II. Kor 4:3-4
II. Kor 4:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn bi ihinrere wa ba si farasin, o farasin fun awọn ti o nù: Ninu awọn ẹniti ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́ di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti o logo, ẹniti iṣe aworan Ọlọrun, ki o máṣe mọlẹ ninu wọn.
Pín
Kà II. Kor 4II. Kor 4:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn tí ìyìn rere wa bá ṣókùnkùn, àwọn tí yóo ṣègbé ni ó ṣókùnkùn sí. Àwọn oriṣa ayé yìí ni wọ́n fọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú, tí ọkàn wọn kò fi lè gbàgbọ́. Èyí ni kò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kristi, tí ó lógo, kí ó tàn sí wọn lára; àní, Kristi tíí ṣe àwòrán Ọlọrun.
Pín
Kà II. Kor 4II. Kor 4:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ṣùgbọ́n báyìí, bí ìyìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìyìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn.
Pín
Kà II. Kor 4