II. Tim 4:1-22

II. Tim 4:1-22 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORINA mo paṣẹ fun ọ niwaju Ọlọrun, ati Kristi Jesu, ẹniti yio ṣe idajọ alãye ati okú, ati nitori ifarahàn rẹ̀ ati ijọba rẹ̀, Wasu ọ̀rọ na; ṣe aisimi li akokò ti o wọ̀, ati akokò ti kò wọ̀; baniwi, ṣe itọ́ni, gbà-ni-niyanju pẹlu ipamọra ati ẹ̀kọ́ gbogbo. Nitoripe ìgba yio de, ti nwọn kì yio le gba ẹkọ́ ti o yè kõro; ṣugbọn bi nwọn ti jẹ ẹniti eti nrìn nwọn ó lọ kó olukọ jọ fun ara wọn ninu ifẹkufẹ ara wọn. Nwọn ó si yi etí wọn pada kuro ninu otitọ, nwọn ó si yipada si ìtan asan. Ṣugbọn mã ṣe pẹlẹ ninu ohun gbogbo, mã farada ipọnju, ṣe iṣẹ efangelisti, ṣe iṣẹ iranṣẹ rẹ laṣepe. Nitori a nfi mi rubọ nisisiyi, atilọ mi si sunmọ etile. Emi ti jà ìja rere, emi ti pari ire-ije mi, emi ti pa igbagbọ́ mọ́: Lati isisiyi lọ a fi ade ododo lelẹ fun mi, ti Oluwa, onidajọ ododo, yio fifun mi li ọjọ na, kì si iṣe kìki emi nikan, ṣugbọn pẹlu fun gbogbo awọn ti o ti fẹ ifarahàn rẹ̀. Sa ipa rẹ lati tete tọ̀ mi wá. Nitori Dema ti kọ̀ mi silẹ, nitori o nfẹ aiye isisiyi, o si lọ si Tessalonika; Kreskeni si Galatia, Titu si Dalmatia. Luku nikan li o wà pẹlu mi. Mu Marku wá pẹlu rẹ: nitori o wulo fun mi fun iṣẹ iranṣẹ. Mo rán Tikiku ni iṣẹ lọ si Efesu. Aṣọ otutu ti mo fi silẹ ni Troa lọdọ Karpu, nigbati iwọ ba mbọ̀ mu u wá, ati iwe wọnni, pẹlupẹlu iwe-awọ wọnni. Aleksanderu alagbẹdẹ bàba ṣe mi ni ibi pupọ̀: Oluwa yio san a fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀: Lọdọ ẹniti ki iwọ ki o mã ṣọra pẹlu; nitoriti o kọ oju ija si iwasu wa pupọ̀. Li àtetekọ jẹ ẹjọ mi, kò si ẹniti o bá mi gba ẹjọ ro, ṣugbọn gbogbo enia li o kọ̀ mi silẹ: adura mi ni ki a máṣe kà a si wọn li ọrùn. Ṣugbọn Oluwa gbà ẹjọ mi ro, o si fun mi lagbara; pe nipasẹ mi ki a le wãsu na ni awàjálẹ̀, ati pe ki gbogbo awọn Keferi ki o le gbọ́: a si gbà mi kuro li ẹnu kiniun nì. Oluwa yio yọ mi kuro ninu iṣẹ buburu gbogbo, yio si gbé mi de inu ijọba rẹ̀ ọrun: ẹniti ogo wà fun lai ati lailai. Amin. Kí Priskilla ati Akuila, ati ile Onesiforu. Erastu wà ni Korinti: ṣugbọn mo fi Trofimu silẹ ni Miletu ninu aisan. Sa ipa rẹ lati tete wá ṣaju ìgba otutù. Eubulu kí ọ, ati Pudeni, ati Linu, ati Klaudia, ati gbogbo awọn arakunrin. Ki Oluwa ki o wà pẹlu ẹmí rẹ. Ki ore-ọfẹ ki o wà pẹlu nyin. Amin.

