II. Tim 3:10-15
II. Tim 3:10-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn iwọ ti mọ̀ ẹkọ́ mi, igbesi aiye mi, ipinnu, igbagbọ́, ipamọra, ifẹ́ni, sũru, Inunibini, iyà; awọn ohun ti o dé bá mi ni Antioku, ni Ikonioni ati ni Listra; awọn inunibini ti mo faradà: Oluwa si gbà mi kuro ninu gbogbo wọn. Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mã gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini. Ṣugbọn awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mã gbilẹ siwaju si i, nwọn o mã tàn-ni-jẹ, a o si mã tàn wọn jẹ. Ṣugbọn iwọ duro ninu nkan wọnni ti iwọ ti kọ́, ti a si ti jẹ ki oju rẹ dá ṣáṣa si, ki iwọ ki o si mọ̀ ọdọ ẹniti iwọ gbé kọ́ wọn; Ati pe lati igba ọmọde ni iwọ ti mọ̀ iwe-mimọ́, ti o le sọ ọ di ọlọ́gbọn si igbala nipasẹ igbagbọ́ ninu Kristi Jesu.
II. Tim 3:10-15 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, o ti tẹ̀lé ẹ̀kọ́ mi, ati ọ̀nà ìgbé-ayé mi, ète mi, ati igbagbọ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi ati ìfaradà mi, ninu inúnibíni, ninu irú ìyà tí ó bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu, ní Listira, ati oríṣìíríṣìí inúnibíni tí mo faradà. Oluwa ni ó yọ mí ninu gbogbo wọn. Wọn yóo ṣe inúnibíni sí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ gbé ìgbé-ayé olùfọkànsìn gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Inúnibíni níláti dé sí wọn. Ṣugbọn yóo túbọ̀ máa burú sí i ni fún àwọn eniyan burúkú ati àwọn ẹlẹ́tàn: wọn yóo máa tan eniyan jẹ, eniyan yóo sì máa tan àwọn náà jẹ. Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, dúró gbọningbọnin ninu àwọn ohun tí o ti kọ́, tí ó sì dá ọ lójú. Ranti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí o ti kọ́ wọn. Nítorí láti ìgbà tí o ti wà ní ọmọde ni o ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n, tí o fi lè ní ìgbàlà nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.
II. Tim 3:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu.