II. A. Ọba 1:12
II. A. Ọba 1:12 Yoruba Bible (YCE)
Elija tún dáhùn pé, “Bí mo bá jẹ́ eniyan Ọlọrun, kí iná wá láti ọ̀run, kí ó sì jó ìwọ ati àwọn aadọta ọmọ ogun rẹ!” Lẹ́sẹ̀ kan náà, iná wá láti ọ̀run, ó sì jó ọ̀gágun náà ati gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀.
II. A. Ọba 1:12 Bibeli Mimọ (YBCV)
Elijah si dahùn, o si wi fun wọn pe, Bi emi ba ṣe enia Ọlọrun, jẹ ki iná ki o sọ̀kalẹ lati ọrun wá, ki o si run ọ ati ãdọta rẹ. Iná Ọlọrun si sọ̀kalẹ lati ọrun wá, o si run u ati ãdọta rẹ̀.