II. A. Ọba 21:3-9
II. A. Ọba 21:3-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitoriti o tun kọ́ ibi giga wọnni ti Hesekiah baba rẹ̀ ti parun; o si tẹ́ pẹpẹ fun Baali o si ṣe ere-oriṣa, bi Ahabu, ọba Israeli ti ṣe, o si mbọ gbogbo ogun ọrun, o si nsìn wọn. O si tẹ́ pẹpẹ ni ile Oluwa, eyiti Oluwa ti sọ pe, Ni Jerusalemu li emi o fi orukọ mi si. On si tẹ́ pẹpẹ fun gbogbo ogun ọrun li agbalá mejeji ile Oluwa. On si mu ki ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná, a si mã ṣe akiyesi afọṣẹ, a si mã ṣe alupàyida, a si mã bá awọn okú ati awọn oṣó lò: o hùwa buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu. O si gbé ere oriṣa fifin kalẹ ti o ti ṣe ni ile na ti Oluwa sọ fun Dafidi ati Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, Ni ile yi, ati ni Jerusalemu, ti mo ti yàn ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, li emi o fi orukọ mi si lailai: Bẹ̃ni emi kì yio si jẹ ki ẹsẹ̀ Israeli ki o yẹ̀ kuro mọ ni ilẹ ti mo fi fun awọn baba wọn; kiki bi nwọn o ba ṣe akiyesi lati ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo pa li aṣẹ fun wọn, ati gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi pa li aṣẹ fun wọn. Ṣugbọn nwọn kò feti silẹ: Manasse si tàn wọn lati ṣe buburu jù eyiti awọn orilẹ-ède ti Oluwa ti parun niwaju awọn ọmọ Israeli ti ṣe.
II. A. Ọba 21:3-9 Yoruba Bible (YCE)
Ó tún àwọn ilé oriṣa tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti parun kọ́, ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún oriṣa Baali, ó sì gbẹ́ ère oriṣa Aṣera, bí Ahabu, ọba Israẹli, ti gbẹ́ ẹ. Ó sì ń bọ àwọn ìràwọ̀. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ oriṣa sinu ilé OLUWA, níbi tí OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli láti máa sin òun. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ fún àwọn ìràwọ̀ ninu àwọn àgbàlá mejeeji tí wọ́n wà ninu ilé OLUWA. Ó fi ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun, a máa ṣe àyẹ̀wò lọ́dọ̀ àwọn aláfọ̀ṣẹ, a sì máa ṣe àlúpàyídà. Bẹ́ẹ̀ ni ó máa ń wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn alásọtẹ́lẹ̀ ati àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó hùwà tí ó burú gidigidi níwájú OLUWA, ó sì rú ibinu OLUWA sókè. Ó gbẹ́ ère Aṣera tí ó gbé sinu ilé OLUWA, ibi tí OLUWA ti sọ fún Dafidi ati Solomoni pé, “Ninu ilé yìí, àní, ní Jerusalẹmu, ni mo yàn láàrin àwọn ìlú àwọn ẹ̀yà mejeejila Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ibi tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae. Ati pé bí àwọn ọmọ Israẹli bá júbà àṣẹ mi, tí wọ́n pa òfin mi, tí Mose, iranṣẹ mi, fún wọn mọ́, n kò ní jẹ́ kí á lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn.” Ṣugbọn àwọn ọmọ ilẹ̀ Juda kò júbà OLUWA, Manase sì mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tí ó burú ju èyí tí àwọn eniyan ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀ dá lọ, àní, àwọn tí OLUWA lé jáde kúrò níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
II. A. Ọba 21:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ Baali dìde, ó sì ṣe ère òrìṣà Aṣerah, gẹ́gẹ́ bí Ahabu ọba Israẹli ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n. Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún OLúWA, èyí tí OLúWA ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.” Ní àgbàlá méjèèjì ilé OLúWA, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú OLúWA, ó sì mú un bínú. Ó fi àwọn ọmọ ara rẹ̀ rú ẹbọ nínú iná, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú OLúWA láti mú un bínú. Ó sì gbé ère fínfín òrìṣà Aṣerah tí ó ti ṣe, ó sì gbé e sínú ilé OLúWA, èyí tí OLúWA ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé OLúWA yìí àti ní Jerusalẹmu, tí èmi ti yàn jáde lára gbogbo ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò kọ orúkọ mi títí láéláé. Èmi kò ní jẹ́ kí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli yẹ̀ kúrò láti ilẹ̀ tí èmi fi fún àwọn baba ńlá wọn tí ó bá jẹ́ wí pé wọn yóò ṣe àkíyèsí láti ṣe gbogbo ohun tí èmi ti paláṣẹ fún wọn kí wọn sì pa gbogbo òfin tí ìránṣẹ́ mi Mose fi fún wọn mọ́.” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà kò tẹ́tí. Manase tàn wọ́n síwájú, bẹ́ẹ̀ ni kí wọ́n lè ṣe búburú ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí OLúWA tí parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli lọ.