II. Kor 2:14-16
II. Kor 2:14-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ọpẹ́ ni fun Ọlọrun, ẹniti nyọ̀ ayọ iṣẹgun lori wa nigbagbogbo ninu Kristi, ti o si nfi õrùn ìmọ rẹ̀ hàn nipa wa nibigbogbo. Nitori õrun didùn Kristi li awa jẹ fun Ọlọrun, ninu awọn ti a ngbalà, ati ninu awọn ti o nṣegbé: Fun awọn kan, awa jẹ õrun ikú si ikú, ati fun awọn miran õrun iyè. Tali o ha si to fun nkan wọnyi?
II. Kor 2:14-16 Yoruba Bible (YCE)
Ṣugbọn ọpẹ́ ni fún Ọlọrun tí ó jẹ́ kí á lè wà ninu àjọyọ̀ ìṣẹ́gun tí Kristi ṣẹgun, nígbà gbogbo. Ọlọrun náà ni ó tún ń mú kí ìmọ̀ rẹ̀ tí ń jáde láti ara wa máa gba gbogbo ilẹ̀ káàkiri bí òórùn dídùn níbi gbogbo. Nítorí àwa ni òórùn dídùn tí Kristi fi rúbọ sí Ọlọrun lọ́dọ̀ àwọn tí à ń gbàlà ati àwọn tí ń ṣègbé. Fún àwọn tí wọn ń ṣègbé, a dàbí òórùn tí n pani, ṣugbọn fún àwọn tí à ń gbàlà, a dàbí òórùn dídùn tí ó ń fún wọn ní ìyè. Ta ló tó ṣe irú iṣẹ́ yìí?
II. Kor 2:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé: Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí?