II. Sam 3:22-39
II. Sam 3:22-39 Bibeli Mimọ (YBCV)
Si wõ, awọn iranṣẹ Dafidi ati Joabu si ti ibi ilepa ẹgbẹ ogun kan bọ̀, nwọn si mu ikogun pupọ bọ̀; ṣugbọn Abneri ko si lọdọ Dafidi ni Hebroni; nitoriti on ti rán a lọ: on si ti lọ li alafia. Nigbati Joabu ati gbogbo ogun ti o pẹlu rẹ̀ si de, nwọn si sọ fun Joabu pe, Abneri, ọmọ Neri ti tọ̀ ọba wá, on si ti rán a lọ, o si ti lọ li alafia. Joabu si tọ̀ ọba wá, o si wipe, Kini iwọ ṣe nì? wõ, Abneri tọ̀ ọ wá; ehatiṣe ti iwọ si fi rán a lọ? on si ti lọ. Iwọ mọ̀ Abneri ọmọ Neri, pe, o wá lati tàn ọ jẹ, ati lati mọ̀ ijadelọ rẹ, ati ibọsile rẹ, ati lati mọ̀ gbogbo eyi ti iwọ nṣe. Nigbati Joabu si jade kuro lọdọ Dafidi, o si ran awọn iranṣẹ lepa Abneri, nwọn si pè e pada lati ibi kanga Sira: Dafidi kò si mọ̀. Abneri si pada si Hebroni, Joabu si ba a tẹ̀ larin oju ọ̀na lati ba a sọ̀rọ li alafia, o si gún u nibẹ labẹ inu, o si kú, nitori ẹjẹ Asaheli arakunrin rẹ̀. Lẹhin igbati Dafidi si gbọ́ ọ, o si wipe, emi ati ijọba mi si jẹ alaiṣẹ niwaju Oluwa titi lai ni ẹjẹ Abneri ọmọ Neri: Jẹ ki o wà li ori Joabu, ati li ori gbogbo idile baba rẹ̀; ki a má si fẹ ẹni ti o li arùn isun, tabi adẹtẹ, tabi ẹni ti ntẹ̀ ọpá, tabi, ẹniti a o fi idà pa, tabi ẹniti o ṣe alaili onjẹ kù ni ile Joabu. Joabu ati Abiṣai arakunrin rẹ̀ si pa Abneri, nitoripe on ti pa Asaheli arakunrin wọn ni Gibeoni li ogun. Dafidi si wi fun Joabu ati fun gbogbo enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ pe, Ẹ fa aṣọ nyin ya, ki ẹnyin ki o si mu aṣọ-ọ̀fọ, ki ẹnyin ki o si sọkun niwaju Abneri. Dafidi ọba tikararẹ̀ si tẹle posi rẹ̀. Nwọn si sin Abneri ni Hebroni: ọba si gbe ohùn rẹ̀ soke, o si sọkun ni iboji Abneri; gbogbo awọn enia na si sọkun. Ọba si sọkun lori Abneri, o si wipe, Abneri iba ku iku aṣiwere? A kò sa dè ọ li ọwọ́, bẹ̃ li a kò si kàn ẹsẹ rẹ li abà: gẹgẹ bi enia iti ṣubu niwaju awọn ikà enia, bẹ̃ni iwọ ṣubu. Gbogbo awọn enia na si tun sọkun lori rẹ̀. Nigbati gbogbo enia si wá lati gbà Dafidi ni iyanju ki o jẹun nigbati ọjọ si mbẹ, Dafidi si bura wipe, Bẹ̃ni ki Ọlọrun ki o ṣe si mi, ati ju bẹ̃ lọ, bi emi ba tọ onjẹ wò, tabi nkan miran, titi õrun yio fi wọ̀. Gbogbo awọn enia si kiyesi i, o si dara loju wọn: gbogbo eyi ti ọba ṣe si dara loju gbogbo awọn enia na. Gbogbo awọn enia na ati gbogbo Israeli si mọ̀ lọjọ na pe, ki iṣe ifẹ ọba lati pa Abneri ọmọ Neri. Ọba si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹnyin kò mọ̀ pe olori ati ẹni-nla kan li o ṣubu li oni ni Israeli? Emi si ṣe alailagbara loni, bi o tilẹ jẹ pe a fi emi jọba; awọn ọkunrin wọnyi ọmọ Seruia si le jù mi lọ: Oluwa ni yio san a fun ẹni ti o ṣe ibi gẹgẹ bi ìwa buburu rẹ̀.
