II. Kor 3:2-3
II. Kor 3:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin ni iwe wa, ti a ti kọ si wa li ọkàn, ti gbogbo enia ti mọ̀, ti nwọn sì ti kà: Bi a ti fi nyin hàn pe, iwe Kristi ni nyin, ti a nṣe iranṣẹ fun, kì iṣe eyiti a fi tadawa kọ, bikoṣe Ẹmí Ọlọrun alãye; kì iṣe ninu tabili okuta, bikoṣe ninu tabili ọkàn ẹran.
II. Kor 3:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin alára ni ìwé wa, tí a ti kọ sí ọkàn wa. Gbogbo eniyan ni wọ́n mọ ìwé yìí, tí wọ́n sì ń kà á. Ó hàn gbangba pé ẹ̀yin ni ìwé tí Kristi kọ, tí ó fi rán wa. Kì í ṣe irú èyí tí wọ́n fi yíǹkì kọ, Ẹ̀mí Ọlọrun alààyè ni wọ́n fi kọ ọ́. Kì í ṣe èyí tí wọ́n kọ sí orí òkúta; ọkàn eniyan ni wọ́n kọ ọ́ sí.
II. Kor 3:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ̀yin fúnrayín ni ìwé ìyìn wa, tí a ti kọ sí yín ní ọkàn, ti gbogbo ènìyàn mọ̀, tí wọ́n sì ń kà. Ẹ̀yin sì ń fihàn pé ìwé tí a gbà sílẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Kristi ni yín, kì í ṣe èyí tí a sì fi jẹ́lú kọ, bí kò sẹ Ẹ̀mí Ọlọ́run alààyè, kì í ṣe nínú wàláà òkúta bí kò ṣe nínú wàláà ọkàn ẹran.