II. Tes 2:9-10
II. Tes 2:9-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ani on, ẹniti wíwa rẹ̀ yio ri gẹgẹ bi iṣẹ Satani pẹlu agbara gbogbo, ati àmi ati iṣẹ-iyanu eke, Ati pẹlu itanjẹ aiṣododo gbogbo fun awọn ti nṣegbé; nitoriti nwọn kò gbà ifẹ otitọ ti a ba fi gbà wọn là.
Pín
Kà II. Tes 2II. Tes 2:9-10 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí Ẹni Burúkú yìí yóo farahàn pẹlu agbára Èṣù: yóo máa pidán, yóo ṣe iṣẹ́ àmì, yóo ṣe iṣẹ́ ìtànjẹ tí ó yani lẹ́nu. Yóo fi ọ̀nà àrékérekè burúkú lóríṣìíríṣìí tan àwọn ẹni ègbé jẹ, nítorí wọn kò ní ìfẹ́ òtítọ́, tí wọn ìbá fi rí ìgbàlà.
Pín
Kà II. Tes 2II. Tes 2:9-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wíwá ẹni ẹ̀ṣẹ̀ yóò rí bí iṣẹ́ Satani, gbogbo èyí tí a fihàn gẹ́gẹ́ bí àdàmọ̀dì iṣẹ́ ìyanu, àdàmọ̀dì ààmì àti àdàmọ̀dì idán, Ní gbogbo ọ̀nà búburú tí a fi ń tan àwọn tí ń ṣègbé jẹ. Wọ́n ṣègbé nítorí wọ́n kọ̀ láti fẹ́ràn òtítọ́ kí wọn sì di ẹni ìgbàlà.
Pín
Kà II. Tes 2