II. A. Ọba 24:10-17

II. A. Ọba 24:10-17 Yoruba Bible (YCE)

Ní àkókò náà ni àwọn ọmọ ogun Nebukadinesari, ọba Babiloni, lọ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dó tì í. Ní àkókò tí wọ́n dó ti ìlú náà ni Nebukadinesari ọba Babiloni lọ sibẹ. Ní ọdún kẹjọ tí ọba Babiloni jọba ni Jehoiakini ọba Juda jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ọba Babiloni, ó sì jọ̀wọ́ ìyá rẹ̀, àwọn iranṣẹ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn òṣìṣẹ́ ààfin rẹ̀ pẹlu, ọba Babiloni bá kó wọn ní ìgbèkùn. Ó kó gbogbo àwọn ìṣúra ilé OLUWA ati àwọn ìṣúra tí ó wà ní ààfin. Gbogbo ohun èèlò wúrà tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA, tí Solomoni ọba Israẹli ṣe, ni ó gé sí wẹ́wẹ́, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti sọ tẹ́lẹ̀. Ó kó gbogbo Jerusalẹmu ní ìgbèkùn; gbogbo àwọn ìjòyè, àwọn akọni, àwọn oníṣẹ́ ọwọ́, ati àwọn alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ ẹgbaarun (10,000), kò ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan ní ìlú náà, àfi àwọn talaka. Ó kó ọba Jehoiakini, ati ìyá rẹ̀, ati àwọn aya rẹ̀, àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ ati àwọn ìjòyè ilẹ̀ náà ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babiloni. Ọba Babiloni kó ẹẹdẹgbaarin (7,000) àwọn akọni ní ìgbèkùn ati ẹgbẹrun kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọwọ́ ati alágbẹ̀dẹ, gbogbo wọn jẹ́ alágbára tí wọ́n lè jagun. Ó fi Matanaya, arakunrin Jehoiakini jọba dípò rẹ̀, ó sì yí orúkọ rẹ̀ pada sí Sedekaya.

II. A. Ọba 24:10-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní àkókò náà àwọn ìránṣẹ́ Nebukadnessari ọba Babeli gbé ogun wá Jerusalẹmu, wọ́n sì gbé dó ti ìlú náà, Nebukadnessari ọba Babeli fúnrarẹ̀ wá sókè sí ìlú nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ fi ogun dó tì í. Jehoiakini ọba Juda àti ìyá rẹ̀ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àti àwọn ìwẹ̀fà àti àwọn ìjòyè gbogbo wọn sì jọ̀wọ́ ara wọn fún un. Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀ ti ọba Babeli ó mú Jehoiakini ẹlẹ́wọ̀n. Gẹ́gẹ́ bí OLúWA ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé OLúWA àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún OLúWA. Ó kó wọn lọ sí ìgbèkùn gbogbo Jerusalẹmu: gbogbo ìjòyè àti àwọn akọni alágbára ọkùnrin, àti gbogbo oníṣọ̀nà àti ọlọ́nà tí àpapọ̀ rẹ̀ jẹ́ ẹgbàárùn-ún ún, àwọn tálákà ènìyàn ilẹ̀ náà nìkan ni ó kù. Nebukadnessari mú Jehoiakini ní ìgbèkùn lọ sí Babeli. Ó sì tún mú ìyá ọba láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, ìyàwó rẹ̀ àwọn ìjòyè rẹ̀ àti àwọn olórí ilé náà. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin ọlọ́lá tí ó jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) alágbára ọkùnrin, àti àwọn oníṣọ̀nà àti alágbẹ̀dẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000), gbogbo àwọn alágbára tí ó yẹ fún ogun ni ọba Babeli kó ní ìgbèkùn lọ sí Babeli Ọba Babeli sì mú Mattaniah arákùnrin baba Jehoiakini, jẹ ọba ní ìlú rẹ̀ ó sì yí orúkọ rẹ̀ padà sí Sedekiah.