II. Sam 3:22-39 Yoruba Bible (YCE)
Kò pẹ́ pupọ lẹ́yìn náà, ni Joabu ati àwọn ọmọ ogun Dafidi pada dé láti ibi tí wọ́n ti lọ ja ogun kan, wọ́n sì kó ọpọlọpọ ìkógun bọ̀. Ṣugbọn Abineri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi, ní Heburoni, nígbà tí wọ́n dé, nítorí pé Dafidi ti ní kí ó máa pada lọ, ó sì ti lọ ní alaafia. Nígbà tí Joabu ati àwọn ọmọ ogun tí wọ́n tẹ̀lé e dé, wọ́n sọ fún Joabu pé, “Abineri ti wá sí ọ̀dọ̀ Dafidi ọba, ọba sì ti jẹ́ kí ó lọ ní alaafia.” Joabu bá lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, ó bèèrè pé, “Irú kí ni o ṣe yìí, Abineri wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, o sì jẹ́ kí ó lọ bẹ́ẹ̀? Ṣebí o mọ̀ pé ó wá tàn ọ́ jẹ ni? Ó wá fi ọgbọ́n wádìí gbogbo ibi tí ò ń lọ, ati gbogbo ohun tí ò ń ṣe ni.” Nígbà tí Joabu kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó ranṣẹ lọ pe Abineri, wọ́n sì dá a pada láti ibi kànga Sira, ṣugbọn Dafidi kò mọ nǹkankan nípa rẹ̀. Nígbà tí Abineri pada dé Heburoni, Joabu mú un lọ sí kọ̀rọ̀ kan, níbi ẹnubodè, bí ẹni pé ó fẹ́ bá a sọ ọ̀rọ̀ àṣírí, Joabu bá fi nǹkan gún un ní ikùn. Bẹ́ẹ̀ ni Abineri ṣe kú, nítorí pé ó pa Asaheli arakunrin Joabu. Nígbà tí Dafidi gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ní, “OLUWA mọ̀ pé, èmi ati àwọn eniyan mi kò lọ́wọ́ sí ikú Abineri rárá, ọwọ́ wa mọ́ patapata ninu ọ̀ràn náà. Orí Joabu ati ìdílé baba rẹ̀ ni ẹ̀bi ìjìyà ikú yìí yóo dà lé. Láti ìrandíran rẹ̀, kò ní sí ẹnikẹ́ni tí kò ní kó àtọ̀sí, tabi kí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀, tabi tí kò ní jẹ́ pé iṣẹ́ obinrin nìkan ni wọn yóo lè ṣe, tabi kí wọ́n pa wọ́n lójú ogun, tabi kí wọ́n máa tọrọ jẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Joabu ati Abiṣai, arakunrin rẹ̀, ṣe pa Abineri tí wọ́n sì gbẹ̀san ikú Asaheli, arakunrin wọn, tí Abineri pa lójú ogun Gibeoni. Dafidi pàṣẹ pé kí Joabu ati àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ fa aṣọ wọn ya, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀, kí wọ́n sì ṣọ̀fọ̀ Abineri. Nígbà tí ó tó àkókò láti sìnkú Abineri, Dafidi ọba pàápàá tẹ̀lé òkú rẹ̀. Heburoni ni wọ́n sin òkú Abineri sí, ọba sọkún létí ibojì rẹ̀, gbogbo àwọn eniyan sì sọkún pẹlu. Dafidi kọ orin arò kan fún Abineri báyìí pé: “Kí ló dé tí Abineri fi kú bí aṣiwèrè? Wọn kò dì ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò dì ọ́ lẹ́sẹ̀; o ṣubú bí ìgbà tí eniyan ṣubú níwájú ìkà.” Gbogbo eniyan sì tún bú sẹ́kún. Gbogbo eniyan rọ Dafidi, pé kí ó jẹun ní ọ̀sán ọjọ́ náà ṣugbọn ó búra pé kí Ọlọrun pa òun bí òun bá fi ẹnu kan nǹkankan títí tí ilẹ̀ yóo fi ṣú. Gbogbo àwọn eniyan ṣe akiyesi ohun tí ọba ṣe yìí, ó sì dùn mọ́ wọn. Gbogbo ohun tí ọba ṣe patapata ni ó dùn mọ́ àwọn eniyan. Gbogbo àwọn eniyan Dafidi, ati gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni ó hàn sí gbangba pé, ọba kò lọ́wọ́ ninu pípa tí wọ́n pa Abineri. Ọba bi àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ṣé ẹ kò mọ̀ pé eniyan ńlá, ati alágbára kan ni ó ṣubú lónìí, ní ilẹ̀ Israẹli?” Ó ní, “Agbára mi dínkù lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òróró ni a fi yàn mí ní ọba. Ìwà ipá àwọn ọmọ Seruaya yìí ti le jù fún mi. OLUWA nìkan ni ó lè san ẹ̀san fún eniyan burúkú gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀.”
