II. Tim 2:10-13
II. Tim 2:10-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina mo nfarada ohun gbogbo nitori ti awọn ayanfẹ, ki awọn na pẹlu le ni igbala ti mbẹ ninu Kristi Jesu pẹlu ogo ainipẹkun. Otitọ li ọrọ na: Nitoripe bi awa ba bá a kú, awa ó si bá a yè: Bi awa ba farada, awa ó si ba a jọba: bi awa ba sẹ́ ẹ, on na yio si sẹ́ wa. Bi awa kò ba gbagbọ́, on duro li olõtọ: nitori on kò le sẹ́ ara rẹ̀.
II. Tim 2:10-13 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, mo farada ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́, kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tí ó wà ninu Kristi Jesu pẹlu ògo tí ó wà títí lae. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, pé, “Bí a bá bá a kú, a óo wà láàyè pẹlu rẹ̀. Bí a bá faradà á, a óo bá a jọba. Bí a bá sẹ́ ẹ, òun náà yóo sẹ́ wa. Bí àwa kò bá tilẹ̀ ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, òun ṣe é gbẹ́kẹ̀lé nígbà gbogbo, nítorí òun kò lè tan ara rẹ̀ jẹ.”
II. Tim 2:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kristi Jesu pẹ̀lú ògo ayérayé. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà: Bi àwa bá bá a kú, àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀. Bí àwa bá faradà, àwa ó sì bá a jẹ ọba: Bí àwa bá sẹ́ ẹ, òun náà yóò sì sẹ́ wa. Bí àwa kò bá gbàgbọ́, òun dúró ni olóòtítọ́: Nítorí òun kò lè sẹ́ ara rẹ̀.