II. Kor 9:6-9
II. Kor 9:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn eyi ni mo wipe, Ẹniti o ba funrugbin kiun, kiun ni yio ká; ẹniti o ba si funrugbin, pupọ, pupọ ni yio ká. Ki olululuku enia ki o ṣe gẹgẹ bi o ti pinnu li ọkàn rẹ̀; kì iṣe àfẹ̀kùnṣe, tabi ti alaigbọdọ má ṣe: nitori Ọlọrun fẹ oninudidun ọlọrẹ. Ọlọrun si le mu ki gbogbo ore-ọfẹ ma bisi i fun nyin; ki ẹnyin, ti o ni anito ohun gbogbo nigbagbogbo, le mã pọ̀ si i ni iṣẹ́ rere gbogbo: (Gẹgẹ bi a ti kọ ọ pe, O ti fọnka; o ti fifun awọn talakà: ododo rẹ̀ duro lailai.
II. Kor 9:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ ranti pé ẹni tí ó bá fúnrúgbìn díẹ̀, díẹ̀ ni yóo kórè. Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn pupọ, pupọ ni yóo kórè. Kí olukuluku ṣe bí ó bá ti pinnu ninu ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹlu ìkanra, tabi àfipáṣe, nítorí onínúdídùn ọlọ́rẹ ni Ọlọrun fẹ́. Ọlọrun lè fun yín ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn, tí ẹ óo fi ní ànító ninu ohun gbogbo nígbà gbogbo. Ẹ óo sì tún ní tí yóo ṣẹ́kù fún ohun rere gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Ẹnìkan lawọ́, ó ń ta àwọn talaka lọ́rẹ, iṣẹ́ àánú rẹ̀ wà títí.”
II. Kor 9:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé: Ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé: “Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà; Òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”