II. Kor 4:16-17
II. Kor 4:16-17 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí náà ni a kò fi sọ ìrètí nù. Nítorí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti òde ń bàjẹ́, ṣugbọn ara wa ti inú ń di titun sí i lojoojumọ. Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ.
Pín
Kà II. Kor 4II. Kor 4:16-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori eyi ni ãrẹ̀ kò ṣe mu wa; ṣugbọn bi ọkunrin ti ode wa ba nparun, sibẹ ọkunrin ti inu wa ndi titun li ojojumọ́. Nitori ipọnju wa ti o fẹrẹ, ti iṣe fun iṣẹ́ju kan, o nṣiṣẹ ogo ainipẹkun ti o pọ̀ rekọja fun wa.
Pín
Kà II. Kor 4