II. Kor 8:1-6
II. Kor 8:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
PẸLUPẸLU, ará, awa nsọ fun nyin niti ore-ọfẹ Ọlọrun, ti a fifun awọn ijọ Makedonia; Bi o ti jẹ pe ninu ọpọ idanwò ipọnju, ọ̀pọlọpọ ayọ̀ wọn ati ibu aini wọn di pipọ si ọrọ̀ ilawọ wọn, Nitori mo jẹri pe gẹgẹ bi agbara wọn, ani ju agbara wọn, nwọn ṣe e lati ifẹ inu ara wọn, Nwọn nfi ẹ̀bẹ pipọ rọ̀ wa niti ẹbun ọfẹ yi, ati ti idapọ ninu iṣẹ-iranṣẹ fun awọn enia mimọ́: Ati eyi, ki iṣe bi awa ti rò rí, ṣugbọn nwọn tètekọ fi awọn tikarawọn fun Oluwa, ati fun wa, nipa ifẹ Ọlọrun; Tobẹ̃ ti awa fi gba Titu niyanju pe, bi o ti bẹ̀rẹ na, bẹ̃ni ki o si pari ẹbun ọfẹ yi ninu nyin pẹlu.
II. Kor 8:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ mọ ohun tí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ti ṣe láàrin àwọn ìjọ Masedonia. Wọ́n ní ọpọlọpọ ìdánwò nípa ìpọ́njú. Sibẹ wọ́n ní ayọ̀ pupọ. Wọ́n ṣe aláìní pupọ, sibẹ wọ́n lawọ́ gan-an. Nítorí mo jẹ́rìí pé wọ́n sa ipá wọn, wọ́n tilẹ̀ ṣe tayọ agbára wọn, tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n sì fi ṣe é. Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìwúrí ni wọ́n fi bẹ̀ wá pé kí á jẹ́ kí àwọn náà lọ́wọ́ ninu iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí fún àwọn onigbagbọ. Wọ́n tilẹ̀ ṣe ju bí a ti lérò lọ, nítorí pé ara wọn pàápàá ni wọ́n kọ́ gbé bùn wá, tí wọ́n sì yọ̀ǹda fún Ọlọrun nípa ìfẹ́ rẹ̀. Ìdí nìyí tí a fi gba Titu níyànjú pé, nígbà tí ó jẹ́ pé òun ni ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oore-ọ̀fẹ́ yìí láàrin yín, kí ó kúkú ṣe é parí.
II. Kor 8:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Pẹ̀lúpẹ̀lú, ará, àwa ń sọ fún yín ní ti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run tí a fífún àwọn ìjọ Makedonia; Bí ó ti jẹ́ pé a dán wọn wò nípa ìpọ́njú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ àti àìlódiwọ̀n àìní wọn ti kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìlawọ́ wọn. Nítorí mo jẹ́rìí pé gẹ́gẹ́ bí agbára wọn, àní ju agbára wọn, wọ́n ṣe é láti ìfẹ́ inú ara wọn. Wọ́n ń fi ẹ̀bẹ̀ púpọ̀ rọ̀ wá ní ti ẹ̀bùn àtinúwá yìí, láti ba à lè ní ìpín nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́. Àti èyí, kì í ṣe bí àwa tí rò rí, ṣùgbọ́n wọ́n tètè kọ́ fi àwọn fúnrawọn fún Olúwa, àti fún wá, nípa ìfẹ́ Ọlọ́run. Tó bẹ́ẹ̀ tí àwa fi gba Titu níyànjú pé, bí ó tí bẹ̀rẹ̀ náà, bẹ́ẹ̀ ni kí ó sì parí ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ yìí nínú yín pẹ̀lú.