II. Tim 4:2-5
II. Tim 4:2-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Wasu ọ̀rọ na; ṣe aisimi li akokò ti o wọ̀, ati akokò ti kò wọ̀; baniwi, ṣe itọ́ni, gbà-ni-niyanju pẹlu ipamọra ati ẹ̀kọ́ gbogbo. Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan. Ṣugbọn mã ṣe pẹlẹ ninu ohun gbogbo, mã farada ipọnju, ṣe iṣẹ efangelisti, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe.
II. Tim 4:2-5 Yoruba Bible (YCE)
Waasu ọ̀rọ̀ náà. Tẹnumọ́ ọn ní àkókò tí ó wọ̀ ati àkókò tí kò wọ̀. Máa báni wí. Máa gbani ní ìyànjú. Máa gbani ní ìmọ̀ràn, pẹlu ọpọlọpọ sùúrù tí ó yẹ kí ẹni tí yóo bá kọ́ eniyan lẹ́kọ̀ọ́ dáradára ní. Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn. Wọn óo di etí wọn sí òtítọ́; ìtàn àhesọ ti ara wọn ni wọn yóo máa gbọ́. Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, fi ara balẹ̀ ninu ohun gbogbo. Farada ìṣòro. Ṣe iṣẹ́ ìyìn rere. Má fi ohunkohun sílẹ̀ láì ṣe ninu iṣẹ́ iranṣẹ rẹ.
II. Tim 4:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán. Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé.