II. A. Ọba 1:7-17

II. A. Ọba 1:7-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

On si wi fun wọn pe, Iru ọkunrin wo li ẹniti o gòke lati pade nyin, ti o si sọ̀rọ wọnyi fun nyin? Nwọn si da a li ohùn pe, Ọkunrin Onirum li ara ni; o si dì àmure awọ mọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. On si wipe, Elijah ara Tiṣbi ni. Nigbana ni ọba rán olori-ogun ãdọta kan pẹlu ãdọta rẹ̀. O si gòke tọ̀ ọ lọ: si kiyesi i, o joko lori òke kan. On si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, ọba wipe, Sọ̀kalẹ. Elijah si dahùn, o si wi fun olori-ogun ãdọta na pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o run ọ ati ãdọta rẹ. Iná si sọ̀kalẹ ti ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀. On si tun rán olori-ogun ãdọta miran pẹlu ãdọta rẹ̀. On si dahùn o si wi fun u pe, Iwọ enia Ọlọrun, Bayi li ọba wi, yara sọ̀kalẹ. Elijah si dahùn, o si wi fun wọn pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o si run ọ ati ãdọta rẹ. Iná Ọlọrun si sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀. O si tun rán olori-ogun ãdọta ekẹta pẹlu ãdọta rẹ̀. Olori-ogun ãdọta kẹta si gòke, o si wá, o si wolẹ lori ẽkún rẹ̀ niwaju Elijah, o si bẹ̀ ẹ, o si wi fun u pe, Iwọ, enia Ọlọrun, emi bẹ̀ ọ́, jẹ ki ẹmi mi ati ẹmi awọn ãdọta ọmọ-ọdọ rẹ wọnyi, ki o ṣọwọn li oju rẹ. Kiyesi i, iná sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run olori-ogun meji arãdọta iṣãju pẹlu arãdọta wọn: njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹmi mi ki o ṣọwọn li oju rẹ. Angeli Oluwa si wi fun Elijah pe, Ba a sọ̀kalẹ lọ: máṣe bẹ̀ru rẹ̀. On si dide, o si ba a sọ̀kalẹ lọ sọdọ ọba. On si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, nitoriti iwọ ran onṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli lati bère ọ̀rọ rẹ̀? nitorina iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú; Bẹ̃ni o kú gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa ti Elijah ti sọ. Jehoramu si jọba ni ipò rẹ̀, li ọdun keji Jehoramu ọmọ Jehoṣafati, ọba Juda, nitoriti kò ni ọmọkunrin.

II. A. Ọba 1:7-17 Yoruba Bible (YCE)

Ọba bá bèèrè pé, “Irú ọkunrin wo ni ó wá pàdé yín lójú ọ̀nà, tí ó sọ bẹ́ẹ̀ fun yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Ọkunrin náà wọ aṣọ tí wọ́n fi awọ ẹranko ṣe, ó sì di àmùrè awọ mọ́ ẹ̀gbẹ́.” Ọba dáhùn pé, “Elija ará Tiṣibe ni.” Ọba bá rán ọ̀gágun kan ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀ kí wọ́n lọ mú Elija. Ọ̀gágun náà rí Elija níbi tí ó jókòó sí ní téńté òkè, ó sì wí fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá.” Elija sì dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. Ọba bá tún rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ-ogun rẹ̀ láti lọ mú Elija. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Elija òun náà tún sọ fún un pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun, ọba sọ pé kí o sọ̀kalẹ̀ wá kíákíá.” Elija tún dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀ kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ọba rán ọ̀gágun mìíràn ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ̀. Ṣugbọn ó gòkè lọ sọ́dọ̀ Elija, ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó bẹ̀ ẹ́ pé, “Ìwọ eniyan Ọlọrun jọ̀wọ́ mo bẹ̀ ọ́, ṣàánú fún mi ati fún àwọn iranṣẹ rẹ wọnyi, kí o sì dá ẹ̀mí wa sí. Iná tí ó wá láti ọ̀run ni ó pa àwọn ọ̀gágun meji ti iṣaaju ati àwọn ọmọ ogun wọn, nítorí náà mo bẹ̀ ọ́, dá ẹ̀mí mi sí.” Nígbà náà ni angẹli OLUWA sọ fún Elija pé kí ó bá wọn lọ, kí ó má sì bẹ̀rù. Elija bá bá a lọ sọ́dọ̀ ọba. Elija sọ fún ọba pé, báyìí ni OLUWA wí, “Nítorí pé o rán oníṣẹ́ láti lọ wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ Baalisebubu, oriṣa Ekironi, bí ẹni pé kò sí Ọlọrun ní Israẹli láti wádìí lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà, o kò ní sàn ninu àìsàn yìí, kíkú ni o óo kú.” Ahasaya sì kú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLUWA tí Elija sọ. Ṣugbọn nítorí pé kò ní ọmọkunrin kankan Joramu, arakunrin rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀, ní ọdún keji tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati jọba ní Juda.

