II. Kor 3:3-7
II. Kor 3:3-7 Bibeli Mimọ (YBCV)
Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran. Irú igbẹkẹle yi li awa si ni nipa Kristi sọdọ Ọlọrun: Kì iṣe pe awa to fun ara wa lati ṣirò ohunkohun bi ẹnipe lati ọdọ awa tikarawa; ṣugbọn lati ọdọ Ọlọrun ni tito wa; Ẹniti o mu wa tó bi iranṣẹ majẹmu titun; kì iṣe ti iwe, bikoṣe ti ẹmí: nitori iwe a mã pani, ṣugbọn ẹmí a mã sọni di ãye. Ṣugbọn bi iṣẹ-iranṣẹ ti ikú, ti a ti kọ ti a si ti gbẹ́ si ara okuta, ba jẹ ologo, tobẹ̃ ti awọn ọmọ Israeli kò le tẹjumọ ati wò oju Mose, nitori ogo oju rẹ̀ (ogo nkọja lọ)
II. Kor 3:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran. Irú ìgbẹ́kẹ̀lé yìí ni àwa ní nípasẹ̀ Kristi sọ́dọ̀ Ọlọ́run: Kì í ṣe pé àwa tó fún ara wa láti ṣírò ohunkóhun bí ẹni pé láti ọ̀dọ̀ àwa tìkára wa; ṣùgbọ́n láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní tító wà; Ẹni tí ó mú wa yẹ bí ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun; kì í ṣe ní ti ìwé àkọsílẹ̀ ṣùgbọ́n ní ti ẹ̀mí, nítorí ìwé a máa pa ni, ṣùgbọ́n ẹ̀mí a máa sọ ní di ààyè. Ṣùgbọ́n bí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ikú, tí a tí kọ tí a sì ti gbẹ́ sí ara òkúta bá jẹ́ ológo tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè tẹjúmọ́ wíwo ojú Mose nítorí ògo ojú rẹ̀ (ògo ti ń kọjá lọ)
II. Kor 3:3-7 Yoruba Bible (YCE)
Ó hàn gbangba pé ẹ̀yin ni ìwé tí Kristi kọ, tí ó fi rán wa. Kì í ṣe irú èyí tí wọ́n fi yíǹkì kọ, Ẹ̀mí Ọlọrun alààyè ni wọ́n fi kọ ọ́. Kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sí orí òkúta; ọkàn eniyan ni wọ́n kọ ọ́ sí. A lè sọ èyí nítorí a ní igbẹkẹle ninu Ọlọrun nípa Kristi. Kì í ṣe pé a ní agbára tó ninu ara wa, tabi pé a ti lè ṣe nǹkankan fúnra wa. Ṣugbọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni a ti ní gbogbo nǹkan ní ànító. Ọlọrun ni ó mú kí á lè jẹ́ iranṣẹ ti majẹmu titun, tí kì í ṣe ti òfin tí a kọ bíkòṣe ti Ẹ̀mí. Nítorí ikú ni òfin tí a kọ sílẹ̀ ń mú wá, ṣugbọn majẹmu ti Ẹ̀mí ń sọ eniyan di alààyè. Bí òfin tí a kọ sí ara òkúta tí ó jẹ́ iranṣẹ ikú bá wá pẹlu ògo, tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ọmọ Israẹli kò lè ṣíjú wo Mose, nítorí ìmọ́lẹ̀ tí ń tàn ní ojú rẹ̀ fún àkókò díẹ̀