II. Pet 2:5-22
II. Pet 2:5-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́; (nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn angẹli bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó o nì, wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí, bí ẹranko igbó tí kò ní èrò, ẹranko sá á tí a dá láti máa mú pa, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn, a ó pa wọn run pátápátá nínú ìbàjẹ́ ara wọn. Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jayé nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àsè pẹ̀lú yín. Ojú wọn kún fún panṣágà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ń tan àwọn tí ọkàn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ; àwọn tí wọ́n ní ọkàn tí ó ti yege nínú wọ̀bìà, ọmọ ègún ni wọ́n. Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìṣòdodo. Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí ìrékọjá rẹ̀, odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì fi òpin sí ìṣiwèrè wòlíì náà. Àwọn wọ̀nyí ni kànga tí kò ní omi, ìkùùkuu tí ẹ̀fúùfù ń gbá kiri; àwọn ẹni tí a pa òkùnkùn biribiri mọ́ dè títí láé. Nítorí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ ìhàlẹ̀ asán, nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, wọn a máa tan àwọn tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má tí ì bọ́ tán kúrò lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n wà nínú ìṣìnà. Wọn a máa ṣe ìlérí òmìnira fún wọn, nígbà tí àwọn pàápàá jẹ́ ẹrú ìdíbàjẹ́; nítorí ènìyàn tí di ẹrú ohunkóhun tí ó bá ṣe ọ̀gá rẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti yọ tán kúrò nínú èérí ayé nípa mímọ́ Olúwa àti Olùgbàlà wá Jesu Kristi, bí wọn bá sì tún fi ara kó o, tí a sì ṣẹ́gun wọn, ìgbẹ̀yìn wọn a burú jú ti ìṣáájú lọ. Nítorí ìbá sàn fún wọn, kí wọn má mọ́ ọ̀nà òdodo, jù pé lẹ́yìn tí wọ́n mọ̀ ọ́n tán, kí wọn yípadà kúrò nínú òfin mímọ́ tí a fi fún wọn. Òwe òtítọ́ náà ṣẹ sí wọn lára: “Ajá tún padà sí èébì ara rẹ̀; àti ẹlẹ́dẹ̀ tí a ti wẹ̀mọ́ tún padà ń yíràá nínú ẹrọ̀fọ̀.”
II. Pet 2:5-22 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun; Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun; O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ: (Nitori ọkunrin olõtọ nì bi o ti ngbe ãrin wọn, ti o nri, ti o si ngbọ́, lojojumọ ni ìwa buburu wọn mba ọkàn otitọ rẹ̀ jẹ́): Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ: Ṣugbọn pãpã awọn ti ntọ̀ ara lẹhin ninu ifẹkufẹ ẽri, ti nwọn si ngàn awọn ijoye, awọn ọ̀yájú, aṣe-tinuẹni, nwọn kò bẹ̀ru ati mã sọ̀rọ ẹgan si awọn oloye. Bẹni awọn angẹli bi nwọn ti pọ̀ ni agbara ati ipá tõ nì, nwọn kò dá wọn lẹjọ ẹ̀gan niwaju Oluwa. Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbẹ́ ti kò li ero, ẹranko ṣa ti a dá lati mã mu pa, nwọn nsọ̀rọ ẹgan ninu ọran ti kò yé wọn; a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn. Nwọn o si jẹ ère aiṣododo, awọn ti nwọn kà a si aiye jijẹ lati mã jẹ adùn aiye li ọsán. Nwọn jẹ́ abawọn ati àbuku, nwọn njaiye ninu asè-ifẹ́ wọn nigbati nwọn ba njẹ ase pẹlu nyin; Awọn oloju ti o kún fun panṣaga, ti kò si le dẹkun ẹ̀ṣẹ idá; ti ntàn awọn ọkàn ti kò fi ẹsẹ mulẹ jẹ: awọn ti nwọn ni ọkàn ti o ti fi ojukòkoro kọ́ra; awọn ọmọ ègún: Nwọn kọ̀ ọ̀na ti o tọ́ silẹ, nwọn si ṣako lọ, nwọn tẹle ọ̀na Balaamu ọmọ Beori, ẹniti o fẹràn ère aiṣododo; Ṣugbọn a ba a wi nitori irekọja rẹ̀: odi kẹtẹkẹtẹ fi ohùn enia sọ̀rọ, o si fi opin si were wolĩ na. Awọn wọnyi ni kanga ti kò li omi, ikũku ti ẹfũfu ngbá kiri; awọn ẹniti a pa òkunkun biribiri mọ́ de tití lai. Nitori igbati nwọn ba nsọ̀rọ ihalẹ asan, ninu ifẹkufẹ ara, nipa wọbia, nwọn a mã tan awọn ti nwọn fẹrẹ má ti ibọ tan kuro lọwọ ti nwọn wà ninu iṣina. Nwọn a mã ṣe ileri omnira fun wọn, nigbati awọn pãpã jẹ ẹrú idibajẹ́: nitori ẹniti o ba ṣẹgun ẹni, on na ni isi sọ ni di ẹrú. Nitori lẹhin ti nwọn ba ti yọ tan kuro ninu ẽri aiye, nipa mimọ̀ Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi, bi nwọn ba si tun fi ara kó o, ti a si ṣẹgun wọn, igbẹhin wọn a buru jù ti iṣaju lọ. Nitori ìba san fun wọn, ki nwọn ki o má mọ̀ ọ̀na ododo, jù lẹhin ti nwọn mọ̀ ọ tan, ki nwọn ki o yipada kuro ninu ofin mimọ́ ti a fifun wọn. Owe otitọ nì ṣẹ si wọn lara, Ajá tún pada si ẽbì ara rẹ̀; ati ẹlẹdẹ ti a ti wẹ̀ mọ́ sinu àfọ ninu ẹrẹ̀.
II. Pet 2:5-22 Yoruba Bible (YCE)
Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò dáríjì àwọn ará àtijọ́, nígbà tí ó fi ìkún omi pa ayé run pẹlu àwọn tí wọn kò bẹ̀rù rẹ̀, àfi Noa, ọ̀kan ninu àwọn mẹjọ, tí ń waasu òdodo, ni ó gbà là. Bẹ́ẹ̀ tún ni ìlú Sodomu ati Gomora tí ó dá lẹ́bi, tí ó sì dáná sun. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ṣugbọn ó yọ Lọti tí ó jẹ́ olódodo eniyan, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí ìwàkiwà àwọn tí ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Nítorí ohun tí ojú rẹ̀ ń rí ati ohun tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ń ba ọkàn ọkunrin olódodo yìí jẹ́ lojoojumọ bí ó ti ń gbé ààrin àwọn eniyan burúkú yìí. Oluwa mọ ọ̀nà láti yọ àwọn olùfọkànsìn kúrò ninu ìdánwò, ṣugbọn ó pa àwọn alaiṣododo mọ́ de ìyà Ọjọ́ Ìdájọ́. Pàápàá jùlọ, yóo jẹ àwọn tí wọn ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn níyà. Wọ́n ń fojú tẹmbẹlu àwọn aláṣẹ. Ògbójú ni wọ́n, ati onigbeeraga; wọn kò bẹ̀rù láti sọ ìsọkúsọ sí àwọn ogun ọ̀run. Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn angẹli tí wọ́n ní agbára ati ipá ju eniyan lọ, kò jẹ́ sọ ìsọkúsọ sí wọn nígbà tí wọn bá ń mú wọn lọ fún ìdájọ́ Ọlọrun. Wọ́n dàbí ẹranko tí kò lè ronú, tí a bí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, tí a mú, tí a pa. Wọn a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ohun tí kò yé wọn. Ìparun yóo bá wọn ninu ọ̀nà ìparun wọn. Ibi ni wọn yóo jèrè lórí ibi tí wọn ń ṣe. Wọ́n ka ati máa ṣe àríyá ní ọ̀sán gangan sí ìgbádùn. Àbùkù ati ẹ̀gàn ni wọ́n láàrin yín. Ẹ̀tàn ni àríyá tí wọn ń ṣe nígbà tí ẹ bá jọ jókòó láti jẹun. Ojú wọn kún fún àgbèrè, kì í sinmi fún ẹ̀ṣẹ̀. Wọn a máa tan àwọn tí kò lágbára. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣá rí owó lọ́nàkọnà. Ọmọ ègún ni wọ́n. Wọ́n fi ọ̀nà títọ́ sílẹ̀, wọ́n ń ṣe ránun-rànun kiri. Wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, tí ó fẹ́ràn èrè aiṣododo. Ṣugbọn tí ó rí ìbáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹranko tí kò lè fọhùn sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó dí wolii náà lọ́wọ́ ninu ìwà aṣiwèrè rẹ̀. Wọ́n dàbí ìsun omi tí ó ti gbẹ, ati ìkùukùu tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri. Ọlọrun ti pèsè ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri fún wọn. Ọ̀rọ̀ kàǹkà-kàǹkà lásán, tí kò ní ìtumọ̀, ní ń ti ẹnu wọn jáde. Nípa ìwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ati ìwà ìbàjẹ́ wọn, wọ́n ń tan àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kúrò láàrin ìwà ìtànjẹ ti ẹgbẹ́ wọ́n àtijọ́ jẹ. Wọ́n ṣèlérí òmìnira fún àwọn eniyan, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹrú ohun ìbàjẹ́ wọn ni àwọn fúnra wọn jẹ́, nítorí tí ohunkohun bá ti borí eniyan, olúwarẹ̀ di ẹrú nǹkan náà. Nítorí bí wọ́n bá ti bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ ayé nípa mímọ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi, tí wọ́n tún wá pada sí ìwà àtijọ́, tí ìwà yìí bá tún borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn á wá burú ju ipò tí wọ́n wà lákọ̀ọ́kọ́ lọ. Nítorí ó sàn fún wọn kí wọn má mọ ọ̀nà òdodo ju pé kí wọn wá mọ̀ ọ́n tán kí wọn wá yipada kúrò ninu òfin mímọ́ tí a ti fi kọ́ wọn. Àwọn ni òtítọ́ òwe yìí ṣẹ mọ́ lára pé, “Ajá tún pada lọ kó èébì rẹ̀ jẹ.” Ati òwe kan tí wọn máa ń pa pé, “Ẹlẹ́dẹ̀ tí wọ́n fọ̀ nù yóo tún pada lọ yíràá ninu ẹrọ̀fọ̀.”