II. Kor 5:16-21
II. Kor 5:16-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina lati isisiyi lọ awa kò mọ̀ ẹnikan nipa ti ara mọ́; bi awa tilẹ ti mọ̀ Kristi nipa ti ara, ṣugbọn nisisiyi awa kò mọ̀ ọ bẹ̃ mọ́. Nitorina bi ẹnikẹni ba wà ninu Kristi, o di ẹda titun: ohun atijọ ti kọja lọ; kiyesi i, nwọn si di titun. Ohun gbogbo si ti ọdọ Ọlọrun wá, ẹniti o si ti ipasẹ Jesu Kristi ba wa laja sọdọ ara rẹ̀, ti o si ti fi iṣẹ-iranṣẹ ìlaja fun wa; Eyini ni pe, Ọlọrun wà nínu Kristi, o mba araiye làja sọdọ ara rẹ̀, kò si kà irekọja wọn si wọn lọrùn; o si ti fi ọ̀rọ ìlaja le wa lọwọ. Nitorina awa ni ikọ̀ fun Kristi, bi ẹnipe Ọlọrun nti ọdọ wa ṣipẹ fun nyin: awa mbẹ̀ nyin nipò Kristi, ẹ ba Ọlọrun làja. Nitori o ti fi i ṣe ẹ̀ṣẹ nitori wa, ẹniti kò mọ̀ ẹ̀ṣẹkẹṣẹ rí; ki awa le di ododo Ọlọrun ninu rẹ̀.
II. Kor 5:16-21 Yoruba Bible (YCE)
Àyọrísí gbogbo èyí ni pé, láti ìgbà yìí lọ, àwa kò tún ní wo ẹnikẹ́ni ní ìwò ti ẹ̀dá mọ́. Nígbà kan ìwò ti ẹ̀dá ni à ń wo Kristi, ṣugbọn a kò tún wò ó bẹ́ẹ̀ mọ́. Èyí ni pé nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà ninu Kristi, ó di ẹ̀dá titun. Ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. Ìgbé-ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì di titun. Iṣẹ́ Ọlọrun ni èyí láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin. Òun ni ó ti là wá níjà pẹlu ara rẹ̀ nípasẹ̀ Kristi. Òun kan náà ni ó tún fún wa ní iṣẹ́ ìlàjà ṣe. Iṣẹ́ náà ni pé Ọlọrun wà ninu Kristi, ó ń làjà láàrin aráyé ati ara rẹ̀. Kò ka àwọn ìwà àìṣedéédé wọn sí wọn lọ́rùn. Ó sì ti wá fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. Nítorí náà, a jẹ́ aṣojú fún Kristi. Ó dàbí ẹni pé àwa ni Ọlọrun ń lò láti fi bẹ̀ yín. A fi orúkọ Kristi bẹ̀ yín, ẹ bá Ọlọrun rẹ́. Kristi kò dẹ́ṣẹ̀. Sibẹ nítorí tiwa, Ọlọrun sọ ọ́ di ọ̀kan pẹlu ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí á lè di olódodo níwájú Ọlọrun nípa rẹ̀.
II. Kor 5:16-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà láti ìsinsin yìí lọ, àwa kò mọ ẹnìkan nípa ti ara mọ́; bí àwa tilẹ̀ ti mọ Kristi nípa ti ara, ṣùgbọ́n nísinsin yìí àwa kò mọ̀ ọ́n bẹ́ẹ̀ mọ́. Nítorí náà bí ẹnìkan bá wà nínú Kristi, ó di ẹ̀dá tuntun: ohun àtijọ́ ti kọjá lọ; kíyèsi i, ohun tuntun ti dé. Ohun gbogbo sì ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, ẹni tí ó sì tipasẹ̀ Jesu Kristi bá wa làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, tí ó sì ti fi iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìlàjà fún wa. Èyí ni pé, Ọlọ́run wà nínú Kristi, ó ń bá aráyé làjà sọ́dọ̀ ara rẹ̀, kò sí ka ìrékọjá wọn sí wọn lọ́rùn; ó sì ti fi ọ̀rọ̀ ìlàjà lé wa lọ́wọ́. Nítorí náà àwa ni ikọ̀ fún Kristi, bí ẹni pé Ọlọ́run ń ti ọ̀dọ̀ wa ṣìpẹ̀ fún yín: àwa ń bẹ̀ yín ní ipò Kristi, “Ẹ bá Ọlọ́run làjà,” Nítorí ó tí fi í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ nítorí wa, ẹni tí kò mọ ẹ̀ṣẹ̀kẹ́ṣẹ̀ rí: kí àwa lè di òdodo Ọlọ́run nínú rẹ̀.