II. A. Ọba 1:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọba béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Irú ọkùnrin wo ni ó wá pàdé yín, tí ó sì sọ irú èyí fún un yín?” Wọ́n dáhùn pé, “Ó jẹ́ ọkùnrin tí ó wọ ẹ̀wù onírun lára pẹ̀lú ọ̀já àmùrè aláwọ tí ó gbà yíká ìbàdí rẹ̀.” Ọba sì wí pé, “Elijah ará Tiṣibi ni.” Ó sì rán balógun pẹ̀lú àwọn ẹgbẹ́ ogun àádọ́ta rẹ̀. Balógun náà sì gòkè tọ Elijah lọ, ẹni tí ó jókòó ní orí òkè, wọ́n sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, ọba wí pé, ‘Sọ̀kalẹ̀ wá!’ ” Elijah sì dá balógun lóhùn pé, “Tí ó bá jẹ́ wí pé ènìyàn Ọlọ́run ni mí, kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti òkè ọ̀run wá kí ó sì jó ìwọ àti àwọn àádọ́ta ọkùnrin rẹ!” Nígbà náà iná náà sì sọ̀kalẹ̀ wá láti òkè ọ̀run ó sì jó balógun àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Ọba sì tún rán balógun àádọ́ta pẹ̀lú àwọn ènìyàn àádọ́ta rẹ̀ sí Elijah. Balógun náà sì wí fún un pé, “Ènìyàn Ọlọ́run, èyí ni ohun tí ọba sọ, ‘Sọ̀kalẹ̀ kánkán!’ ” “Tí èmi bá jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run,” Elijah sì dáhùn, “Ǹjẹ́ kí iná kí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run kí ó sì jó ọ run àti àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ!” Nígbà náà iná Ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run ó sì jó o run pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ènìyàn rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ọba tún rán balógun kẹta pẹ̀lú àwọn àádọ́ta ọkùnrin. Balógun ẹ̀ẹ̀kẹ́ta lọ sí òkè, ó sì kúnlẹ̀ lórí orókún rẹ̀ níwájú Elijah. “Ènìyàn Ọlọ́run,” Ó sì bẹ̀bẹ̀ pé, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, jọ̀wọ́ jẹ́ kí ẹ̀mí mi àti ẹ̀mí àwọn àádọ́ta ìránṣẹ́ rẹ wọ̀nyí ṣọ̀wọ́n ní ojú rẹ! Wò ó, iná ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti jó àwọn balógun méjì àràádọ́ta àkọ́kọ́ pẹ̀lú àràádọ́ta wọn. Ṣùgbọ́n Nísinsin yìí ní ojúrere fún ẹ̀mí mi!” Angẹli OLúWA sọ fún Elijah pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀; má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Elijah dìde ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ pẹ̀lú rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba. Ó sọ fún ọba pé, “Èyí ni ohun tí OLúWA wí: Ṣé nítorí wí pé kò sí Ọlọ́run ní Israẹli fún ọ láti pè ni ìwọ fi rán ìránṣẹ́ lọ sí ọ̀dọ̀ Baali-Sebubu, òrìṣà Ekroni láti lọ ṣe ìwádìí? Nítorí pé o ṣe èyí, ìwọ kò ní dìde lórí ibùsùn tí o dùbúlẹ̀ lé láìsí àní àní ìwọ yóò kú!” Bẹ́ẹ̀ ó sì kú, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ OLúWA tí Elijah ti sọ. Nítorí Ahasiah kò ní ọmọ, Jehoramu jẹ ọba ní ọdún kejì tí Jehoramu ọmọ Jehoṣafati ọba Juda.