II. Sam 3:22-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Sì wò ó, àwọn ìránṣẹ́ Dafidi àti Joabu sì ti ibi ìlépa ẹgbẹ́ ogun kan bọ̀, wọ́n sì mú ìkógun púpọ̀ bọ̀; ṣùgbọ́n Abneri kò sí lọ́dọ̀ Dafidi ní Hebroni; nítorí tí òun ti rán an lọ: òun sì ti lọ ní Àlàáfíà. Nígbà tí Joabu àti gbogbo ogun tí ó pẹ̀lú rẹ̀ sì dé, wọ́n sì sọ fún Joabu pé Abneri, ọmọ Neri ti tọ ọba wá, òun sì ti rán an lọ, ó sì ti lọ ní àlàáfíà. Joabu sì tọ ọba wá, ó sì sọ pé, “Kí ni ìwọ ṣe yìí? Wò ó, Abneri tọ̀ ọ́ wá; èéha ti ṣe tí ìwọ sì fi rán an lọ? Òun sì ti lọ. Ìwọ mọ Abneri ọmọ Neri, pé ó wá láti tàn ọ́ jẹ ni, àti láti mọ ìjáde lọ rẹ, àti wíwọlé rẹ́ àti láti mọ gbogbo èyí tí ìwọ ń ṣe.” Nígbà tí Joabu sì jáde kúrò lọ́dọ̀ Dafidi, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ láti lépa Abneri, wọ́n sì pè é padà láti ibi kànga Sira: Dafidi kò sì mọ̀. Abneri sì padà sí Hebroni, Joabu sì bá a tẹ̀ láàrín ojú ọ̀nà láti bá a sọ̀rọ̀ ní àlàáfíà, ó sì gún un níbẹ̀ lábẹ́ inú, ó sì kú, nítorí ẹ̀jẹ̀ Asaheli arákùnrin rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi sì gbọ́ ọ ó sì wí pé, “Èmi àti ìjọba mi sì jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú OLúWA títí láé ní ti ẹ̀jẹ̀ Abneri ọmọ Neri: Jẹ́ kí ó wà ní orí Joabu, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀; kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní ààrùn ìsun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi idà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Joabu.” (Joabu àti Abiṣai arákùnrin rẹ̀ sì pa Abneri, nítorí pé òun ti pa Asaheli arákùnrin wọn ní Gibeoni ní ogun.) Dafidi sì wí fún Joabu àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yin sì sọkún níwájú Abneri.” Dafidi ọba tìkára rẹ̀ sì tẹ̀lé pósí rẹ̀. Wọ́n sì sin Abneri ní Hebroni: ọba sì gbé ohùn rẹ̀ sókè, ó sì sọkún ní ibojì Abneri; gbogbo àwọn ènìyàn náà sì sọkún. Ọba sì sọkún lórí Abneri, ó sì wí pé: “Ǹjẹ́ Abneri ó yẹ kí ó kú bí aṣiwèrè? A kò sá à dè ọ́ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kò kan ẹsẹ̀ rẹ ní àbà. Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ń ṣubú níwájú àwọn ìkà ènìyàn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ ṣubú.” Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì tún sọkún lórí rẹ̀. Nígbà tí gbogbo ènìyàn sì wá láti gba Dafidi ní ìyànjú kí ó jẹun, nígbà tí ọjọ́ sì ń bẹ, Dafidi sì búra wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí èmi yóò bá tọ́ oúnjẹ wò, tàbí nǹkan mìíràn títí oòrùn yóò fi wọ̀!” Gbogbo àwọn ènìyàn sì kíyèsi i, ó sì dára lójú wọn: gbogbo èyí tí ọba ṣe sì dára lójú gbogbo àwọn ènìyàn náà. Gbogbo àwọn ènìyàn náà àti gbogbo Israẹli sì mọ̀ lọ́jọ́ náà pé, kì í ṣe ìfẹ́ ọba láti pa Abneri ọmọ Neri. Ọba sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin kò mọ̀ pé olórí àti ẹni ńlá kan ni ó ṣubú lónìí ní Israẹli. Èmi sì ṣe aláìlágbára lónìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a fi èmi jẹ ọba; àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ọmọ Seruiah sì le jù mí lọ: OLúWA ni yóò san án fún ẹni tí ó ṣe ibi gẹ́gẹ́ bí ìwà búburú rẹ̀!”