II. Tim 2:8-13
II. Tim 2:8-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ranti Jesu Kristi, ti o jinde kuro ninu okú, lati inu irú-ọmọ Dafidi, gẹgẹ bi ihinrere mi, Ninu eyiti emi nri ipọnju titi dé inu ìde bi arufin; ṣugbọn a kò dè ọ̀rọ Ọlọrun. Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun. Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè: Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sẹ́ ẹ, on na yio si sẹ́ wa. Bi awa kò ba gbagbọ́, on duro li olõtọ: nitori on kò le sẹ́ ara rẹ̀.
II. Tim 2:8-13 Yoruba Bible (YCE)
Ranti Jesu Kristi tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí a bí ninu ìdílé Dafidi. Ìyìn rere tí mò ń waasu nìyí. Ninu iṣẹ́ yìí ni mo ti ń jìyà títí mo fi di ẹlẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn. Ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè fi ẹ̀wọ̀n de ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, pé, “Bí a bá bá a kú, a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀. Bí a bá faradà á, a óo bá a jọba. Bí a bá sẹ́ ẹ, òun náà yóo sẹ́ wa. Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo, nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.”
II. Tim 2:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Rántí Jesu Kristi, ti ó jíǹde kúrò nínú òkú, láti inú irú-ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere mi. Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà: Bi àwa bá bá a kú, àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀. Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jẹ ọba: Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa. Bí àwa kò bá gbàgbọ́, òun dúró ni olóòtítọ́: Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.