II. A. Ọba 7:1-20

II. A. Ọba 7:1-20 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBANA ni Eliṣa wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa: Bayi li Oluwa wi, Ni iwòyi ọla li a o ta oṣùwọn iyẹ̀fun kikuna kan ni ṣekeli kan ni ẹnu bode Samaria. Nigbana ni ijòye kan li ọwọ ẹniti ọba nfi ara tì dá enia Ọlọrun li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, bi Oluwa tilẹ ṣí ferese li ọrun, nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀. Adẹtẹ̀ mẹrin kan si wà ni atiwọ̀ bodè; nwọn si wi fun ara wọn pe, Ẽṣe ti awa fi joko nihinyi titi awa o fi kú? Bi awa ba wipe, Awa o wọ̀ ilu lọ, iyàn si mbẹ ni ilu, awa o si kú nibẹ: bi awa ba si joko jẹ nihinyi, awa o kú pẹlu. Njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki awa ki o ṣubu si ọwọ ogun awọn ara Siria: bi nwọn ba dá wa si, awa o yè: bi nwọn ba si pa wa, awa o kú na ni. Nwọn si dide li afẹ̀mọjumọ lati lọ si ibùdo awọn ara Siria: nigbati nwọn si de apa ti o kangun ibùdo Siria, kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ. Nitori ti Oluwa ṣe ki ogun awọn ara Siria ki o gbọ́ ariwo kẹkẹ́, ati ariwo ẹṣin, ariwo ogun nla: nwọn si wi fun ara wọn pe, Kiyesi i, ọba Israeli ti bẹ̀ ogun awọn ọba Hitti, ati awọn ọba Egipti si wa, lati wá bò wa mọlẹ. Nitorina ni nwọn dide, nwọn si salọ ni afẹ̀mọjumọ, nwọn si fi agọ wọn silẹ, ati ẹṣin wọn, ati kẹtẹkẹtẹ wọn, ani, ibùdo wọn gẹgẹ bi o ti wà, nwọn si salọ fun ẹmi wọn. Nigbati adẹtẹ̀ wọnyi de apa ikangun bùdo, nwọn wọ inu agọ kan lọ, nwọn jẹ, nwọn si mu, nwọn sì kó fadakà ati wura ati agbáda lati ibẹ lọ, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́; nwọn si tún pada wá, nwọn si wọ̀ inu agọ miran lọ, nwọn si kó lati ibẹ lọ pẹlu, nwọn si lọ, nwọn si pa a mọ́. Nigbana ni nwọn wi fun ara wọn pe, Awa kò ṣe rere: oni yi, ọjọ ihinrere ni, awa si dakẹ: bi awa ba duro titi di afẹmọjumọ, iyà yio jẹ wa: njẹ nisisiyi ẹ wá, ẹ jẹ ki a si lọ isọ fun awọn ara ile ọba. Bẹ̃ni nwọn wá, nwọn si ke si awọn onibodè ilu; nwọn si wi fun wọn pe, Awa de bùdo awọn ara Siria, si kiyesi i, kò si ọkunrin kan nibẹ, bẹ̃ni kò si ohùn enia kan, bikòṣe ẹṣin ti a so, ati kẹtẹkẹtẹ ti a so, ati agọ bi nwọn ti wà. Ẹnikan si pè awọn onibodè; nwọn si sọ ninu ile ọba. Ọba si dide li oru, o si wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Emi o fi hàn nyin nisisiyi eyiti awọn ara Siria ti ṣe si wa. Nwọn mọ̀ pe, ebi npa wa; nitorina nwọn jade lọ ni bùdo lati fi ara wọn pamọ́ ni igbẹ wipe, Nigbati nwọn ba jade ni ilu, awa o mu wọn lãyè, awa o si wọ̀ inu ilu lọ. Ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀ si dahùn o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki awa ki o mu marun ninu ẹṣin ti o kù, ninu awọn ti o kù ni ilu, kiyesi i, nwọn sa dabi gbogbo ọ̀pọlọpọ Israeli ti o kù ninu rẹ̀; kiyesi i, ani bi gbogbo ọ̀pọlọpọ enia Israeli ti a run, si jẹ ki a ranṣẹ lọ iwò. Nitorina nwọn mu ẹṣin kẹkẹ́ meji; ọba si ranṣẹ tọ̀ ogun awọn ara Siria lẹhin, wipe, Ẹ lọ iwò. Nwọn si tọ̀ wọn lẹhin de Jordani: si wò o, gbogbo ọ̀na kún fun agbáda ati ohun elò ti awọn ara Siria gbé sọnù ni iyára wọn. Awọn onṣẹ si pada, nwọn si sọ fun ọba. Awọn enia si jade lọ, nwọn si kó ibùdo awọn ara Siria. Bẹ̃ni a ntà oṣùwọn iyẹ̀fun