II. Sam 13:6-20

II. Sam 13:6-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

Amnoni si dubulẹ, o si ṣe bi ẹnipe on ṣaisan: ọba si wá iwò o, Amnoni si wi fun ọba pe, Jọwọ, jẹ ki Tamari aburo mi ki o wá, ki o si din akarà meji li oju mi, emi o si jẹ li ọwọ́ rẹ̀. Dafidi si ranṣẹ si Tamari ni ile pe, Lọ si ile Amnoni ẹgbọ́n rẹ, ki o si ṣe ti onjẹ fun u. Tamari si lọ si ile Amnoni ẹgbọ́n rẹ̀, on si mbẹ ni ibulẹ. Tamari si mu iyẹfun, o si pò o, o si fi ṣe akara li oju rẹ̀, o si din akara na. On si mu awo na, o si dà a sinu awo miran niwaju rẹ̀; ṣugbọn o kọ̀ lati jẹ. Amnoni si wipe, jẹ ki gbogbo ọkunrin jade kuro lọdọ mi. Nwọn si jade olukuluku ọkunrin kuro lọdọ rẹ̀. Amnoni si wi fun Tamari pe, mu onjẹ na wá si yara, emi o si jẹ lọwọ rẹ. Tamari si mu akara ti o ṣe, o si mu u tọ̀ Amnoni ẹgbọ́n rẹ̀ ni iyẹwu. Nigbati o si sunmọ ọ lati fi onjẹ fun u, on si di i mu, o si wi fun u pe, wá dubulẹ tì mi, aburo mi. On si da a lohùn wipe, Bẹ̃kọ ẹgbọ́n mi, máṣe tẹ́ mi; nitoripe ko tọ́ ki a ṣe iru nkan bẹ̃ ni Israeli, iwọ máṣe huwa were yi. Ati emi, nibo li emi o gbe itiju mi wọ̀? iwọ o si dabi ọkan ninu awọn aṣiwere ni Israeli. Njẹ nitorina, emi bẹ̀ ọ, sọ fun ọba; nitoripe on kì yio kọ̀ lati fi mi fun ọ. Ṣugbọn o kọ̀ lati gbọ́ ohùn rẹ̀; o si fi agbara mu u, o si ṣẹgun rẹ̀, o si ba a dapọ̀. Amnoni si korira rẹ̀ gidigidi, irira na si wá jù ifẹ ti on ti ni si i ri lọ. Amnoni si wi fun u pe, Dide, ki o si ma lọ. On si wi fun u pe, Ko ha ni idi bi; lilé ti iwọ nlé mi yi buru jù eyi ti iwọ ti ṣe si mi lọ. Ṣugbọn on ko fẹ gbọ́ tirẹ̀. On si pe ọmọ-ọdọ rẹ̀ ti iṣe iranṣẹ rẹ̀, o si wi fun u pe, Jọwọ, tì obinrin yi sode fun mi, ki o si ti ilẹkùn mọ ọ. On si ni aṣọ alaràbara kan li ara rẹ̀: nitori iru aṣọ awọ̀leke bẹ̃ li awọn ọmọbinrin ọba ti iṣe wundia ima wọ̀. Iranṣẹ rẹ̀ si mu u jade, o si ti ilẹkun mọ ọ. Tamari si bu ẽru si ori rẹ̀, o si fa aṣọ alaràbara ti mbẹ lara rẹ̀ ya, o si ka ọwọ́ rẹ̀ le ori, o si nkigbe bi o ti nlọ. Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀ si bi i lere pe, Amnoni ẹgbọ́n rẹ ba ọ ṣe bi? njẹ aburo mi, dakẹ; ẹgbọ́n rẹ ni iṣe; má fi nkan yi si ọkàn rẹ. Tamari si joko ni ibanujẹ ni ile Absalomu ẹgbọ́n rẹ̀.

