II. A. Ọba 4:8-37

II. A. Ọba 4:8-37 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si di ọjọ kan, Eliṣa si kọja si Ṣunemu, nibiti obinrin ọlọla kan wà; on si rọ̀ ọ lati jẹ onjẹ. O si ṣe, nigbakugba ti o ba nkọja lọ, on a yà si ibẹ lati jẹ onjẹ. On si wi fun ọkọ rẹ̀ pe, Sa wò o na, emi woye pe, enia mimọ́ Ọlọrun li eyi ti ngbà ọdọ wa kọja nigbakugba. Emi bẹ̀ ọ, jẹ ki a ṣe yàrá kekere kan lara ogiri; si jẹ ki a gbe ibùsùn kan sibẹ fun u, ati tabili kan, ati ohun-ijoko kan, ati ọpá-fitila kan: yio si ṣe, nigbati o ba tọ̀ wa wá, ki on ma wọ̀ sibẹ. O si di ọjọ kan, ti o wá ibẹ̀, o si yà sinu yàrá na, o si dubulẹ nibẹ. On si wi fun Gehasi iranṣẹ rẹ̀ pe, Pè ara Ṣunemu yi. Nigbati o si pè e, o duro niwaju rẹ̀. On si wi fun u pe, nisisiyi, sọ fun u pe, Kiyesi i, iwọ ti fi gbogbo itọju yi ṣe aniyàn wa; kini a ba ṣe fun ọ? Iwọ nfẹ́ ki a sọ̀rọ rẹ fun ọba bi? tabi fun olori-ogun? On si dahùn wipe, Emi ngbe lãrin awọn enia mi. On si wipe, Njẹ kini a ba ṣe fun u? Gehasi si dahùn pe, Nitõtọ, on kò li ọmọ, ọkọ rẹ̀ si di arugbo. On si wipe, Pè e wá, nigbati o si ti pè e de, o duro li ẹnu-ọ̀na. On si wipe, Li akokò yi gẹgẹ bi igba aiye, iwọ gbé ọmọkunrin kan mọra. On si wipe, Bẹ̃kọ̀, oluwa mi, iwọ enia Ọlọrun, má ṣe purọ fun iranṣẹbinrin rẹ. Obinrin na si loyun, o si bi ọmọkunrin kan li akokò na ti Eliṣa ti sọ fun u, gẹgẹ bi igba aiye. Nigbati ọmọ na si dagba, o di ọjọ kan, ti o jade tọ̀ baba rẹ̀ lọ si ọdọ awọn olukore. O si wi fun baba rẹ̀ pe, Ori mi, ori mi! On si sọ fun ọmọ-ọdọ̀ kan pe, Gbé e tọ̀ iya rẹ̀ lọ. Nigbati o si gbé e, ti o mu u tọ̀ iya rẹ̀ wá, o joko li ẽkun rẹ̀ titi di ọjọ kanri, o si kú. On si gòke, o si tẹ́ ẹ sori ibùsun enia Ọlọrun na, o si sé ilẹ̀kun mọ ọ, o si jade lọ. On si ke si ọkọ rẹ̀, o si wipe, Emi bẹ̀ ọ, rán ọkan ninu awọn ọdọmọkunrin si mi, ati ọkan ninu awọn kẹtẹkẹtẹ, emi o si sare tọ̀ enia Ọlọrun lọ, emi o si tun pada. On si wipe, Ẽṣe ti iwọ o fi tọ̀ ọ lọ loni? kì isa ṣe oṣù titun, bẹ̃ni kì iṣe ọjọ isimi. On sì wipe, Alafia ni. Nigbana li o di kẹtẹkẹtẹ ni gãri, o si wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Mã le e, ki o si ma nṣo; máṣe dẹ̀ ire fun mi, bikòṣepe mo sọ fun ọ. Bẹ̃li o lọ, o si de ọdọ enia Ọlọrun na li òke Karmeli. O si ṣe, nigbati enia Ọlọrun na ri i li okère, o si sọ fun Gehasi ọmọ ọdọ rẹ̀ pe, Wò ara Ṣunemu nì: Emi bẹ̀ ọ, sure nisisiyi ki o pade rẹ̀, ki o si wi fun u pe, Alafia ki o wà bi? alafia ki ọkọ rẹ̀ wà bi? alafia ki ọmọde wà bi? On si dahùn wipe, Alafia ni. Nigbati o si de ọdọ enia Ọlọrun li ori òke, o gbá a li ẹsẹ̀ mu: ṣugbọn Gehasi sunmọ ọ lati tì i kurò. Enia Ọlọrun na si wipe, Jọwọ rẹ̀ nitori ọkàn rẹ̀ bajẹ ninu rẹ̀, Oluwa si pa a mọ́ fun mi, kò si sọ fun mi. Nigbana li o wipe, Mo ha tọrọ ọmọ li ọwọ oluwa mi bi? Emi kò ha wipe, Máṣe tàn mi jẹ? O si wi fun Gehasi pe, Di àmure rẹ, ki o si mu ọpa mi li ọwọ rẹ, ki o si lọ, bi iwọ ba ri ẹnikẹni li ọ̀na, máṣe ki i; bi ẹnikeni ba si kí ọ, máṣe da a li ohùn: ki o si fi ọpá mi le iwaju ọmọ na. Iya ọmọ na si wipe, Bi Oluwa ti mbẹ, ati bi ẹmi rẹ ti mbẹ, emi kì o fi ọ silẹ. On si dide, o si ntọ̀ ọ lẹhin. Gehasi si kọja siwaju wọn, o si fi ọpá na le ọmọ na ni iwaju, ṣugbọn kò si ohùn, tabi afiyesi: nitorina o si tun pada lati lọ ipade rẹ̀, o si wi fun u pe, Ọmọ na kò ji. Nigbati Eliṣa si wọ̀ inu ile, kiyesi i, ọmọ na ti kú, a si tẹ́ ẹ sori ibùsun rẹ̀. O si wọ̀ inu ile lọ, o si se ilẹ̀kun mọ awọn mejeji, o si gbadura si Oluwa. On si gòke, o si dubulẹ le ọmọ na, o si fi ẹnu rẹ̀ le ẹnu rẹ̀, ati oju rẹ̀ le oju rẹ̀, ati ọwọ rẹ̀ le ọwọ rẹ̀: on si nà ara rẹ̀ le ọmọ na, ara ọmọ na si di gbigboná. O si pada, o si rìn lọ, rìn bọ̀ ninu ile lẹ̃kan; o si gòke, o si nà ara rẹ̀ le e; ọmọ na si sín nigba meje; ọmọ na si là oju rẹ̀. O si pè Gehasi, o si wipe, Pè ara Ṣunemu yi wá. O si pè e. Nigbati o si wọle tọ̀ ọ wá, o ni, Gbé ọmọ rẹ. Nigbana li o wọ̀ inu ile, o si wolẹ li ẹba ẹṣẹ̀ rẹ̀, o si dojubolẹ, o si gbé ọmọ rẹ̀, o si jade lọ.

II. A. Ọba 4:8-37 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu, níbi tí obinrin ọlọ́rọ̀ kan ń gbé; obinrin náà sì pe Eliṣa wọlé kí ó wá jẹun. Láti ìgbà náà, ilé obinrin yìí ni Eliṣa ti máa ń jẹun ní Ṣunemu. Obinrin náà sọ fún ọkọ rẹ̀ pé, “Mo wòye pé ọkunrin tí ó ń wá síbí yìí jẹ́ ẹni mímọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ kí á ṣe yàrá kékeré kan sí òkè ilé wa, kí á gbé ibùsùn, tabili, àga ati fìtílà sibẹ, kí ó lè máa dé sibẹ nígbàkúùgbà tí ó bá wá síbí.” Ní ọjọ́ kan tí Eliṣa pada lọ sí Ṣunemu, ó wọ inú yàrá náà lọ láti sinmi. Ó bá rán Gehasi iranṣẹ rẹ̀ kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó wọlé ó dúró níwájú Eliṣa. Eliṣa sọ fún Gehasi kí ó bèèrè lọ́wọ́ obinrin náà ohun tí ó fẹ́ kí òun ṣe fún un, fún gbogbo nǹkan tí ó ti ṣe fún àwọn. Ó ní, bóyá ó fẹ́ kí òun sọ ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ fún ọba ni tabi fún balogun? Obinrin náà dáhùn pé ààrin àwọn eniyan òun ni òun ń gbé. Eliṣa bá bèèrè lọ́wọ́ Gehasi pé, “Kí ni mo lè ṣe fún un nígbà náà?” Gehasi ní, “Kò bímọ, ọkọ rẹ̀ sì ti di arúgbó.” Eliṣa bá rán Gehasi kí ó pe obinrin náà wá. Nígbà tí ó dé, ó dúró ní ẹnu ọ̀nà. Eliṣa sọ fún un pé, “Níwòyí àmọ́dún, o óo fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọkunrin.” Obinrin náà dáhùn pé, “Háà! Oluwa mi, eniyan Ọlọrun ni ọ́, nítorí náà má ṣe parọ́ fún iranṣẹbinrin rẹ.” Ṣugbọn obinrin náà lóyún ó sì bí ọmọkunrin ní akoko náà ní ọdún tí ó tẹ̀lé e gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Eliṣa. Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí ọmọ náà dàgbà, ó lọ bá baba rẹ̀ ninu oko níbi tí wọ́n ti ń kórè. Lójijì, ó kígbe pe baba rẹ̀, ó ní, “Orí mi! Orí mi!” Baba rẹ̀ sì sọ fún iranṣẹ kan kí ó gbé ọmọ náà lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀. Nígbà tí iranṣẹ náà gbé ọmọ náà dé ọ̀dọ̀ ìyá rẹ̀, ìyá rẹ̀ gbé e lé ẹsẹ̀ títí ọmọ náà fi kú ní ọ̀sán ọjọ́ náà. Obinrin náà bá gbé òkú ọmọ náà lọ sí yàrá Eliṣa, ó tẹ́ ẹ sí orí ibùsùn rẹ̀, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì jáde. Ó kígbe pe ọkọ rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ rán iranṣẹ kan sí mi pẹlu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan. Mo fẹ́ sáré lọ rí eniyan Ọlọ́run, n óo pada dé kíákíá.” Ọkọ rẹ̀ bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ló dé tí o fi fẹ́ lọ rí i lónìí? Òní kì í ṣe ọjọ́ oṣù tuntun tabi ọjọ́ ìsinmi.” Ó sì dáhùn pé, “Kò séwu.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà ní gàárì tán, ó sọ fún iranṣẹ náà pé, “Jẹ́ kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà máa sáré dáradára, kí ó má sì dẹ̀rìn, àfi bí mo bá sọ pé kí ó má sáré mọ́.” Ó lọ bá Eliṣa ní orí òkè Kamẹli. Eliṣa rí i tí ó ń bọ̀ lókèèrè, ó bá sọ fún Gehasi, iranṣẹ rẹ̀, pé, “Wò ó! Obinrin ará Ṣunemu nì ni ó ń bọ̀ yìí! Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì bèèrè alaafia rẹ̀ ati ti ọkọ rẹ̀ ati ti ọmọ rẹ̀ pẹlu.” Obinrin náà dá Gehasi lóhùn pé, “Alaafia ni gbogbo wa wà.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì di ẹsẹ̀ rẹ̀ mú. Gehasi súnmọ́ ọn láti tì í kúrò, ṣugbọn Eliṣa wí fún un pé, “Fi obinrin náà sílẹ̀, ṣé o kò rí i pé inú rẹ̀ bàjẹ́ gidigidi ni? OLUWA kò sì bá mi sọ nǹkankan nípa rẹ̀.” Obinrin náà bá sọ fún Eliṣa pé, “Ǹjẹ́ mo tọrọ ọmọ lọ́wọ́ rẹ bí? Ǹjẹ́ n kò sọ fún ọ kí o má ṣe tàn mí jẹ?” Eliṣa bá sọ fún Gehasi pé, “Ṣe gírí, kí o mú ọ̀pá mi lọ́wọ́, kí o sì máa lọ. Bí o bá pàdé ẹnikẹ́ni lọ́nà, má ṣe kí i, bí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má dáhùn.” Nígbà náà ni ìyá ọmọ náà wí pé “Bí OLUWA tí ń bẹ láàyè tí ẹ̀mí ìwọ pàápàá sì ń bẹ, n kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Gehasi bá dìde, ó bá a lọ. Ó lọ fi ọ̀pá Eliṣa lé ọmọ náà lójú, ṣugbọn ọmọ náà kò jí. Ó bá pada lọ sọ fún Eliṣa pé ọmọ náà kò jí. Nígbà tí Eliṣa dé ilé náà, ó bá òkú ọmọ náà lórí ibùsùn. Ó wọlé síbi tí òkú ọmọ náà wà, ó ti ìlẹ̀kùn, ó sì gbadura sí OLUWA. Ó nà gbalaja lé ọmọ náà lórí, ó fẹnu kò ó lẹ́nu, ó fojú kò ó lójú, ó sì gbé ọwọ́ lé ọwọ́ rẹ̀. Bí ó sì ti nà lé ọmọ náà, ara ọmọ náà bẹ̀rẹ̀ sí lọ́ wọ́ọ́rọ́. Lẹ́yìn náà, ó dìde, ó rìn síwá sẹ́yìn ninu ilé náà, ó tún pada lọ nà lé ọmọ náà. Ọmọ náà sín lẹẹmeje, ó sì la ojú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó wí fún Gehasi pé kí ó pe obinrin ará Ṣunemu náà wá, Gehasi bá pè é. Nígbà tí obinrin náà dé, Eliṣa wí fún un pé kí ó gba ọmọ rẹ̀. Obinrin náà wólẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì dojúbolẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó mú ọmọ rẹ̀, ó sì jáde lọ.

