II. Kor 12:8-9
II. Kor 12:8-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi. On si wi fun mi pe, Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera. Nitorina tayọ̀tayọ̀ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mã gbe inu mi.
II. Kor 12:8-9 Yoruba Bible (YCE)
Ẹẹmẹta ni mo bẹ Oluwa nítorí rẹ̀ pé kí ó mú un kúrò lára mi. Ìdáhùn tí ó fún mi ni pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ. Ninu àìlera rẹ ni agbára mi di pípé.” Nítorí náà ninu àwọn ohun tí ó jẹ́ àìlera fún mi ni mo ní ayọ̀ pupọ jùlọ, àwọn ni n óo fi ṣe ìgbéraga, kí agbára Kristi lè máa bá mi gbé.
II. Kor 12:8-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi.