II. Tim 4:1-7
II. Tim 4:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ẹniti yio ṣe idajọ alãye ati okú, ati nitori ifarahàn rẹ̀ ati ijọba rẹ̀, Wasu ọ̀rọ na; ṣe aisimi li akokò ti o wọ̀, ati akokò ti kò wọ̀; baniwi, ṣe itọ́ni, gbà-ni-niyanju pẹlu ipamọra ati ẹ̀kọ́ gbogbo. Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan. Ṣugbọn mã ṣe pẹlẹ ninu ohun gbogbo, mã farada ipọnju, ṣe iṣẹ efangelisti, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe. Nitori a nfi mi rubọ nisisiyi, atilọ mi si sunmọ etile. Emi ti jà ìja rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ́ mọ́
II. Tim 4:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Mò ń kìlọ̀ fún ọ níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, tí ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ àwọn alààyè ati àwọn òkú; mò ń kì ọ́ nílọ̀ nítorí ìfarahàn rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀. Waasu ọ̀rọ̀ náà. Tẹnumọ́ ọn ní àkókò tí ó wọ̀ ati àkókò tí kò wọ̀. Máa báni wí. Máa gbani ní ìyànjú. Máa gbani ní ìmọ̀ràn, pẹlu ọpọlọpọ sùúrù tí ó yẹ kí ẹni tí yóo bá kọ́ eniyan lẹ́kọ̀ọ́ dáradára ní. Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn. Wọn óo di etí wọn sí òtítọ́; ìtàn àhesọ ti ara wọn ni wọn yóo máa gbọ́. Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, fi ara balẹ̀ ninu ohun gbogbo. Farada ìṣòro. Ṣe iṣẹ́ ìyìn rere. Má fi ohunkohun sílẹ̀ láì ṣe ninu iṣẹ́ iranṣẹ rẹ. Ní tèmi, a ti fi mí rúbọ ná. Àkókò ati fi ayé sílẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tó. Mo ti ja ìjà rere. Mo ti dé òpin iré ìje náà.
II. Tim 4:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀. Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán. Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé. Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé. Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́