II. Sam 11:1-5
II. Sam 11:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, lẹhin igbati ọdun yipo, li akoko igbati awọn ọba ima jade ogun, Dafidi si rán Joabu, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati gbogbo Israeli; nwọn si pa awọn ọmọ Ammoni, nwọn si dó ti Rabba. Dafidi si joko ni Jerusalemu. O si ṣe, ni igbà aṣalẹ kan, Dafidi si dide ni ibusùn rẹ̀, o si nrìn lori orule ile ọba, lati ori orule na li o si ri obinrin kan ti o nwẹ̀ ara rẹ̀; obinrin na si ṣe arẹwa jọjọ lati wò. Dafidi si ranṣẹ, o si bere obinrin na. Ẹnikan si wipe, Eyi kọ Batṣeba, ọmọbinrin Eliami, aya Uria ará Hitti? Dafidi si rán awọn iranṣẹ, o si mu u; on si wọ inu ile tọ̀ ọ lọ, on si ba a dapọ̀: nigbati o si wẹ ara rẹ̀ mọ́ tan, o si pada lọ si ile rẹ̀. Obinrin na si fẹra kù, o si ranṣẹ o si sọ fun Dafidi, o si wipe, Emi fẹra kù.
II. Sam 11:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò ìgbà tí igi ń rúwé, tí ó jẹ́ àkókò tí gbogbo àwọn ọba máa ń lọ sójú ogun, Dafidi rán Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Israẹli jáde. Wọ́n ṣẹgun àwọn ará Amoni, wọ́n sì dó ti ìlú Raba, ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí Dafidi jí lójú oorun, ó gun orí òrùlé ààfin rẹ̀. Bí ó ti ń rìn káàkiri níbẹ̀, ó rí obinrin kan tí ń wẹ̀, obinrin náà jẹ́ arẹwà gidigidi. Dafidi bá rán oníṣẹ́ lọ, láti wádìí aya ẹni tí obinrin náà í ṣe. Ẹnìkan sì sọ fún un pé Batiṣeba ọmọ Eliamu ni, aya Uraya, ará Hiti. Dafidi bá ranṣẹ lọ pè é. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bá a lòpọ̀. Batiṣeba sì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ètò ìwẹ̀nùmọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tí ó parí nǹkan oṣù rẹ̀ ni. Ó bá pada lọ sí ilé rẹ̀. Nígbà tí ó yá, ó rí i pé òun lóyún, ó sì rán oníṣẹ́, pé kí wọ́n sọ fún Dafidi ọba.
II. Sam 11:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Dafidi sì rán Joabu, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Israẹli; wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ammoni, wọ́n sì dó ti Rabba. Dafidi sì jókòó ní Jerusalẹmu. Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dafidi sì dìde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò. Dafidi sì ránṣẹ́ ó sì béèrè obìnrin náà. Ẹnìkan sì wí pé, Èyí ha kọ́ ni Batṣeba, ọmọbìnrin Eliamu, aya Uriah ará Hiti. Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́, ó sì mú un; ó sì wọ inú ilé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a dàpọ̀: nígbà tí ó sì wẹ ara rẹ̀ mọ́ tán, ó sì padà lọ sí ilé rẹ̀. Obìnrin náà sì lóyún, ó sì ránṣẹ́ ó sì sọ fún Dafidi, ó sì wí pé, “Èmi ti lóyún.”