II. Pet 1:4-8
II. Pet 1:4-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ̀ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu ìwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin bá ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aiye nipa ifẹkufẹ. Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere; Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru; Ati ifẹ ọmọnikeji kún ìwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji. Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi ti nwọn bá si pọ̀, nwọn kì yio jẹ ki ẹ ṣe ọ̀lẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi.

II. Pet 1:4-8 Yoruba Bible (YCE)
Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé. Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí. Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà. Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ. Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi.
II. Pet 1:4-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi.