II. Pet 3:15-17
II. Pet 3:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un. Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, a ti kìlọ̀ fun yín tẹ́lẹ̀. Ẹ ṣọ́ra kí àwọn eniyan burúkú wọnyi má baà tàn yín sí inú ìṣìnà wọn, kí ẹ má baà ṣubú lórí ìpìlẹ̀ tí ẹ dúró sí.
II. Pet 3:15-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki ẹ si mã kà a si pe, sũru Oluwa wa igbala ni; bi Paulu pẹlu, arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si nyin, gẹgẹ bi ọgbọ́n ti a fifun u; Bi o ti nsọ̀rọ nkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ̀ gbogbo; ninu eyi ti ohun miran ti o ṣòro lati yéni gbé wà, eyiti awọn òpè ati awọn alaiduro nibikan nlọ́, bi nwọn ti nlọ́ iwe mimọ́ iyoku, si iparun ara wọn. Nitorina ẹnyin olufẹ, bi ẹnyin ti mọ̀ nkan wọnyi tẹlẹ ẹ mã kiyesara, ki a má ba fi ìṣina awọn enia buburu fà nyin lọ, ki ẹ si ṣubu kuro ni iduro ṣinṣin nyin.
II. Pet 3:15-17 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un. Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù. Nítorí náà, ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, a ti kìlọ̀ fun yín tẹ́lẹ̀. Ẹ ṣọ́ra kí àwọn eniyan burúkú wọnyi má baà tàn yín sí inú ìṣìnà wọn, kí ẹ má baà ṣubú lórí ìpìlẹ̀ tí ẹ dúró sí.
II. Pet 3:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Paulu pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un. Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn. Nítorí náà ẹ̀yin olùfẹ́, bí ẹ̀yin ti mọ nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀, ẹ máa kíyèsára, kí a má ba à fi ìṣìnà àwọn ènìyàn búburú fà yín lọ, kí ẹ sì ṣubú kúrò ní ìdúró ṣinṣin yín.