kikunná kan ni ṣekeli kan, ati oṣuwọn barle meji ni ṣekeli kan, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa. Ọba si yàn ijòye na, lọwọ ẹniti o nfi ara tì, lati ṣe itọju ẹnu bodè: awọn enia si tẹ̀ ẹ mọlẹ ni bodè, o si kú, bi enia Ọlọrun na ti wi, ẹniti o sọ̀rọ nigbati ọba sọ̀kalẹ tọ̀ ọ wá. O si ṣe, bi enia Ọlọrun na ti sọ fun ọba, wipe, Oṣùwọn barle meji fun ṣekeli kan, ati òṣuwọn iyẹfun kikunná kan, fun ṣekeli kan, yio wà ni iwòyi ọla ni ẹnu bodè Samaria: Ijòye na si da enia Ọlọrun na li ohùn, o si wipe, Kiyesi i, nisisiyi, bi Oluwa tilẹ ṣe ferese li ọrun, iru nkan yi ha le ri bẹ̃? On si wipe, Kiyesi i, iwọ o fi oju rẹ ri i, ṣugbọn iwọ kì yio jẹ ninu rẹ̀. Bẹ̃li o si ri fun u: nitori awọn enia tẹ̀ ẹ mọlẹ ni ẹnu bodè, o si kú.

II. A. Ọba 7:1-20 Yoruba Bible (YCE)

Eliṣa dáhùn pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ní àkókò yìí lọ́la, ní ẹnubodè Samaria, àwọn eniyan yóo ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan, tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kan.” Ọ̀kan ninu àwọn ọ̀gágun tí wọ́n wà níbẹ̀, tí ó jẹ́ aṣojú ọba dá Eliṣa lóhùn, ó ní, “Bí OLUWA bá tilẹ̀ da àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá, ǹjẹ́ ohun tí o sọ yìí lè rí bẹ́ẹ̀?” Eliṣa dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.” Àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin kan wà ní ẹnubodè Samaria, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Kí ló dé tí a óo fi dúró síbí títí tí a óo fi kú? Bí a bá lọ sinu ìlú ebi yóo pa wá kú nítorí ìyàn wà níbẹ̀, bí a bá sì dúró níbí, a óo kú bákan náà. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria. Bí wọ́n bá pa wá, a jẹ́ pé ikú yá, bí wọ́n bá sì dá wa sí, a óo wà láàyè.” Nígbà tí ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ sí pofírí, wọ́n lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọn kò rí ẹnìkan kan. OLUWA ti mú kí àwọn ọmọ ogun Siria gbọ́ ìró ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin ati ọpọlọpọ àwọn ọmọ ogun. Wọ́n wí fún ara wọn pé ọba Israẹli ti lọ bẹ àwọn ọmọ ogun Hiti ati ti Ijipti láti wá bá àwọn jà. Nítorí náà, wọ́n sá lọ ní àṣáálẹ́ ọjọ́ náà, wọ́n fi ibùdó ogun wọn ati àwọn ẹṣin wọn ati àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n sì sá àsálà fún ẹ̀mí wọn. Nígbà tí àwọn adẹ́tẹ̀ mẹrin náà dé ìkangun ibùdó ogun, wọ́n wọ inú àgọ́ kan lọ. Wọ́n jẹ ohun tí wọ́n bá níbẹ̀; wọ́n sì mu. Wọ́n kó fadaka ati wúrà ati aṣọ tí wọ́n rí níbẹ̀, wọ́n lọ kó wọn pamọ́. Wọ́n pada wá, wọ́n wọ inú àgọ́ mìíràn, wọ́n tún ṣe bákan náà. Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ohun tí à ń ṣe yìí kò dára, ọjọ́ ìròyìn ayọ̀ ni ọjọ́ òní. Bí a bá dákẹ́, tí a sì dúró di òwúrọ̀ a óo jìyà. Ẹ jẹ́ kí á lọ sọ fún àwọn ará ilé ọba.” Wọ́n bá lọ sí Samaria, wọ́n sì kígbe pe àwọn aṣọ́nà láti ẹnubodè pé, “A ti lọ sí ibùdó ogun àwọn ará Siria, a kò rí ẹnìkan kan níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò gbúròó ẹnìkan kan. Àwọn ẹṣin ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn wà bí wọ́n ṣe so wọ́n mọ́lẹ̀, gbogbo àwọn àgọ́ wọn sì wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Siria ti fi wọ́n sílẹ̀.” Àwọn aṣọ́nà bá sọ fún àwọn tí wọ́n wà ní ààfin ọba. Ọba dìde ní òru ọjọ́ náà, ó sọ fún àwọn olórí ogun rẹ̀ pé, “Mo mọ ète àwọn ará Siria. Wọ́n mọ̀ pé ìyàn mú ninu ìlú wa, nítorí náà ni wọ́n ṣe fi ibùdó ogun wọn sílẹ̀ láti sá pamọ́ sinu igbó, pẹlu èrò pé a óo wá oúnjẹ wá. Kí wọ́n lè mú wa láàyè, kí wọ́n sì gba ìlú wa.” Ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun náà dá ọba lóhùn pé, “Ṣebí àwọn eniyan náà yóo kú ni gẹ́gẹ́ bí àwọn tí wọ́n ti kú. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á rán àwọn ọkunrin kan pẹlu ẹṣin marun-un tí ó kù láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” Ọba sì rán ọkunrin meji pẹlu kẹ̀kẹ́ ogun meji láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Àwọn ọkunrin náà lọ títí dé odò Jọdani. Ní gbogbo ojú ọ̀nà náà ni wọ́n ti ń rí àwọn aṣọ ati àwọn ohun ìjà tí àwọn ará Siria jù sọnù nígbà tí wọn ń sá lọ. Wọ́n sì pada wá ròyìn fún ọba. Àwọn ará Samaria sì tú jáde láti lọ kó ìkógun ní ibùdó ogun àwọn ará Siria. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí OLUWA ti sọ, wọ́n ta òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan ní ìwọ̀n ṣekeli kan. Ọba Israẹli fi ìtọ́jú ẹnubodè ìlú sí abẹ́ àkóso ọ̀gágun tí ó jẹ́ aṣojú rẹ̀. Àwọn eniyan sì tẹ ọ̀gágun náà pa, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Nítorí nígbà tí eniyan Ọlọrun sọ fún ọba pé, “Ní ìwòyí ọ̀la, lẹ́nu bodè Samaria, àwọn eniyan yóo máa ra òṣùnwọ̀n ìyẹ̀fun kíkúnná kan tabi òṣùnwọ̀n ọkà baali meji ní ìwọ̀n ṣekeli kọ̀ọ̀kan,” ọ̀gágun náà dáhùn pé, “Ǹjẹ́ èyí lè ṣẹ, bí OLUWA tilẹ̀ rọ̀jò àwọn nǹkan wọnyi sílẹ̀ láti ojú ọ̀run wá.” Eliṣa sì dá a lóhùn pé, “O óo fi ojú rẹ rí i, ṣugbọn o kò ní jẹ ninu rẹ̀.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀ fún un, nítorí àwọn eniyan tẹ ọ̀gágun náà pa ní ẹnubodè ìlú.

II. A. Ọba 7:1-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Eliṣa wí pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLúWA. Èyí ni ohun tí OLúWA sọ: Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, a ó ta òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun barle kíkúnná kan ní ṣékélì kan àti méjì òṣùwọ̀n ọkà barle fún ṣékélì kan ní ẹnu-bodè Samaria.” Ìjòyè kan ẹni tí ọwọ́ ọba ń fi ara tì dáhùn wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Ẹ wò ó, tí OLúWA bá tilẹ̀ ṣí fèrèsé ọ̀run sílẹ̀, ṣé èyí lè rí bẹ́ẹ̀?” “Ìwọ yóò rí i pẹ̀lú ojú rẹ,” Eliṣa dáhùn, “ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ nǹkan kan lára rẹ̀!” Nísinsin yìí àwọn ọkùnrin mẹ́rin kan wà pẹ̀lú ẹ̀tẹ̀ ní ẹnu àbáwọlé ibodè ìlú. Wọ́n wí fún olúkúlùkù pé, “kí ni ó dé tí àwa yóò fi jókòó síbí títí àwa yóò fi kú? Tí àwa bá wí pé, ‘Àwa lọ sí ìlú, ìyàn wà níbẹ̀,’ àwa yóò sì kú. Tí àwa bá dúró níbí, a máa kú, ǹjẹ́ Nísinsin yìí ẹ jẹ́ kí a lọ sí ibùdó ti àwọn ará Siria kí àwa kí ó sì tẹríba. Bí wọ́n bá dá wa sí, àwa yóò yè, tí wọ́n bá sì pa wá, bẹ́ẹ̀ ni àwa yóò kú.” Ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n dìde wọ́n sì lọ sí ibùdó àwọn ará Siria. Nígbà tí wọ́n dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó náà, kò sí ọkùnrin kan níbẹ̀, nítorí tí Olúwa jẹ́ kí àwọn ará Siria gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, ọba Israẹli ti bẹ ogun àwọn Hiti àti àwọn ọba Ejibiti láti dojúkọ wá!” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn. Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní ààrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ. Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú. Nígbà náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Àwa kò ṣe ohun rere. Òní yìí jẹ́ ọjọ́ ìròyìn rere àwa sì pa á mọ́ ara wa. Tí àwa bá dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ìjìyà yóò jẹ́ ti wa. Ẹ jẹ́ kí a lọ ní ẹ̀ẹ̀kan kí a lọ ròyìn èyí fún àwọn ilé ọba.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ wọ́n sì pe àwọn asọ́bodè ìlú, wọ́n sì wí fún wọn pé, “Àwa lọ sí ibùdó àwọn ará Siria kò sì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ tàbí ohùn ènìyàn kan àyàfi ẹṣin tí a so àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgọ́ náà sì wà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà.” Àwọn aṣọ́bodè náà pariwo ìròyìn náà, wọ́n sì sọ nínú ààfin ọba. Ọba sì dìde ní òru ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò sọ fún yín ohun tí àwọn ará Siria tí ṣe fún wa. Wọ́n mọ̀ wí pé ebi ń pa wá; bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì ti kúrò ni ibùdó láti sápamọ́ sí ẹ̀gbẹ́ ilé, wọ́n rò wí pé, ‘Wọn yóò jáde lóòtítọ́, nígbà náà àwa yóò mú wọn ní ààyè, àwa yóò sì wọ inú ìlú lọ.’ ” Ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dáhùn pé, “Èmí o bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí àwa kí ó mú márùn-ún nínú àwọn ẹṣin tí ó kù, nínú àwọn tí ó kù ní ìlú—kíyèsí i, wọ́n sá dàbí gbogbo àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ Israẹli tí ó kù nínú rẹ̀, kíyèsí i, àní bí gbogbo ènìyàn Israẹli tí a run, sí jẹ́ kí a rán wọn lọ láti lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan kẹ̀kẹ́ méjì pẹ̀lú ẹṣin wọn, ọba sì ránṣẹ́ tọ ogun àwọn ará Siria lẹ́yìn ó pàṣẹ fún àwọn awakọ̀ pé, “Ẹ lọ kí ẹ lọ wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀.” Wọ́n sì tẹ̀lé wọn títí dé Jordani, wọ́n sì rí gbogbo ọ̀nà kún fún agbádá pẹ̀lú ohun èlò tí ará àwọn Siria gbé sọnù ní yàrá wọn. Ìránṣẹ́ náà padà ó sì wá sọ fún ọba. Nígbà náà àwọn ènìyàn jáde lọ ìkógun ní ibùdó àwọn ará Siria. Bẹ́ẹ̀ ni òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun kan ni wọ́n tà fún ṣékélì kan, àti òṣùwọ̀n barle méjì ní ṣékélì kan, gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ. Nísinsin yìí ọba sì mú ìjòyè náà lórí ẹni tí ó fi ọwọ́ ara rẹ̀ tì ní ìkáwọ́ ẹnu ibodè, àwọn ènìyàn sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè. Ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọtẹ́lẹ̀ nígbà tí ọba sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀. Ó sì ti ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọ́run ti sọ fún ọba: “Ní àsìkò yìí ní ọ̀la, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun ni a ó ta nì ṣékélì kan àti òṣùwọ̀n méjì barle ní ṣékélì kan ní ẹnu-ọ̀nà ibodè Samaria.” Ìjòyè náà ti wí fún ènìyàn Ọlọ́run pé, “Wò ó, kódà ti OLúWA bá ṣí fèrèsé ní ọ̀run, ṣé èyí lè ṣẹlẹ̀?” Ènìyàn Ọlọ́run sì ti dáhùn pé, “kìkì ojú rẹ ni ìwọ yóò fi rí i, Ṣùgbọ́n ìwọ kò ní jẹ ọ̀kankan lára rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí fún un gẹ́lẹ́, nítorí tí àwọn ènìyàn tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ẹnu ibodè, ó sì kú.