II. A. Ọba 5:3-5
II. A. Ọba 5:3-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
On si wi fun iya rẹ̀ pe, oluwa mi iba wà niwaju woli ti mbẹ ni Samaria! nitõtọ on iba wò o sàn kuro ninu ẹ̀tẹ rẹ̀. On si wọle, o si sọ fun oluwa rẹ̀ pe, Bayi bayi li ọmọdebinrin ti o ti ilẹ Israeli wá wi. Ọba Siria si wipe, Wá na, lọ, emi o si fi iwe ranṣẹ si ọba Israeli. On si jade lọ, o si mu talenti fàdakà mẹwa lọwọ, ati ẹgbãta iwọ̀n wurà, ati ipãrọ aṣọ mẹwa.
II. A. Ọba 5:3-5 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, ọmọbinrin náà sọ fún ọ̀gá rẹ̀ pé, “Bí oluwa mi Naamani bá lọ sí ọ̀dọ̀ wolii tí ó wà ní Samaria, yóo rí ìwòsàn gbà.” Nígbà tí Naamani gbọ́, ó sọ ohun tí ọmọbinrin náà sọ fún ọba. Ọba Siria dáhùn pé, “Tètè lọ, n óo sì fi ìwé ranṣẹ sí ọba Israẹli.” Naamani mú ìwọ̀n talẹnti fadaka mẹ́wàá ati ẹgbaata (6,000) ìwọ̀n ṣekeli wúrà ati ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá
II. A. Ọba 5:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sọ fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ọ̀gá mi lè rí wòlíì tí ó wà ní Samaria! Yóò wò ó sàn kúrò nínú ẹ̀tẹ̀ rẹ̀.” Naamani lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ̀ ó sì wí fún un ohun tí ọmọbìnrin Israẹli ti sọ. “Ní gbogbo ọ̀nà, lọ,” ọba Aramu dá a lóhùn pé, “Èmi yóò fi ìwé ránṣẹ́ sí ọba Israẹli.” Bẹ́ẹ̀ ni Naamani lọ, ó sì mú pẹ̀lú rẹ̀ tálẹ́ǹtì fàdákà mẹ́wàá, ẹgbẹ̀ta ìwọ̀n wúrà (6,000) àti ìpààrọ̀ aṣọ mẹ́wàá.