II. Tim 4:1-22 Yoruba Bible (YCE)

Mò ń kìlọ̀ fún ọ níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, tí ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ àwọn alààyè ati àwọn òkú; mò ń kì ọ́ nílọ̀ nítorí ìfarahàn rẹ̀ ati ìjọba rẹ̀. Waasu ọ̀rọ̀ náà. Tẹnumọ́ ọn ní àkókò tí ó wọ̀ ati àkókò tí kò wọ̀. Máa báni wí. Máa gbani ní ìyànjú. Máa gbani ní ìmọ̀ràn, pẹlu ọpọlọpọ sùúrù tí ó yẹ kí ẹni tí yóo bá kọ́ eniyan lẹ́kọ̀ọ́ dáradára ní. Àkókò ń bọ̀ tí àwọn eniyan kò ní fẹ́ fetí sí ẹ̀kọ́ tí ó yè. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara wọn ni wọn yóo tẹ̀lé, tí wọn yóo kó àwọn olùkọ́ tira, tí wọn yóo máa sọ ohun tí wọn máa ń fẹ́ gbọ́ fún wọn. Wọn óo di etí wọn sí òtítọ́; ìtàn àhesọ ti ara wọn ni wọn yóo máa gbọ́. Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, fi ara balẹ̀ ninu ohun gbogbo. Farada ìṣòro. Ṣe iṣẹ́ ìyìn rere. Má fi ohunkohun sílẹ̀ láì ṣe ninu iṣẹ́ iranṣẹ rẹ. Ní tèmi, a ti fi mí rúbọ ná. Àkókò ati fi ayé sílẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ tó. Mo ti ja ìjà rere. Mo ti dé òpin iré ìje náà. Nisinsinyii adé òdodo náà wà nílẹ̀ fún mi, tí Oluwa onídàájọ́ òdodo yóo fún mi ní ọjọ́ náà. Èmi nìkan kọ́ ni yóo sì fún, yóo fún gbogbo àwọn tí wọn ń fi tìfẹ́tìfẹ́ retí ìfarahàn rẹ̀. Sa gbogbo ipá rẹ láti tètè wá sọ́dọ̀ mi. Demasi ti fi mí sílẹ̀ nítorí ó fẹ́ràn nǹkan ayé yìí. Ó ti lọ sí Tẹsalonika. Kirẹsẹnsi ti lọ sí Galatia. Titu ti lọ sí Dalimatia. Luku nìkan náà ni ó kù lọ́dọ̀ mi. Mú Maku lọ́wọ́ bí o bá ń bọ̀ nítorí ó wúlò fún mi bí iranṣẹ. Mo ti rán Tukikọsi lọ sí Efesu. Nígbà tí o bá ń bọ̀, bá mi mú agbádá tí mo fi sọ́dọ̀ Kapu ní Tiroasi bọ̀. Bá mi mú àwọn ìwé mi náà bọ̀, pataki jùlọ àwọn ìwé aláwọ mi. Alẹkisanderu, alágbẹ̀dẹ bàbà fi ojú mi rí nǹkan! Kí Oluwa san ẹ̀san fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀. Kí ìwọ náà ṣọ́ra lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí títa ni ó ń tako àwọn ohun tí à ń sọ. Nígbà tí mo níláti jà fún ara mi ní ẹẹkinni, kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbèjà mi: gbogbo wọn ni wọ́n fi mí sílẹ̀. Kí Ọlọrun má kà á sí wọn lọ́rùn. Ṣugbọn Oluwa dúró tì mí, ó fún mi lágbára tí mo fi waasu ìyìn rere lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu fi gbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe bọ́ lẹ́nu kinniun. Oluwa yóo yọ mí kúrò ninu iṣẹ́ burúkú gbogbo, yóo sì gbà mí sinu ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run. Tirẹ̀ ni ògo lae ati laelae. Amin. Kí Pirisila ati Akuila ati ìdílé Onesiforosi. Erastu ti dúró ní Kọrinti. Mo fi Tirofimọsi sílẹ̀ ní Miletu pẹlu àìlera. Sa ipá rẹ láti wá kí ó tó di àkókò òtútù. Yubulọsi kí ọ, ati Pudẹsi, Linọsi, Kilaudia ati gbogbo àwọn arakunrin. Kí Oluwa wà pẹlu ẹ̀mí rẹ. Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín.

II. Tim 4:1-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, ẹni tí yóò ṣe ìdájọ́ alààyè àti òkú, àti nítorí ìfarahàn rẹ̀ àti ìjọba rẹ̀. Wàásù ọ̀rọ̀ náà, ṣe àìsimi ní àkókò tí ó wọ̀, àti àkókò ti kò wọ̀; bá ni wí, ṣe ìtọ́ni, gbani níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra àti ẹ̀kọ́ gbogbo. Nítorí pé ìgbà yóò dé, tí wọn kì yóò lè gba ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti jẹ́ ẹni tí etí ń rin, wọn ó lọ kó olùkọ́ jọ fún ara wọn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n ó sì yí etí wọn padà kúrò nínú òtítọ́, wọn ó sì yípadà sí ìtàn asán. Ṣùgbọ́n máa faradà ìpọ́njú, ṣe iṣẹ́ efangelisti, ṣe iṣẹ́ rẹ láṣepé. Nítorí à ń fi mi rú ẹbọ nísinsin yìí, àtilọ mi sì súnmọ́ etílé. Èmi ti ja ìjà rere, èmi tí parí iré-ìje mi, èmi ti pa ìgbàgbọ́ mọ́; Láti ìsinsin yìí lọ a fi adé òdodo lélẹ̀ fún mi, tí Olúwa onídàájọ́ òdodo, yóò fífún mi ni ọjọ́ náà kì í sì í ṣe kìkì èmi nìkan ṣùgbọ́n pẹ̀lú fún gbogbo àwọn tí ó ti fẹ́ ìfarahàn rẹ̀. Sa ipá rẹ láti tètè tọ̀ mí wá. Nítorí Dema ti kọ̀ mí sílẹ̀, nítorí ó ń fẹ́ ayé yìí, ó sì lọ sí Tẹsalonika; Kreskeni sí Galatia, Titu sí Dalimatia. Luku nìkan ni ó wà pẹ̀lú mi, mú Marku wá pẹ̀lú rẹ: nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́. Mo rán Tikiku ní iṣẹ́ lọ sí Efesu. Aṣọ òtútù tí mo fi sílẹ̀ ní Troasi lọ́dọ̀ Karpu, nígbà tí ìwọ bá ń bọ̀ mú un wa, àti àwọn ìwé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ìwé-awọ. Aleksanderu alágbẹ̀dẹ bàbà ṣe mi ni ibi púpọ̀: Olúwa yóò san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀: Lọ́dọ̀ ẹni tí kí ìwọ máa ṣọ́ra pẹ̀lú, nítorí tí ó kọ ojú ìjà sí ìwàásù wa púpọ̀. Ní àkọ́kọ́ jẹ́ ẹjọ́ mi, kò sí ẹni tí ó ba mi gba ẹjọ́ rò ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ni o kọ̀ mi sílẹ̀: Àdúrà mi ni kí a má ṣe ká à sí wọn lọ́rùn. Ṣùgbọ́n Olúwa gba ẹjọ́ mi rò, ó sì fún mi lágbára; pé nípasẹ̀ mi kí a lè wàásù náà ní àwàjálẹ̀, àti pé kí gbogbo àwọn aláìkọlà lè gbọ́; a sì gbà mí kúrò lẹ́nu kìnnìún náà. Olúwa yóò yọ mí kúrò nínú iṣẹ́ búburú gbogbo, yóò sì mu mí dé inú ìjọba ọ̀run. Ẹni ti ògo wà fún láé àti láéláé. Àmín. Kí Priska àti Akuila, àti ilé Onesiforu. Erastu wà ní Kọrinti: ṣùgbọ́n mo fi Tirofimu sílẹ̀ ni Miletu nínú àìsàn. Sa ipá rẹ láti tètè wá ṣáájú ìgbà òtútù. Eubulu kí ọ, àti Pudeni, àti Linu, Klaudia, àti gbogbo àwọn arákùnrin. Kí Olúwa wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú yín.