II. Tes 1:11-12
II. Tes 1:11-12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori eyiti awa pẹlu ngbadura fun nyin nigbagbogbo, pe ki Ọlọrun wa ki o le kà nyin yẹ fun ìpe nyin, ki o le mu gbogbo ifẹ ohun rere ati iṣẹ igbagbọ́ ṣẹ ni agbara: Ki a le yìn orukọ Jesu Oluwa wa logo ninu nyin, ati ẹnyin ninu rẹ̀, gẹgẹ bi ore-ọfẹ Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Oluwa.
II. Tes 1:11-12 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí èyí ni a fi ń gbadura fun yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọrun wa lè kà yín yẹ fún ìpè tí ó pè yín, kí ó mú èrò gbogbo ṣẹ, kí ó sì fi agbára fun yín láti máa gbé ìgbé-ayé tí ó yẹ onigbagbọ; kí ẹ lè yin orúkọ Oluwa wa Jesu lógo, kí òun náà sì yìn yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa ati ti Oluwa Jesu Kristi.
II. Tes 1:11-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí èyí, àwa pẹ̀lú ń gbàdúrà fún un yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọ́run wa kí ó lè kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀, àti pé nípa agbára rẹ̀, òun yóò mú gbogbo èrò rere yín ṣẹ àti gbogbo ohun tí ìgbàgbọ́ bá rú jáde. Wọ̀nyí ni àdúrà wa, kí orúkọ Jesu Olúwa wa lè di yíyìn lógo nínú yín àti ẹ̀yin nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run àti ti Jesu Kristi Olúwa.