II. Sam 24:24
II. Sam 24:24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọba si wi fun Arauna pe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn emi o rà a ni iye kan lọwọ rẹ, bi o ti wù ki o ṣe; bẹ̃li emi kì yio fi eyiti emi kò nawo fun, rú ẹbọ sisun si Oluwa Ọlọrun mi. Dafidi si rà ibi ipaka na, ati awọn malũ na li ãdọta ṣekeli fadaka.
II. Sam 24:24 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ọba dá a lóhùn pé, “Rárá o, n óo san owó rẹ̀ fún ọ, nítorí pé ohunkohun tí kò bá ní ná mi lówó, n kò ní fi rúbọ sí OLUWA Ọlọrun mi.” Dafidi bá ra ibi ìpakà ati àwọn akọ mààlúù náà, ní aadọta ṣekeli owó fadaka.
II. Sam 24:24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọba sì wí fún Arauna pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́; ṣùgbọ́n èmi ó rà á ní iye kan lọ́wọ́ rẹ, bí ó ti wù kí ó ṣe; bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi èyí tí èmi kò náwó fún, rú ẹbọ sísun sí OLúWA Ọlọ́run mi.” Dafidi sì ra ibi ìpakà náà, àti àwọn màlúù náà ní àádọ́ta ṣékélì fàdákà.