II. Pet 3:15-16
II. Pet 3:15-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki ẹ si mã kà a si pe, sũru Oluwa wa igbala ni; bi Paulu pẹlu, arakunrin wa olufẹ, ti kọwe si nyin, gẹgẹ bi ọgbọ́n ti a fifun u; Bi o ti nsọ̀rọ nkan wọnyi pẹlu ninu iwe rẹ̀ gbogbo; ninu eyi ti ohun miran ti o ṣòro lati yéni gbé wà, eyiti awọn òpè ati awọn alaiduro nibikan nlọ́, bi nwọn ti nlọ́ iwe mimọ́ iyoku, si iparun ara wọn.
II. Pet 3:15-16 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ fi í sọ́kàn pé ìdí tí Oluwa wa fi mú sùúrù ni pé kí á lè ní ìgbàlà, bí Paulu arakunrin wa àyànfẹ́ ti kọ̀wé si yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fún un. Ninu gbogbo àwọn ìwé rẹ̀, nǹkankan náà ní ó ń sọ nípa ọ̀rọ̀ wọnyi. Ninu àwọn ìwé wọnyi, àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn le. Àwọn òpè ati àwọn tí wọn kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ a máa yí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ pada sí ìparun ara wọn, bí wọ́n ti ń yí àwọn ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yòókù.
II. Pet 3:15-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Kí ẹ sì máa kà á sí pé, sùúrù Olúwa wa ìgbàlà ni; bí Paulu pẹ̀lú arákùnrin wa olùfẹ́, ti kọ̀wé sí yín gẹ́gẹ́ bí ọgbọ́n tí a fi fún un. Bí ó tí ń sọ̀rọ̀ nǹkan wọ̀nyí pẹ̀lú nínú ìwé rẹ̀ gbogbo nínú èyí ti ohun mìíràn sọ̀rọ̀ láti yé ni gbé wà, èyí ti àwọn òpè àti àwọn aláìdúró níbìkan ń lo, bí wọ́n ti ń lo ìwé mímọ́ ìyókù, sí ìparun ara wọn.