ṣugbọn ẹ̀yin yóo gba agbára nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé yin. Ẹ óo wá máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo Judia ati ní Samaria ati títí dé òpin ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, bí wọ́n ti ń wò ó, a gbé e sókè, ìkùukùu bò ó, wọn kò sì rí i mọ́. Bí wọ́n ti tẹjú mọ́ òkè bí ó ti ń lọ, àwọn ọkunrin meji tí wọ́n wọ aṣọ funfun dúró tì wọ́n. Wọ́n ní, “Ẹ̀yin ará Galili, kí ló dé tí ẹ fi dúró tí ẹ̀ ń wòkè bẹ́ẹ̀? Jesu kan náà, tí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, lọ sí ọ̀run yìí, yóo tún pada wá bí ẹ ṣe rí i tí ó ń lọ sí ọ̀run.”
Iṣe Apo 1:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà, nígbà tí wọ́n sì péjọpọ̀, wọn bi í léèrè pé, “Olúwa, láti ìgbà yí lọ ìwọ yóò ha mú ìjọba padà fún Israẹli bí?” Ó sì wí fún wọn pé, “Kì í ṣe tiyín ni láti mọ àkókò tàbí ìgbà tí Baba ti yàn nípa àṣẹ òun tìkára rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò gba agbára, nígbà tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé e yín: ẹ̀yin yóò sì máa ṣe ẹlẹ́rìí mi ni Jerusalẹmu, àti ní gbogbo Judea, àti ní Samaria, àti títí dé òpin ilẹ̀ ayé.” Nígbà tí ó sì tí wí nǹkan wọ̀nyí, a gbà á sókè lójú wọn; ìkùùkuu àwọsánmọ̀ sì gbà á kúrò lójú wọn. Bí wọ́n sì ti tẹjúmọ́ ojú ọ̀run bí ó ti ń lọ sókè, lójijì, àwọn ọkùnrin méjì tí ó wọ aṣọ funfun dúró létí ọ̀dọ̀ wọn. Wọ́n sì wí pé, “Ẹ̀yin ara Galili, èéṣe tí ẹ̀yin fi dúró tí ẹ̀ ń wo ojú ọ̀run? Jesu yìí, tí a gbà sókè ọ̀run kúrò lọ́wọ́ yín, yóò padà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí tí ó ń lọ sì ọ̀run.”