II. Sam 13:6-20 Yoruba Bible (YCE)

Amnoni bá dùbúlẹ̀, ó ṣe bí ẹni tí ó ń ṣàìsàn. Nígbà tí Dafidi ọba lọ bẹ̀ ẹ́ wò, Amnoni wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari, arabinrin mi, wá ṣe àkàrà díẹ̀ lọ́dọ̀ mi níhìn-ín, níbi tí mo ti lè máa rí i, kí ó sì gbé e wá fún mi.” Dafidi bá ranṣẹ pe Tamari ninu ààfin, ó ní kí ó lọ sinu ilé Amnoni, kí ó lọ tọ́jú oúnjẹ fún un. Tamari lọ, ó bá Amnoni lórí ibùsùn níbi tí ó dùbúlẹ̀ sí. Ó bu ìyẹ̀fun díẹ̀, ó pò ó, ó gé e ní ìwọ̀n àkàrà bíi mélòó kan, níbi tí Amnoni ti lè máa rí i. Lẹ́yìn náà, ó gbé e sórí iná títí tí ó fi jinná, ó sì dà á sinu àwo kan, ó gbé e fún un. Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò jẹ ẹ́, ó ní kí ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn bá jáde. Amnoni bá sọ fún un pé, “Gbé e tọ̀ mí wá ninu yàrá mi, kí o sì gbé e kalẹ̀ níwájú mi.” Tamari bá gbé àkàrà náà, ó sì tọ Amnoni lọ láti gbé e kalẹ̀ níwájú rẹ̀ ninu yàrá. Bí ó ti ń gbé e fún un, ni Amnoni gbá a mú, ó wí fún un pé, “Wá, mo fẹ́ bá ọ lòpọ̀.” Tamari dáhùn pé, “Rárá, má fi ipá mú mi, nítorí ẹnìkan kò gbọdọ̀ dán irú rẹ̀ wò ní Israẹli, má hùwà òmùgọ̀; níbo ni mo fẹ́ fi ojú sí láàrin gbogbo eniyan? Ohun ìtìjú patapata ni yóo sì jẹ́ fún ìwọ náà ní Israẹli. Jọ̀wọ́, bá ọba sọ̀rọ̀, mo mọ̀ dájúdájú pé yóo fi mí fún ọ.” Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ ohun tí Tamari sọ fún un. Nígbà tí ó sì jẹ́ pé Amnoni lágbára jù ú lọ, ó fi tipátipá bá a lòpọ̀. Lẹ́yìn náà, Amnoni kórìíra rẹ̀ gidigidi. Ìkórìíra náà pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ó tún wá ju bí ó ti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ní kí ó bọ́ sóde, kí ó máa lọ. Tamari dá a lóhùn pé, “Rárá, arakunrin mi, lílé tí ò ń lé mi jáde yìí burú ju ipá tí o fi bá mi lòpọ̀ lọ.” Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò gbọ́ tirẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Amnoni pe iranṣẹ rẹ̀ kan, ó wí fún un pé, “Mú obinrin yìí jáde kúrò níwájú mi, tì í sóde, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” Iranṣẹ náà bá ti Tamari jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. Aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ alápá gígùn, irú èyí tí àwọn ọmọ ọba, obinrin, tí kò tíì wọlé ọkọ máa ń wọ̀, ni Tamari wọ̀. Tamari bá ku eérú sí orí, ó fa aṣọ rẹ̀ ya, ó káwọ́ lórí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọkún bí ó ti ń lọ. Nígbà tí Absalomu, ẹ̀gbọ́n Tamari, rí i, ó bi í léèrè pé, “Ṣé Amnoni bá ọ lòpọ̀ ni? Jọ̀wọ́, arabinrin mi, gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ọmọ baba kan náà ni ẹ̀yin mejeeji, nítorí náà, má sọ fún ẹnikẹ́ni.” Tamari bá ń gbé ilé Absalomu. Òun nìkan ni ó dá wà, inú rẹ̀ sì bàjẹ́ pupọ.

II. Sam 13:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Amnoni sì dùbúlẹ̀, ó sì díbọ́n pé òun ṣàìsàn: ọba sì wá wò ó, Amnoni sì wí fún ọba pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Tamari àbúrò mi ó wá, kí ó sì dín àkàrà méjì lójú mi, èmi ó sì jẹ ní ọwọ́ rẹ̀.” Dafidi sì ránṣẹ́ sí Tamari ní ilé pé, “Lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ, kí ó sì se oúnjẹ fún un.” Tamari sì lọ sí ilé Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀, òun sì ń bẹ ní ìdùbúlẹ̀. Tamari sì mú ìyẹ̀fun, ó sì pò ó, ó sì fi ṣe àkàrà lójú rẹ̀, ó sì dín àkàrà náà. Òun sì mú àwo náà, ó sì dà á sínú àwo mìíràn níwájú rẹ̀; ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti jẹ. Amnoni sì wí pé, “Jẹ́ kí gbogbo ọkùnrin jáde kúrò lọ́dọ̀ mi!” Wọ́n sì jáde olúkúlùkù ọkùnrin kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Amnoni sì wí fún Tamari pé, “Mú oúnjẹ náà wá sí yàrá, èmi ó sì jẹ ẹ́ lọ́wọ́ rẹ.” Tamari sì mú àkàrà tí ó ṣe, ó sì mú un tọ Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní yàrá. Nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti fi oúnjẹ fún un, òun sì dìímú, ó sì wí fún un pé, “Wá dùbúlẹ̀ tì mí, àbúrò mi.” Òun sì dá a lóhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ ẹ̀gbọ́n mi, má ṣe tẹ́ mi; nítorí pé kò tọ kí a ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ní Israẹli, ìwọ má ṣe hùwà òmùgọ̀ yìí. Àti èmi, níbo ni èmi ó gbé ìtìjú mi wọ̀? Ìwọ ó sì dàbí ọ̀kan nínú àwọn aṣiwèrè ní Israẹli. Ǹjẹ́ nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́, sọ fún ọba; nítorí pé òun kì yóò kọ̀ láti fi mí fún ọ.” Ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti gbọ́ ohùn rẹ̀; ó sì fi agbára mú un, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì bá a dàpọ̀. Amnoni sì kórìíra rẹ̀ gidigidi, ìríra náà sì wá ju ìfẹ́ tí òun ti ní sí i rí lọ. Amnoni sì wí fún un pé, “Dìde, kí o sì máa lọ!” Òun sì wí fún un pé, “Kó ha ní ìdí bí! Lílé tí ìwọ ń lé mi yìí burú ju èyí tí ìwọ ti ṣe sí mi lọ.” Ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Òun sì pe ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, ti obìnrin yìí sóde fún mi, kí o sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn.” Òun sì ní aṣọ aláràbarà kan lára rẹ̀: nítorí irú aṣọ àwọ̀lékè bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọbìnrin ọba tí í ṣe wúńdíá máa ń wọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ̀ sì mú un jáde, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ ọn. Tamari sì bu eérú sí orí rẹ̀, ó sì fa aṣọ aláràbarà tí ń bẹ lára rẹ̀ ya, ó sì ká ọwọ́ rẹ̀ lé orí, ó sì ń kígbe bí ó ti ń lọ. Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ sì bí i léèrè pé, “Amnoni ẹ̀gbọ́n rẹ bá ọ sùn bí? Ǹjẹ́ àbúrò mi, dákẹ́; ẹ̀gbọ́n rẹ ní í ṣe; má fi nǹkan yìí sí ọkàn rẹ.” Tamari sì jókòó ní ìbànújẹ́ ní ilé Absalomu ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa