II. Sam 11:1-2
II. Sam 11:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, lẹhin igbati ọdun yipo, li akoko igbati awọn ọba ima jade ogun, Dafidi si rán Joabu, ati awọn iranṣẹ rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ati gbogbo Israeli; nwọn si pa awọn ọmọ Ammoni, nwọn si dó ti Rabba. Dafidi si joko ni Jerusalemu. O si ṣe, ni igbà aṣalẹ kan, Dafidi si dide ni ibusùn rẹ̀, o si nrìn lori orule ile ọba, lati ori orule na li o si ri obinrin kan ti o nwẹ̀ ara rẹ̀; obinrin na si ṣe arẹwa jọjọ lati wò.
II. Sam 11:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkókò ìgbà tí igi ń rúwé, tí ó jẹ́ àkókò tí gbogbo àwọn ọba máa ń lọ sójú ogun, Dafidi rán Joabu ati àwọn ọ̀gágun rẹ̀ ati àwọn ọmọ ogun Israẹli jáde. Wọ́n ṣẹgun àwọn ará Amoni, wọ́n sì dó ti ìlú Raba, ṣugbọn Dafidi dúró ní Jerusalẹmu. Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí Dafidi jí lójú oorun, ó gun orí òrùlé ààfin rẹ̀. Bí ó ti ń rìn káàkiri níbẹ̀, ó rí obinrin kan tí ń wẹ̀, obinrin náà jẹ́ arẹwà gidigidi.
II. Sam 11:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn ìgbà tí ọdún yípo, ní àkókò ìgbà tí àwọn ọba máa ń jáde ogun, Dafidi sì rán Joabu, àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, àti gbogbo Israẹli; wọ́n sì pa àwọn ọmọ Ammoni, wọ́n sì dó ti Rabba. Dafidi sì jókòó ní Jerusalẹmu. Ó sì ṣe, ní ìgbà àṣálẹ́ kan, Dafidi sì dìde ní ibùsùn rẹ̀, ó sì ń rìn lórí òrùlé ilé ọba, láti orí òrùlé náà ni ó sì rí obìnrin kan tí ó ń wẹ̀ ara rẹ̀; obìnrin náà sì ṣe arẹwà lójú láti wò.