II. Kor 8:13-14
II. Kor 8:13-14 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori emi kò fẹ ki awọn ẹlomiran wà ni irọrun, ki o si jẹ ipọnju fun nyin, Ṣugbọn nipa idọgba, pe ki ọpọlọpọ ini nyin li akoko yi le ṣe ẹkún aini wọn, ki ọ̀pọlọpọ ini wọn pẹlu le ṣe ẹkún aini nyin: ki idọgba ki o le wà
II. Kor 8:13-14 Yoruba Bible (YCE)
Kì í ṣe pé, kí àwọn ẹlòmíràn má ṣe nǹkankan, kí ó jẹ́ pé ẹ̀yin nìkan ni ọrùn yóo wọ̀. Ṣugbọn ọ̀ràn kí ẹ jọ pín in ṣe ní dọ́gba-dọ́gba ni. Ní àkókò yìí, ọ̀pọ̀ tí ẹ ní yóo mú kí ẹ lè pèsè fún àìní àwọn tí ẹ̀ ń rànlọ́wọ́. Ní ọjọ́ iwájú, ọ̀pọ̀ tí àwọn náà bá ní yóo mú kí wọ́n lè pèsè fún àìní yín. Ọ̀rọ̀ ojuṣaaju kò ní sí níbẹ̀.
II. Kor 8:13-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí èmi kò fẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn wà ní ìrọ̀rùn, kí ó sì jẹ́ ìpọ́njú fún yín, ṣùgbọ́n pé nípa mímú dọ́gba, Ní àkókò yìí, pé kí àníṣẹ́kù yín lè ṣe déédé àìní wọn, kí àníṣẹ́kù tiwọn pẹ̀lú ba à lè ṣe déédé àìní yín: kí ìmúdọ́gba ba à lè wà.