II. Tim 4:1-4
II. Tim 4:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORINA mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ẹniti yio ṣe idajọ alãye ati okú, ati nitori ifarahàn rẹ̀ ati ijọba rẹ̀, Wasu ọ̀rọ na; ṣe aisimi li akokò ti o wọ̀, ati akokò ti kò wọ̀; baniwi, ṣe itọ́ni, gbà-ni-niyanju pẹlu ipamọra ati ẹ̀kọ́ gbogbo. Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan.
II. Tim 4:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Mò ń kìlọ̀ fún ọ níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, tí ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ àwọn alààyè ati àwọn òkú; mò ń kì ọ́ nílọ̀ nítorí ìfarahàn rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀. Waasu ọ̀rọ̀ náà. Tẹnumọ́ ọn ní àkókò tí ó wọ̀ ati àkókò tí kò wọ̀. Máa báni wí. Máa gbani ní ìyànjú. Máa gbani ní ìmọ̀ràn, pẹlu ọpọlọpọ sùúrù tí ó yẹ kí ẹni tí yóo bá kọ́ eniyan lẹ́kọ̀ọ́ dáradára ní. Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn. Wọn óo di etí wọn sí òtítọ́; ìtàn àhesọ ti ara wọn ni wọn yóo máa gbọ́.
II. Tim 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀. Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán.