II. Pet 1:3-5
II. Pet 1:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá. Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé. Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí.
II. Pet 1:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere
II. Pet 1:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi agbara rẹ̀ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti ìye ati ti ìwa-bi-Ọlọrun, nipa ìmọ ẹniti o pè wa nipa ogo ati ọlanla rẹ̀: Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ̀ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu ìwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin bá ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aiye nipa ifẹkufẹ. Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere