II. Tim 3:1-17

II. Tim 3:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

ṢUGBỌN eyi ni ki o mọ̀, pe ni ikẹhin ọjọ ìgbà ewu yio de. Nitori awọn enia yio jẹ olufẹ ti ara wọn, olufẹ owo, afunnú, agberaga, asọ̀rọbuburu, aṣaigbọran si obi, alailọpẹ, alaimọ́, Alainifẹ, alaile darijini, abanijẹ́, alaile-kó-ra-wọnnijanu, onroro, alainifẹ-ohun-rere, Onikupani, alagidi, ọlọkàn giga, olufẹ fãji jù olufẹ Ọlọrun lọ; Awọn ti nwọn ni afarawe iwa-bi-Ọlọrun, ṣugbọn ti nwọn sẹ́ agbara rẹ̀: yẹra kuro lọdọ awọn wọnyi pẹlu. Nitori ninu irú eyi li awọn ti nrakò wọ̀ inu ile, ti nwọn si ndì awọn obinrin alailọgbọn ti a dì ẹ̀ṣẹ rù ni igbekùn, ti a si nfi onirũru ifẹkufẹ fà kiri, Nwọn nfi igbagbogbo kẹ́kọ, nwọn kò si le de oju ìmọ otitọ. Njẹ gẹgẹ bi Janesi ati Jamberi ti kọ oju ija si Mose, bẹ̃li awọn wọnyi kọ oju ija si otitọ: awọn enia ti inu wọn dibajẹ, awọn ẹni ìtanù niti ọran igbagbọ́. Ṣugbọn nwọn kì yio lọ siwaju jù bẹ̃lọ: nitori wère wọn yio farahan fun gbogbo enia gẹgẹ bi tiwọn ti yọri si. Ṣugbọn iwọ ti mọ̀ ẹkọ́ mi, igbesi aiye mi, ipinnu, igbagbọ́, ipamọra, ifẹ́ni, sũru, Inunibini, iyà; awọn ohun ti o dé bá mi ni Antioku, ni Ikonioni ati ni Listra; awọn inunibini ti mo faradà: Oluwa si gbà mi kuro ninu gbogbo wọn. Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mã gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini. Ṣugbọn awọn enia buburu, ati awọn ẹlẹtàn yio mã gbilẹ siwaju si i, nwọn o mã tàn-ni-jẹ, a o si mã tàn wọn jẹ. Ṣugbọn iwọ duro ninu nkan wọnni ti iwọ ti kọ́, ti a si ti jẹ ki oju rẹ dá ṣáṣa si, ki iwọ ki o si mọ̀ ọdọ ẹniti iwọ gbé kọ́ wọn; Ati pe lati igba ọmọde ni iwọ ti mọ̀ iwe-mimọ́, ti o le sọ ọ di ọlọ́gbọn si igbala nipasẹ igbagbọ́ ninu Kristi Jesu. Gbogbo iwe-mimọ́ ni o ni imísi Ọlọrun ti o si ni ère fun ẹkọ́, fun ibaniwi, fun itọ́ni, fun ikọ́ni ti o wà ninu ododo: Ki enia Ọlọrun ki o le pé, ti a ti mura silẹ patapata fun iṣẹ rere gbogbo.

II. Tim 3:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Kí o mọ èyí pé àkókò ìṣòro ni ọjọ́ ìkẹyìn yóo jẹ́. Nítorí àwọn eniyan yóo wà tí ó jẹ́ pé ara wọn ati owó nìkan ni wọn óo fẹ́ràn. Wọn óo jẹ́ oníhàlẹ̀, onigbeeraga, ati onísọkúsọ. Wọn yóo máa ṣe àfojúdi sí àwọn òbí wọn. Wọn óo jẹ́ aláìmoore; aláìbọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, onínú burúkú; akọ̀mágbẹ̀bẹ̀, abanijẹ́; àwọn tí kò lè kó ara wọn níjàánu, òǹrorò; àwọn tí kò fẹ́ ohun rere; ọ̀dàlẹ̀, jàǹdùkú, àwọn tí ó jọ ara wọn lójú pupọ, àwọn tí wọ́n fẹ́ràn fàájì, dípò kí wọ́n fẹ́ràn Ọlọrun. Ní òde, ara wọn dàbí olùfọkànsìn, ṣugbọn wọn kò mọ agbára ẹ̀sìn tòótọ́. Ìwọ jìnnà sí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀. Ara wọn ni àwọn tíí máa tọ ojúlé kiri, tí wọn máa ń ki àwọn aṣiwèrè obinrin mọ́lẹ̀, àwọn obinrin tí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ ti wọ̀ lẹ́wù, tí wọn ń ṣe oríṣìíríṣìí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Àwọn obinrin wọnyi ń kẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, sibẹ wọn kò lè ní ìmọ̀ òtítọ́. Bí Janesi ati Jamberesi ti tako Mose, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkunrin wọnyi tako òtítọ́. Orí irú àwọn eniyan bẹ́ẹ̀ ti kú, a sì ti ṣá wọn tì ní ti igbagbọ. Ṣugbọn wọn kò lè máa bá irú ìwà bẹ́ẹ̀ lọ pẹ́ títí. Nítorí pé ìwà wèrè wọn yóo hàn kedere sí gbogbo eniyan, gẹ́gẹ́ bí ti Janesi ati Jamberesi ti hàn. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, o ti tẹ̀lé ẹ̀kọ́ mi, ati ọ̀nà ìgbé-ayé mi, ète mi, ati igbagbọ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi ati ìfaradà mi, ninu inúnibíni, ninu irú ìyà tí ó bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu, ní Listira, ati oríṣìíríṣìí inúnibíni tí mo faradà. Oluwa ni ó yọ mí ninu gbogbo wọn. Wọn yóo ṣe inúnibíni sí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ gbé ìgbé-ayé olùfọkànsìn gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Inúnibíni níláti dé sí wọn. Ṣugbọn yóo túbọ̀ máa burú sí i ni fún àwọn eniyan burúkú ati àwọn ẹlẹ́tàn: wọn yóo máa tan eniyan jẹ, eniyan yóo sì máa tan àwọn náà jẹ. Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, dúró gbọningbọnin ninu àwọn ohun tí o ti kọ́, tí ó sì dá ọ lójú. Ranti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí o ti kọ́ wọn. Nítorí láti ìgbà tí o ti wà ní ọmọde ni o ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n, tí o fi lè ní ìgbàlà nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu. Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọrun, ó sì wúlò fún ẹ̀kọ́, fún ìbáwí, fún ìtọ́nisọ́nà, fún ìlànà nípa ìwà òdodo, kí eniyan Ọlọrun lè jẹ́ ẹni tí ó pé, tí ó múra sílẹ̀ láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rere.

II. Tim 3:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ṣùgbọ́n èyí ni kí o mọ̀: pé ní ìkẹyìn ọjọ́ ìgbà ewu yóò dé. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, olùfẹ́ owó, afọ́nnu, agbéraga, asọ̀rọ̀ búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìmọ́. Aláìnífẹ̀ẹ́, aláìlèdáríjì, abanijẹ́, aláìlè-kó-aràwọn-níjánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́ ohun rere, oníkúpani, alágídí, ọlọ́kàn gíga, olùfẹ́ fàájì ju olùfẹ́ Ọlọ́run lọ. Àwọn tí wọn ní àfarawé ìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọn sẹ́ agbára rẹ̀; yẹra kúrò lọ́dọ̀ àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú. Nítorí nínú irú èyí ni àwọn ti ń rákò wọ inú ilé, tí wọ́n sì ń di àwọn obìnrin aláìlọ́gbọ́n tí a di ẹ̀ṣẹ̀ rù ní ìgbèkùn, tí a sì ń fi onírúurú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ fà kiri Wọ́n ń fi ìgbà gbogbo kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n kò sì lè dé ojú ìmọ̀ òtítọ́. Ǹjẹ́ gẹ́gẹ́ bí Janesi àti Jamberi ti kọ ojú ìjà sí Mose náà ni wọ́n kọjú ìjà sí òtítọ́: àwọn ènìyàn tí inú wọn díbàjẹ́, àwọn ẹni ìtanù ní ti ọ̀ràn ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n wọn kì yóò lọ síwájú ju bẹ́ẹ̀ lọ: Nítorí òmùgọ̀ wọn yóò farahàn fún gbogbo ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ti àwọn méjì yìí náà, ti yọrí si. Ṣùgbọ́n ìwọ ti mọ ẹ̀kọ́ mi, ìgbésí ayé mi, ìpinnu, ìgbàgbọ́, ìpamọ́ra, ìfẹ́ sùúrù. Inúnibíni, ìyà; àwọn ohun tí ó dé bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu ní Lysra; àwọn inúnibíni tí mo faradà: Olúwa sì gbà mi kúrò nínú gbogbo wọn. Nítòótọ́, gbogbo àwọn tí ó fẹ́ máa gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run nínú Kristi Jesu yóò faradà inúnibíni Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa burú síwájú sí i, wọn ó máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ. Ṣùgbọ́n ìwọ dúró nínú nǹkan wọ̀nyí tí ìwọ ti kọ́, tí a sì ti jẹ́ kí ojú rẹ dá ṣáṣá sí, kí ìwọ sì mọ̀ ọ̀dọ̀ ẹni tí ìwọ gbé kọ́ wọn. Àti pé láti ìgbà ọmọdé ni ìwọ ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n sí ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Kristi Jesu. Gbogbo ìwé mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọ́run tí ó sì ní èrè fún ẹ̀kọ́, fún ìbániwí, fún ìtọ́ni, fún ìkọ́ni tí ó wà nínú òdodo. Kí ènìyàn Ọlọ́run lè pé, tí a ti múra sílẹ̀ pátápátá fun iṣẹ́ rere gbogbo.