II. A. Ọba 4:8-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkúgbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun. Ó sọ fún ọkọ rẹ̀, “Mo mọ̀ pé ọkùnrin tí ó máa ń sábà wá sí ọ̀dọ̀ wa jẹ́ ọkùnrin mímọ́ Ọlọ́run. Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùsùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti fìtílà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.” Ní ọjọ́ kan nígbà tí Eliṣa wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi pé, “Pe ará Ṣunemu.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀. Eliṣa wí fún un pé, “wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìhìnrere fún wa. Nísinsin yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ” “Ṣé a lè jẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?” “Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Eliṣa béèrè. Gehasi wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.” Nígbà náà Eliṣa wí pé, “Pè é,” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. Eliṣa sọ wí pé, “Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ.” “Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi!” n kò fi ara mọ́ ọn. “Jọ̀wọ́, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà!” Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ fún un. Ọmọ náà dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó wà pẹ̀lú àwọn olùkórè. “Orí mi! Orí mi!” Ó wí fún baba rẹ̀. Baba rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́, “Gbé e lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.” Lẹ́yìn ìgbà tí ìránṣẹ́ náà ti gbé e sókè tí ó sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ, ọmọ ọkùnrin náà jókòó sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi di ọ̀sán gangan, nígbà náà ó sì kú. Ó lọ sí òkè ó sì tẹ́ ọmọ náà lórí ibùsùn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì tìlẹ̀kùn, ó jáde lọ. Ó pe ọkọ rẹ̀ ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan kí èmi kí ó lè lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run kíákíá kí n sì padà.” “Kí ni ó dé tí o fi fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí?” Ó béèrè. “Kì í ṣe oṣù tuntun tàbí ọjọ́ ìsinmi.” Ó wí pé, “Gbogbo rẹ̀ ti dára.” Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Máa nìṣó; má ṣe dẹ́sẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì jáde wá, ó sì wá sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè Karmeli. Nígbà tí ó sì rí i láti òkèrè, ènìyàn Ọlọ́run sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi, “Wò ó! Ará Ṣunemu nì! Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáradára? Ṣé ọkọ rẹ wà dáradára? Ṣé ọmọ rẹ wà dáradára?’ ” Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáradára.” Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Gehasi wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, “Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú, Kíkorò, ṣùgbọ́n OLúWA fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi.” “Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, olúwa mi?” Obìnrin náà wí pé, “Ṣé mi ò sọ fún ọ pé kí o, ‘Má ṣe fa ìrètí mi sókè’?” Eliṣa wí fún Gehasi pé, “Ká agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè, mú ọ̀pá mi sí ọwọ́ rẹ kí o sì sáré. Tí o bá pàdé ẹnikẹ́ni má ṣe kí i, tí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má ṣe dá a lóhùn, fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ ọkùnrin náà.” Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti ń bẹ láààyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láààyè, èmi kò ní í fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e. Gehasi sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn tàbí ìdáhùn. Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi padà lọ láti lọ bá Eliṣa láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.” Nígbà tí Eliṣa dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. Ó sì wọ ilé, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí OLúWA. Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná. Eliṣa yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì ṣí ojú rẹ̀. Eliṣa sì pe Gehasi ó sì wí pé, “Pe ará Ṣunemu.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.” Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ síwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ Orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ.