II. Pet 3:3-5
II. Pet 3:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi pe, nigba ọjọ ikẹhin, awọn ẹlẹgan yio de pẹlu ẹgan wọn, nwọn o mã rin nipa ifẹ ara wọn, Nwọn o si mã wipe, Nibo ni ileri wíwa rẹ̀ gbé wà? lati igbati awọn baba ti sùn, ohun gbogbo nlọ bi nwọn ti wà rí lati ìgba ọjọ ìwa. Nitori eyi ni nwọn mọ̃mọ ṣe aifẹ̃mọ, pe nipa ọ̀rọ Ọlọrun li awọn ọrun ti wà lati ìgba atijọ, ati ti ilẹ yọri jade ninu omi, ti o si duro ninu omi
II. Pet 3:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọn óo máa sọ pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí ìlérí pé Jesu tún ń pada bọ̀? Nítorí láti ìgbà tí àwọn baba wa ninu igbagbọ ti lọ tán, bákan náà ni gbogbo nǹkan rí láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé!” Nítorí wọ́n fi ojú fo èyí dá pé, láti ìgbà àtijọ́ ni àwọn ọ̀run ti wà, ati pé láti inú omi ni ilẹ̀ ti jáde nípa àṣẹ Ọlọrun.
II. Pet 3:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ẹ kọ́ mọ èyí pé, nígbà ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn ẹlẹ́gàn yóò dé pẹ̀lú ẹ̀gàn wọn. Wọn ó máa rìn nípa ìfẹ́ ara wọn. Wọn ó sì máa wí pé, “Níbo ni ìlérí wíwà rẹ̀ gbé wà? Láti ìgbà tí àwọn baba ti sùn, ohun gbogbo ń lọ bí wọ́n ti wà rí láti ìgbà ọjọ́ yìí wá.” Nítorí èyí ni wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ ṣe àìfẹ́ ẹ́ mọ̀ pé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ọ̀run ti wà láti ìgbà àtijọ́ àti tí ilẹ̀ yọrí jáde nínú omi, tí ó sì dúró nínú omi.