II. Kor 4:1-15

II. Kor 4:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITORINA bi awa ti ni iṣẹ-iranṣẹ yi, gẹgẹ bi a ti ri ãnu gbà, ãrẹ̀ kò mu wa; Ṣugbọn awa ti kọ̀ gbogbo ohun ìkọkọ ti o ni itiju silẹ, awa kò rìn li ẹ̀tan, bẹ̃li awa kò fi ọwọ́ ẹ̀tan mu ọ̀rọ Ọlọrun; ṣugbọn nipa fifi otitọ hàn, awa nfi ara wa le ẹri-ọkàn olukuluku enia lọwọ niwaju Ọlọrun. Ṣugbọn bi ihinrere wa ba si farasin, o farasin fun awọn ti o nù: Ninu awọn ẹniti ọlọrun aiye yi ti sọ ọkàn awọn ti kò gbagbọ́ di afọju, ki imọlẹ ihinrere Kristi ti o logo, ẹniti iṣe aworan Ọlọrun, ki o máṣe mọlẹ ninu wọn. Nitori awa kò wãsu awa tikarawa, bikoṣe Kristi Jesu Oluwa; awa tikarawa si jẹ ẹrú nyin nitori Jesu. Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi. Ṣugbọn awa ni iṣura yi ninu ohun èlo amọ̀, ki ọlá nla agbara na ki o le ṣe ti Ọlọrun, ki o má ti ọdọ wa wá. A npọn wa loju niha gbogbo, ṣugbọn ara kò ní wa: a ndãmú wa, ṣugbọn a kò sọ ireti nù. A nṣe inunibini si wa, ṣugbọn a kò kọ̀ wa silẹ; a nrẹ̀ wa silẹ, ṣugbọn a kò si pa wa run; Nigbagbogbo awa nru ikú Jesu Oluwa kiri li ara wa, ki a le fi ìye Jesu hàn pẹlu li ara wa. Nitoripe nigbagbogbo li a nfi awa ti o wà lãyè fun ikú nitori Jesu, ki a le fi ìye Jesu hàn ninu ara kikú wa pẹlu. Bẹ̃ni ikú nṣiṣẹ ninu wa, ṣugbọn ìye ninu nyin. Awa li ẹmí igbagbọ́ kanna, gẹgẹ bi a ti kọ́ ọ pe, emi gbagbọ́, nitorina li emi ṣe sọ: awa pẹlu gbagbọ́, nitorina li awa si ṣe nsọ; Awa mọ̀ pe, ẹniti o jí Jesu Oluwa dide yio si jí wa dide pẹlu nipa Jesu, yio si mu wa wá iwaju rẹ̀ pẹlu nyin. Nitoripe tinyin li ohun gbogbo, ki ọpọ̀ ore-ọfẹ nipa awọn pipọ le mu ki ọpẹ di pipọ fun ogo Ọlọrun.

II. Kor 4:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Nítorí èyí, níwọ̀n ìgbà tí ó wu Ọlọrun ninu àánú rẹ̀ láti fi iṣẹ́ yìí fún wa ṣe, ọkàn wa kò rẹ̀wẹ̀sì. A ti kọ àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tíí máa ti eniyan lójú sílẹ̀. A kò hùwà ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò yí ọ̀rọ̀ Ọlọrun po. Ṣugbọn ọ̀nà tí a fi gba iyì ninu ẹ̀rí-ọkàn eniyan ati níwájú Ọlọrun ni pé à ń fi òtítọ́ hàn kedere. Ṣugbọn tí ìyìn rere wa bá ṣókùnkùn, àwọn tí yóo ṣègbé ni ó ṣókùnkùn sí. Àwọn oriṣa ayé yìí ni wọ́n fọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lójú, tí ọkàn wọn kò fi lè gbàgbọ́. Èyí ni kò jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ ìyìn rere Kristi, tí ó lógo, kí ó tàn sí wọn lára; àní, Kristi tíí ṣe àwòrán Ọlọrun. Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi. Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi. Ṣugbọn bí ìkòkò amọ̀ ni àwa tí ìṣúra yìí wà ninu wa rí, kí ó lè hàn gbangba pé Ọlọrun ni ó ní agbára tí ó tóbi jùlọ, kì í ṣe àwa. A ní oríṣìíríṣìí ìṣòro, ṣugbọn wọn kò wó wa mọ́lẹ̀; ọkàn wa ń dààmú, ṣugbọn a kò ṣe aláìní ìrètí. Àwọn eniyan ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣugbọn Ọlọrun kò fi wá sílẹ̀. Wọ́n gbé wa ṣubú, ṣugbọn wọn kò lè pa wá. À ń ru ikú Jesu káàkiri lára wa nígbà gbogbo, kí ìyè Jesu lè hàn lára wa. Nítorí pé nígbà gbogbo ni à ń fi ẹ̀mí wa wéwu nítorí Jesu, níwọ̀n ìgbà tí a wà láàyè, kí ìyè Jesu lè hàn ninu ẹran-ara wa tí yóo di òkú. Ó wá jẹ́ pé ikú ní ń ṣiṣẹ́ ninu wa, nígbà tí ìyè ń ṣiṣẹ́ ninu yín. Àkọsílẹ̀ kan sọ pé, “Mo gbàgbọ́, nítorí náà ni mo fi sọ̀rọ̀.” Nígbà tí ó ti jẹ́ pé a ní ẹ̀mí igbagbọ kan náà, àwa náà gbàgbọ́, nítorí náà ni a fi ń sọ̀rọ̀. A mọ̀ pé ẹni tí ó jí Oluwa Jesu dìde yóo jí àwa náà dìde pẹlu Jesu, yóo wá mú àwa ati ẹ̀yin wá sí iwájú rẹ̀. Nítorí tiyín ni gbogbo èyí, kí oore-ọ̀fẹ́ lè máa pọ̀ sí i fún ọpọlọpọ eniyan, kí ọpẹ́ yín lè máa pọ̀ sí i fún ògo Ọlọrun.

II. Kor 4:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítorí náà, níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé nípa àánú Ọlọ́run ni a rí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yìí gba, àárẹ̀ kò mú ọkàn wa rara; Ṣùgbọ́n àwa tí kọ gbogbo ohun ìkọ̀kọ̀ tí ó ní ìtìjú sílẹ̀, àwa kò rìn ní ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò fi ọwọ́ ẹ̀tàn mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nípa fífi òtítọ́ hàn, àwa ń fi ara wa le ẹ̀rí ọkàn olúkúlùkù ènìyàn lọ́wọ́ níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n báyìí, bí Ìhìnrere wa bá sí fi ara sin, ó fi ara sin fún àwọn tí ó ń ṣègbé. Nínú àwọn ẹni tí ọlọ́run ayé yìí ti sọ ọkàn àwọn aláìgbàgbọ́ dí afọ́jú, kí ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere Kristi tí ó lógo, ẹni tí í ṣe àwòrán Ọlọ́run, má ṣe mọ́lẹ̀ nínú wọn. Nítorí àwa kò wàásù àwa tìkára wa, bí kò ṣe Kristi Jesu Olúwa; àwa tìkára wa sì jẹ́ ẹrú yín nítorí Jesu. Nítorí Ọlọ́run ni ẹni tí ó wí pé, “Kí ìmọ́lẹ̀ ó tan láti inú òkùnkùn jáde,” òun ní ó ti ń tan mọ́lẹ̀ lọ́kàn wa, láti fún wa ní ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọ́run ní ojú Jesu Kristi. Ṣùgbọ́n àwa ní ìṣúra yìí nínú ohun èlò amọ̀, kí ọláńlá agbára náà lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kí ó má ṣe ti ọ̀dọ̀ wa wá. A ń pọ́n wa lójú níhà gbogbo, ṣùgbọ́n ara kò ni wá: a ń dààmú wa, ṣùgbọ́n a kò sọ ìrètí nù. A ń ṣe inúnibíni sí wa, ṣùgbọ́n a kò kọ̀ wá sílẹ̀; a ń rẹ̀ wá sílẹ̀ ṣùgbọ́n a kò pa wá run. Nígbà gbogbo àwa ń ru ikú Jesu Olúwa kiri ni ará wa, kí a lè fi ìyè Jesu hàn pẹ̀lú lára wa. Nítorí pé nígbà gbogbo ní a ń fi àwa tí ó wà láààyè fún ikú nítorí Jesu, kí a lè fi ìyè hàn nínú ara kíkú wa pẹ̀lú. Bẹ́ẹ̀ ni ikú ń ṣiṣẹ́ nínú wa, ṣùgbọ́n ìyè ṣiṣẹ́ nínú yín. Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ pé, “Èmi gbàgbọ́, nítorí náà ni èmi ṣe sọ,” pẹ̀lú ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, a tún gbàgbọ́ àti nítorí náà ni àwa sì ṣe ń sọ. Àwa mọ̀ pé, ẹni tí o jí Jesu Olúwa dìde yóò sì jí wa dìde pẹ̀lú nípa Jesu, yóò sì mú wa wà níwájú rẹ̀ pẹ̀lú yín Nítorí tiyín ní gbogbo rẹ̀, ki ọ̀pẹ lè dí púpọ̀ fún ògo Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ ti ń gbòòrò sí i fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn.