II. Tim 4:3-4
II. Tim 4:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan.
II. Tim 4:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn. Wọn óo di etí wọn sí òtítọ́; ìtàn àhesọ ti ara wọn ni wọn yóo máa gbọ́.
II. Tim 4:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán.