II. Kor 4:6-7
II. Kor 4:6-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi. Ṣugbọn awa ni iṣura yi ninu ohun èlo amọ̀, ki ọlá nla agbara na ki o le ṣe ti Ọlọrun, ki o má ti ọdọ wa wá.
II. Kor 4:6-7 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi. Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa.
II. Kor 4:6-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá.