II. Kor 9:11-15
II. Kor 9:11-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ti a ti sọ di ọlọrọ̀ ninu ohun gbogbo, fun ilawọ gbogbo ti nṣiṣẹ ọpẹ si Ọlọrun nipa wa. Nitori iṣẹ-iranṣẹ ìsin yi kò fi kun iwọn aini awọn enia mimọ́ nikan, ṣugbọn o tubọ pọ si i nipa ọ̀pọlọpọ ọpẹ́ si Ọlọrun, Lẹhin ti nwọn fi iṣẹ-isin yi dan nyin wo, nwọn yin Ọlọrun li ogo fun itẹriba ijẹwọ́ nyin si ihinrere Kristi, ati fun ilàwọ ìdawó nyin fun wọn ati fun gbogbo enia; Nigbati awọn tikarawọn pẹlu ẹ̀bẹ nitori nyin nṣafẹri nyin nitori ọpọ ore-ọfẹ Ọlọrun ti mbẹ ninu nyin. Ọpẹ́ ni fun Ọlọrun nitori alailesọ ẹ̀bun rẹ̀.
II. Kor 9:11-15 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ óo jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní gbogbo ọ̀nà tí ẹ óo fi lè máa lawọ́ nígbà gbogbo. Ọpọlọpọ eniyan yóo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà tí a bá fún wọn ní ẹ̀bùn tí ẹ gbé kalẹ̀ nítorí ìlawọ́ yín. Nítorí kì í ṣe àìní àwọn onigbagbọ nìkan ni iṣẹ́ ìsìn yìí yóo pèsè fún, ṣugbọn yóo mú kí ọpọlọpọ eniyan máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun. Nítorí iṣẹ́ yìí jẹ́ ẹ̀rí tí àwọn eniyan yóo fi máa yin Ọlọrun fún rírẹ̀ tí ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ ní ìgbọràn gẹ́gẹ́ bí ìjẹ́wọ́ igbagbọ yín ninu ìyìn rere ti Kristi, ati nítorí ìlawọ́ yín ninu iṣẹ́ yìí fún wọn ati fún gbogbo onigbagbọ. Wọn yóo wá máa gbadura fun yín, ọkàn wọn yóo fà sọ́dọ̀ yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun lórí yín. Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun nítorí ẹ̀bùn rẹ̀ tí kò ní òǹkà.
II. Kor 9:11-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa. Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìhìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn. Àti nínú àdúrà fún un yín, ọkàn wọn ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín. Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀!