II. Kor 5:6-9
II. Kor 5:6-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina awa ni igboiya nigbagbogbo, awa si mọ̀ pe, nigbati awa mbẹ ni ile ninu ara, awa kò si lọdọ Oluwa: (Nitoripe nipa igbagbọ́ li awa nrìn, kì iṣe nipa riri:) Mo ni, awa ni igboiya, awa si nfẹ ki a kuku ti inu ara kuro, ki a si le wà ni ile lọdọ Oluwa. Nitorina awa ndù u, pe bi awa ba wà ni ile tabi bi a kò si, ki awa ki o le jẹ ẹni itẹwọgbà lọdọ rẹ̀.
II. Kor 5:6-9 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà, a ní ìgboyà nígbà gbogbo. A mọ̀ pé níwọ̀n ìgbà tí a bá fi ara yìí ṣe ilé, a dàbí ẹni tí ó jáde kúrò lọ́dọ̀ Oluwa. Nítorí igbagbọ ni a fi ń gbé ìgbé-ayé wa, kì í ṣe ohun tí à ń fi ojú rí. Bí mo ti sọ, a ní ìgboyà. Inú wa ìbá sì dùn kí á kúrò ninu àgọ́ ti ara yìí, kí á bọ́ sinu ilé lọ́dọ̀ Oluwa. Nítorí èyí, kì báà jẹ́ pé a wà ninu ilé ti ibí, tabi kí á bọ́ sinu ilé ti ọ̀hún, àníyàn wa ni pé kí á sá jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Oluwa.
II. Kor 5:6-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Nítorí náà àwa ní ìgboyà nígbà gbogbo, àwa sì mọ̀ pé, nígbà tí àwa ń bẹ ní ilé nínú ara, àwa kò sí lọ́dọ̀ Olúwa. Àwa ń gbé nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe nípa rí rí. Mo ní, àwa ní ìgboyà, àwa sì ń fẹ́ kí a kúkú ti inú ara kúrò, kí a sì lè wà ní ilé lọ́dọ̀ Olúwa. Nítorí náà àwa ń ṣakitiyan, pé, bí àwa bá wà ní ilé tàbí bí a kò sí, kí àwa lè jẹ́ ẹni ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀.


