II. Pet 1:1-21

II. Pet 1:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

SIMONI Peteru, iranṣẹ ati Aposteli Jesu Kristi, si awọn ti o ti gbà irú iyebiye igbagbọ́ kanna pẹlu wa, ninu ododo Ọlọrun wa ati ti Jesu Kristi Olugbala: Ki ore-ọfẹ ati alafia ki o mã bisi i fun nyin ninu ìmọ Ọlọrun, ati ti Jesu Oluwa wa, Bi agbara rẹ̀ bi Ọlọrun ti fun wa li ohun gbogbo ti iṣe ti ìye ati ti ìwa-bi-Ọlọrun, nipa ìmọ ẹniti o pè wa nipa ogo ati ọlanla rẹ̀: Nipa eyiti o ti fi awọn ileri rẹ̀ ti o tobi pupọ ti o si ṣe iyebiye fun wa: pe nipa iwọnyi ni ki ẹnyin ki o le di alabapin ninu ìwa Ọlọrun, nigbati ẹnyin bá ti yọ kuro ninu ibajẹ ti mbẹ ninu aiye nipa ifẹkufẹ. Ati nitori eyi nã pãpã, ẹ mã ṣe aisimi gbogbo, ẹ fi ìwarere kún igbagbọ́, ati ìmọ kún ìwarere; Ati airekọja kún ìmọ; ati sũru kún airekọja; ati ìwa-bi-Ọlọrun kún sũru; Ati ifẹ ọmọnikeji kún ìwa-bi-Ọlọrun; ati ifẹni kún ifẹ ọmọnikeji. Nitori bi ẹnyin bá ni nkan wọnyi ti nwọn bá si pọ̀, nwọn kì yio jẹ ki ẹ ṣe ọ̀lẹ tabi alaileso ninu ìmọ Oluwa wa Jesu Kristi. Nitori ẹniti o ba ṣe alaini nkan wọnyi, o fọju, kò le riran li òkẽre, o si ti gbagbé pe a ti wẹ̀ on nù kuro ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ atijọ. Nitorina, ará, ẹ tubọ mã ṣe aisimi lati sọ ìpe ati yiyàn nyin di dajudaju: nitori bi ẹnyin ba nṣe nkan wọnyi, ẹnyin kì yio kọsẹ lai. Nitori bayi li a ó pese fun nyin lọpọlọpọ lati wọ ijọba ainipẹkun ti Oluwa ati Olugbala wa Jesu Kristi. Nitorina emi ó mã mura lati mã mu nkan wọnyi wá si iranti nyin nigbagbogbo bi ẹnyin tilẹ ti mọ̀ wọn, ti ẹsẹ nyin si mulẹ ninu otitọ ti ẹnyin ni. Emi si rò pe o yẹ, niwọn igbati emi ba mbẹ ninu agọ́ yi, lati mã fi iranti rú nyin soke; Bi emi ti mọ̀ pe, bibọ́ agọ́ mi yi silẹ kù si dẹdẹ, ani bi Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mi. Emi o si mã ṣãpọn pẹlu, ki ẹnyin ki o le mã ranti nkan wọnyi nigbagbogbo lẹhin ikú mi. Nitori ki iṣe bi ẹniti ntọ ìtan asan lẹhin ti a fi ọgbọ́n-kọgbọn là silẹ, li awa fi agbara ati wíwá Jesu Kristi Oluwa wa hàn nyin, ṣugbọn ẹlẹri ọlá nla rẹ̀ li awa iṣe. Nitoriti o gbà ọlá on ogo lati ọdọ Ọlọrun Baba, nigbati irú ohùn nì fọ̀ si i lati inu ogo nla na wá pe, Eyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si jọjọ. Ohùn yi ti o ti ọrun wá li awa si gbọ́, nigbati awa mbẹ pẹlu rẹ̀ lori òke mimọ́ na. Awa si ni ọ̀rọ asọtẹlẹ ti o fẹsẹmulẹ jubẹ̃lọ; eyiti o yẹ ki ẹ kiyesi bi fitila ti ntàn ni ibi òkunkun, titi ilẹ yio fi mọ́, ti irawọ owurọ̀ yio si yọ li ọkàn nyin. Ki ẹ kọ́ mọ̀ eyi, pe kò si ọ̀kan ninu asọtẹlẹ inu iwe-mimọ́ ti o ni itumọ̀ ikọkọ. Nitori asọtẹlẹ kan kò ti ipa ifẹ enia wá ri; ṣugbọn awọn enia nsọrọ lati ọdọ Ọlọrun bi a ti ndari wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ wá.

II. Pet 1:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Èmi, Simoni Peteru iranṣẹ ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí wọn ní irú anfaani tí a níláti gbàgbọ́ bíi tiwa, nípa òdodo Ọlọrun wa ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia pọ̀ sí i fun yín nípa mímọ Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa. Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá. Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé. Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí. Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà. Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ. Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi. Afọ́jú ni ẹni tí kò bá ní àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ kò ríran jìnnà, kò sì lè ronú ẹ̀yìn-ọ̀la. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ti ṣe ní ẹ̀tọ́ láti rìn gaara wọ ìjọba ayérayé ti Oluwa wa, ati Olùgbàlà Jesu Kristi. Nítorí náà ni mo ṣe pinnu pé n óo máa ran yín létí gbogbo nǹkan wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ̀ wọ́n, ẹ sì ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu òtítọ́ tí ẹ ti mọ̀. Nítorí mo kà á sí ẹ̀tọ́ mi, níwọ̀n ìgbà tí mo wà ninu àgọ́ ara yìí, láti ji yín ninu oorun nípa rírán yín létí. Nítorí mo mọ̀ pé láìpẹ́ n óo bọ́ àgọ́ ara mi sílẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Oluwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. Ṣugbọn mò ń làkàkà pé nígbà tí mo bá lọ tán, kí ẹ ní ohun tí ẹ óo fi máa ṣe ìrántí nǹkan wọnyi nígbà gbogbo. Kì í ṣe ìtàn àròsọ ni a gbójú lé nígbà tí a sọ fun yín nípa agbára ati wíwá Oluwa wa Jesu Kristi, ṣugbọn ẹlẹ́rìí ọlá ńlá rẹ̀ ni a jẹ́. Nítorí a rí i nígbà tí ó gba ọlá ati ògo lọ́dọ̀ Ọlọrun Baba, nígbà tí ó gbọ́ ohùn láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ọlá ati ògo yẹ fún, tí ó wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ ọmọ mi, inú mi dùn sí ọ.” Àwa fúnra wa gbọ́ ohùn yìí nígbà tí ó wá láti ọ̀run nítorí a wà pẹlu rẹ̀ lórí òkè mímọ́ nígbà náà. A tún rí ẹ̀rí tí ó dájú ninu àsọtẹ́lẹ̀ àwọn wolii, pé, kí ẹ ṣe akiyesi ọ̀rọ̀ yìí, nítorí ó dàbí fìtílà tí ń tàn ninu òkùnkùn, títí ilẹ̀ yóo fi mọ̀, títí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóo fi tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ sinu ọkàn yín. Ṣugbọn kí ẹ kọ́kọ́ mọ èyí pé, kò sí àsọtẹ́lẹ̀ kan ninu Ìwé Mímọ́ tí ẹnìkan lè dá túmọ̀. Nítorí kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ ẹnikẹ́ni ni àsọtẹ́lẹ̀ kan fi wá, nípa Ẹ̀mí Mímọ́ ni àwọn eniyan fi ń sọ ọ̀rọ̀ tí ó ti ọ̀dọ̀ Oluwa wá.

II. Pet 1:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi, Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà. Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa. Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́. Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi. Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí. Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́ ara yìí. Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́ ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní, bí Olúwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. Èmi ó sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi. Nítorí kì í ṣe bí ẹni tí ó ń tọ ìtàn asán lẹ́yìn tí a fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n là sílẹ̀, nígbà tí àwa sọ fún yín ní ti agbára àti wíwá Jesu Kristi Olúwa, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí ọláńlá rẹ̀ ni àwa jẹ́. Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà. Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀. Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.