II. A. Ọba 9:1-7
II. A. Ọba 9:1-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
ELIṢA woli si pè ọkan ninu awọn ọmọ woli, o si wi fun u pe, Dì amurè ẹ̀gbẹ rẹ, ki o si mu igò ororo yi lọwọ rẹ, ki o si lọ si Ramoti-Gileadi: Nigbati iwọ ba si de ibẹ, ki iwọ ki o wá Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi li awari nibẹ, ki o si wọle, ki o si mu u ki o dide kuro lãrin awọn arakunrin rẹ̀, ki o si mu u lọ si yàra inu ile lọhun; Ki o si mu igò ororo na, ki o si tú u si ori rẹ̀, ki o si wipe, Bayi li Oluwa wipe, Emi fi ororo yàn ọ li ọba li ori Israeli. Si ṣi ilẹkun, ki o si sá, má si ṣe duro. Bẹ̃ni ọdọmọkunrin na, ani ọdọmọkunrin woli na, lọ si Ramoti-Gileadi. Nigbati o si debẹ, kiyesi i, awọn olori-ogun wà ni ijoko; on si wipe, Emi ni iṣẹ kan si ọ, balogun. Jehu si wipe, Si tani ninu gbogbo wa? On si wipe, Si ọ, balogun. On si dide, o si wọ̀ inu ile: o si tú ororo na si i li ori, o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti fi ororo yàn ọ li ọba lori enia Oluwa, lori Israeli. Iwọ o si kọlù ile Ahabu oluwa rẹ, ki emi o le gbẹsan ẹjẹ awọn woli iranṣẹ mi, ati ẹ̀jẹ gbogbo awọn iranṣẹ Oluwa lọwọ Jesebeli.
II. A. Ọba 9:1-7 Yoruba Bible (YCE)
Eliṣa pe ọ̀kan ninu àwọn ọmọ àwọn wolii, ó sọ fún un pé, “Ṣe kánkán, kí o lọ sí Ramoti Gileadi pẹlu ìgò òróró yìí. Nígbà tí o bá dé ibẹ̀, bèèrè Jehu, ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi; mú un wọ yàrá kan lọ kúrò láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀. Kí o da òróró inú ìgò yìí sí i lórí, kí o sì wí pé, OLUWA sọ pé, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Kí o sì yára sá kúrò níbẹ̀.” Ọdọmọkunrin wolii náà bá lọ sí Ramoti Gileadi. Nígbà tí ó dé ibẹ̀, ó bá àwọn olórí ogun níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé. Ó wí pé, “Balogun, wọ́n rán mi níṣẹ́ sí ọ.” Jehu bá bèèrè pé, “Ta ni ninu wa?” Ọdọmọkunrin náà bá dáhùn pé, “Ìwọ ni, Balogun.” Àwọn mejeeji bá jọ wọ inú yàrá lọ, ọdọmọkunrin wolii náà da òróró sí orí Jehu, ó sì wí pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Mo fi òróró yàn ọ́ ní ọba lórí Israẹli, àwọn eniyan OLUWA.’ O óo pa ìdílé oluwa rẹ, Ahabu ọba rẹ́, kí n lè gbẹ̀san lára Jesebẹli fún àwọn wolii mi ati àwọn iranṣẹ mi tí ó pa.
II. A. Ọba 9:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Wòlíì Eliṣa fi àṣẹ pe ọkùnrin kan láti ẹgbẹ́ àwọn wòlíì, ó sì wí fún un pé, “Ki agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè rẹ, gba ṣágo kékeré òróró yìí pẹ̀lú rẹ, kí o sì lọ sí Ramoti Gileadi. Nígbà tí o bá dé bẹ̀, wá Jehu ọmọ Jehoṣafati, ọmọ Nimṣi kiri. Lọ sí ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀, mú un kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀, kí o sì mú un wọ inú yàrá lọ́hùn ún lọ. Nígbà náà, mú ṣágo kékeré yìí, kí o sì da òróró náà lé e lórí, kí o sì wí pé, ‘Èyí ni ohun tí OLúWA wí: Èmi fi ààmì òróró yàn Ọ́ ní ọba lórí Israẹli.’ Nígbà náà, ṣí ìlẹ̀kùn, kí o sì sáré; Má ṣe jáfara!” Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀dọ́mọkùnrin náà, wòlíì náà lọ sí Ramoti Gileadi. Nígbà tí ó dé, ó rí àwọn olórí ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí wọ́n jókòó papọ̀. “Èmi ní iṣẹ́ fún ọ, olórí,” Ó wí. “Sí ta ni nínú wa?” Jehu béèrè. Òun sì wí pé, “Sí ọ, balógun,” Ó dáhùn. Jehu dìde sókè, ó sì wọ inú ilé lọ. Nígbà náà, wòlíì náà da òróró náà sórí Jehu; ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi fi ààmì òróró yàn ọ́ ní ọba lórí àwọn ènìyàn OLúWA Israẹli. Kí ìwọ kí ó pa ilé Ahabu ọ̀gá à rẹ̀ run, Èmi yóò sì gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì àti gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ OLúWA tí a ta sílẹ̀ látọwọ́ ọ Jesebeli.