II. Pet 2:1-16
II. Pet 2:1-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN awọn woli eke wà lãrin awọn enia na pẹlu, gẹgẹ bi awọn olukọ́ni eke yio ti wà larin nyin, awọn ẹniti yio yọ́ mu adámọ ègbé wọ̀ inu nyin wá, ani ti yio sẹ́ Oluwa ti o rà wọn, nwọn o si mu iparun ti o yara kánkán wá sori ara wọn. Ọpọlọpọ ni yio si mã tẹle ìwa wọbia wọn; nipa awọn ẹniti a o fi mã sọ ọrọ-odi si ọ̀na otitọ. Ati ninu ojukòkoro ni nwọn o mã fi nyin ṣe ere jẹ nipa ọrọ ẹtàn: idajọ ẹniti kò falẹ̀ lati ọjọ ìwa, ìparun wọn kò si tõgbé. Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti nwọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi, ti o si fi wọn sinu ọgbun òkunkun biribiri awọn ti a pamọ́ de idajọ; Ti kò si dá aiye igbãni si, ṣugbọn o pa Noa pẹlu awọn meje miran mọ́, oniwasu ododo, nigbati o mu kikun omi wá sori aiye awọn alaiwà-bi-Ọlọrun; Ti o sọ awọn ilu Sodomu on Gomorra di ẽru, nigbati o fi ifọ́ afọbajẹ dá wọn lẹbi, ti o fi wọn ṣe apẹrẹ fun awọn ti yio jẹ alaiwà-bi-Ọlọrun; O si yọ Loti olõtọ, ẹniti ìwa wọbia awọn enia buburu bà ninu jẹ: (Nitori ọkunrin olõtọ nì bi o ti ngbe ãrin wọn, ti o nri, ti o si ngbọ́, lojojumọ ni ìwa buburu wọn mba ọkàn otitọ rẹ̀ jẹ́): Oluwa mọ̀ bi ã ti íyọ awọn ẹni ìwa-bi-Ọlọrun kuro ninu idanwo ati bi ã ti ípa awọn alaiṣõtọ ti a njẹ niya mọ dè ọjọ idajọ: Ṣugbọn pãpã awọn ti ntọ̀ ara lẹhin ninu ifẹkufẹ ẽri, ti nwọn si ngàn awọn ijoye, awọn ọ̀yájú, aṣe-tinuẹni, nwọn kò bẹ̀ru ati mã sọ̀rọ ẹgan si awọn oloye. Bẹni awọn angẹli bi nwọn ti pọ̀ ni agbara ati ipá tõ nì, nwọn kò dá wọn lẹjọ ẹ̀gan niwaju Oluwa. Ṣugbọn awọn wọnyi, bi ẹranko igbẹ́ ti kò li ero, ẹranko ṣa ti a dá lati mã mu pa, nwọn nsọ̀rọ ẹgan ninu ọran ti kò yé wọn; a o pa wọn run patapata ninu ibajẹ ara wọn. Nwọn o si jẹ ère aiṣododo, awọn ti nwọn kà a si aiye jijẹ lati mã jẹ adùn aiye li ọsán. Nwọn jẹ́ abawọn ati àbuku, nwọn njaiye ninu asè-ifẹ́ wọn nigbati nwọn ba njẹ ase pẹlu nyin; Awọn oloju ti o kún fun panṣaga, ti kò si le dẹkun ẹ̀ṣẹ idá; ti ntàn awọn ọkàn ti kò fi ẹsẹ mulẹ jẹ: awọn ti nwọn ni ọkàn ti o ti fi ojukòkoro kọ́ra; awọn ọmọ ègún: Nwọn kọ̀ ọ̀na ti o tọ́ silẹ, nwọn si ṣako lọ, nwọn tẹle ọ̀na Balaamu ọmọ Beori, ẹniti o fẹràn ère aiṣododo; Ṣugbọn a ba a wi nitori irekọja rẹ̀: odi kẹtẹkẹtẹ fi ohùn enia sọ̀rọ, o si fi opin si were wolĩ na.
II. Pet 2:1-16 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn bí àwọn wolii èké ti dìde láàrin àwọn eniyan Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni àwọn olùkọ́ni èké yóo wà láàrin yín. Wọn óo fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ mú ẹ̀kọ́kẹ́kọ̀ọ́ wọ ààrin yín. Wọn óo sẹ́ Oluwa wọn tí ó rà wọ́n pada, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀ wọn óo mú ìparun wá sórí ara wọn kíákíá. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo bá wọn kẹ́gbẹ́ ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn; nítorí ìṣe wọn, àwọn eniyan yóo máa gan ọ̀nà òtítọ́. Wọn óo fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín nítorí ojúkòkòrò, kí wọ́n lè fi yín ṣe èrè jẹ. Ìdájọ́ tí ó wà lórí wọn láti ìgbà àtijọ́ kò parẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìparun tí ń bọ̀ wá bá wọn kò sùn. Nítorí Ọlọrun kò dáríjì àwọn angẹli tí ó ṣẹ̀ ẹ́, ṣugbọn ó jù wọ́n sinu ọ̀gbun tí ó ṣókùnkùn biribiri ní ọ̀run àpáàdì títí di ọjọ́ ìdájọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun kò dáríjì àwọn ará àtijọ́, nígbà tí ó fi ìkún omi pa ayé run pẹlu àwọn tí wọn kò bẹ̀rù rẹ̀, àfi Noa, ọ̀kan ninu àwọn mẹjọ, tí ń waasu òdodo, ni ó gbà là. Bẹ́ẹ̀ tún ni ìlú Sodomu ati Gomora tí ó dá lẹ́bi, tí ó sì dáná sun. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò bẹ̀rù Ọlọrun. Ṣugbọn ó yọ Lọti tí ó jẹ́ olódodo eniyan, tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́ nítorí ìwàkiwà àwọn tí ń ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn. Nítorí ohun tí ojú rẹ̀ ń rí ati ohun tí etí rẹ̀ ń gbọ́ ń ba ọkàn ọkunrin olódodo yìí jẹ́ lojoojumọ bí ó ti ń gbé ààrin àwọn eniyan burúkú yìí. Oluwa mọ ọ̀nà láti yọ àwọn olùfọkànsìn kúrò ninu ìdánwò, ṣugbọn ó pa àwọn alaiṣododo mọ́ de ìyà Ọjọ́ Ìdájọ́. Pàápàá jùlọ, yóo jẹ àwọn tí wọn ń tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn lọ́rùn níyà. Wọ́n ń fojú tẹmbẹlu àwọn aláṣẹ. Ògbójú ni wọ́n, ati onigbeeraga; wọn kò bẹ̀rù láti sọ ìsọkúsọ sí àwọn ogun ọ̀run. Nígbà tí ó jẹ́ pé àwọn angẹli tí wọ́n ní agbára ati ipá ju eniyan lọ, kò jẹ́ sọ ìsọkúsọ sí wọn nígbà tí wọn bá ń mú wọn lọ fún ìdájọ́ Ọlọrun. Wọ́n dàbí ẹranko tí kò lè ronú, tí a bí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, tí a mú, tí a pa. Wọn a máa sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí ohun tí kò yé wọn. Ìparun yóo bá wọn ninu ọ̀nà ìparun wọn. Ibi ni wọn yóo jèrè lórí ibi tí wọn ń ṣe. Wọ́n ka ati máa ṣe àríyá ní ọ̀sán gangan sí ìgbádùn. Àbùkù ati ẹ̀gàn ni wọ́n láàrin yín. Ẹ̀tàn ni àríyá tí wọn ń ṣe nígbà tí ẹ bá jọ jókòó láti jẹun. Ojú wọn kún fún àgbèrè, kì í sinmi fún ẹ̀ṣẹ̀. Wọn a máa tan àwọn tí kò lágbára. Gbogbo ohun tí ó wà lórí ẹ̀mí wọn ni pé kí wọ́n ṣá rí owó lọ́nàkọnà. Ọmọ ègún ni wọ́n. Wọ́n fi ọ̀nà títọ́ sílẹ̀, wọ́n ń ṣe ránun-rànun kiri. Wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, tí ó fẹ́ràn èrè aiṣododo. Ṣugbọn tí ó rí ìbáwí fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ẹranko tí kò lè fọhùn sọ̀rọ̀ bí eniyan, ó dí wolii náà lọ́wọ́ ninu ìwà aṣiwèrè rẹ̀.
II. Pet 2:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé. Nítorí pé bi Ọlọ́run kò bá dá àwọn angẹli si nígbà tí wọn ṣẹ̀, ṣùgbọ́n ti ó sọ wọ́n sí ìsàlẹ̀ ọ̀run àpáàdì tí ó sì fi wọ́n sínú ọ̀gbun òkùnkùn biribiri nínú ìfipamọ́ títí dé ìdájọ́. Bí òun kò si dá ayé ìgbàanì sí, nígbà tí ó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn aláìwà-bí-Ọlọ́run, ṣùgbọ́n ó pa Noa mọ́, oníwàásù òdodo, pẹ̀lú àwọn ọmọ méje mìíràn. Tí ó sọ àwọn ìlú Sodomu àti Gomorra di eérú, nígbà tí ó fi ìparun pátápátá dá wọn lẹ́bi, tí ó fi wọ́n ṣe àpẹẹrẹ fún àwọn tí yóò jẹ́ aláìwà-bí-Ọlọ́run. Tí ó sì yọ Lọti olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí ìwà ẹ̀gbin àwọn ènìyàn láìlófin bà nínú jẹ́; (nítorí ọkùnrin olóòtítọ́ náà bí ó ti ń gbé àárín wọn, tí ó ń rí, tí ó sì ń gbọ́, lójoojúmọ́ ni ìwà búburú wọn ń bá ọkàn òtítọ́ rẹ̀ jẹ́) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, Olúwa mọ bí a tí ń yọ àwọn ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kúrò nínú ìdánwò àti bí a ti ń pa àwọn aláìṣòótọ́ mo fún ọjọ́ ìdájọ́ nígbà tí wọn yóò tẹ̀síwájú nínú ìjìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n pàápàá àwọn tí ó ń tọ ẹran-ara lẹ́yìn nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìwà èérí, tí wọ́n sì ń gan àwọn ìjòyè. Àwọn ọ̀dájú àti agbéraga, wọn kò bẹ̀rù láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí àwọn ẹni ògo. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn angẹli bí wọ́n ti pọ̀ ní agbára àti ipá tó o nì, wọn kò dá wọ́n lẹ́jọ́ ẹ̀gàn níwájú Olúwa. Ṣùgbọ́n àwọn wọ̀nyí, bí ẹranko igbó tí kò ní èrò, ẹranko sá á tí a dá láti máa mú pa, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nínú ọ̀rọ̀ tí kò yé wọn, a ó pa wọn run pátápátá nínú ìbàjẹ́ ara wọn. Wọn yóò gba ibi padà bí ibi tí wọ́n ti ṣe. Òye ìgbafẹ́ tí wọ́n ní láti máa jẹ adùn ayé. Wọ́n jẹ́ àbàwọ́n àti àbùkù, wọ́n ń jayé nínú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ń jẹ àsè pẹ̀lú yín. Ojú wọn kún fún panṣágà, wọn kò sì dẹ́kun ẹ̀ṣẹ̀ dídá; wọ́n ń tan àwọn tí ọkàn kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ jẹ; àwọn tí wọ́n ní ọkàn tí ó ti yege nínú wọ̀bìà, ọmọ ègún ni wọ́n. Wọ́n kọ ọ̀nà tí ó tọ́ sílẹ̀, wọ́n sì ṣáko lọ, wọ́n tẹ̀lé ọ̀nà Balaamu ọmọ Beori, ẹni tó fẹ́ràn èrè àìṣòdodo. Ṣùgbọ́n a bá a wí nítorí ìrékọjá rẹ̀, odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ fi ohùn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó sì fi òpin sí ìṣiwèrè wòlíì náà.