II. Kor 12:1-21
II. Kor 12:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
EMI ko le ṣe aiṣogo bi kò tilẹ ṣe anfani. Nitori emi ó wá si iran ati iṣipaya Oluwa. Emi mọ̀ ọkunrin kan ninu Kristi ni ọdún mẹrinla sẹhin, (yala ninu ara ni, emi kò mọ̀; tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀; Ọlọrun ni o mọ): a gbé irú enia bẹ̃ lọ si ọ̀run kẹta. Emi si ti mọ̀ irú ọkunrin bẹ̃, (yala li ara ni, tabi lati ara kuro ni, emi kò mọ̀: Ọlọrun mọ̀) Bi a ti gbé e lọ soke si Paradise, ti o si gbọ́ ọ̀rọ ti a kò le sọ, ti kò tọ́ fun enia lati mã sọ. Nipa irú ẹni bẹ̃ li emi ó ma ṣogo: ṣugbọn nipa ti emi tikarami emi kì yio ṣogo, bikoṣe ninu ailera mi. Nitoripe bi emi tilẹ nfẹ mã ṣogo, emi kì yio jẹ aṣiwère; nitoripe emi ó sọ otitọ: ṣugbọn mo kọ̀, ki ẹnikẹni ki o má bã fi mi pè jù ohun ti o ri ti emi jẹ lọ, tabi ju eyiti o gbọ lẹnu mi. Ati nitori ọ̀pọlọpọ iṣipaya, ki emi ki o má ba gbé ara mi ga rekọja, a si ti fi ẹgún kan si mi lara, iranṣẹ Satani, lati pọn mi loju, ki emi ki o má ba gberaga rekọja. Nitori nkan yi ni mo ṣe bẹ̀ Oluwa nigba mẹta pe, ki o le kuro lara mi. On si wi fun mi pe, Ore-ọfẹ mi to fun ọ: nitoripe a sọ agbara mi di pipé ninu ailera. Nitorina tayọ̀tayọ̀ li emi ó kuku ma ṣogo ninu ailera mi, ki agbara Kristi ki o le mã gbe inu mi. Nitorina emi ni inu didùn ninu ailera gbogbo, ninu ẹ̀gan gbogbo, ninu aini gbogbo, ninu inunibini gbogbo, ninu wahalà gbogbo nitori Kristi: nitori nigbati mo ba jẹ alailera, nigbana ni mo di alagbara. Mo di wère nipa ṣiṣogo; ẹnyin li o mu mi ṣe e: nitoriti o tọ́ ti ẹ ba yìn mi: nitoriti emi kò rẹ̀hin li ohunkohun si awọn Aposteli gigagiga na, bi emi kò tilẹ jamọ nkankan. Nitõtọ a ti ṣe iṣẹ àmi Aposteli larin nyin ninu sũru gbogbo, ninu iṣẹ àmi, ati iṣẹ iyanu, ati iṣẹ agbara. Nitori ninu kili ohun ti ẹnyin rẹ̀hin si ijọ miran, bikoṣe niti pe emi tikarami ko jẹ oniyọnu fun nyin? ẹ dari aṣiṣe yi ji mi. Kiyesi i, igba kẹta yi ni mo mura tan lati tọ̀ nyin wá; emi kì yio si jẹ oniyọnu fun nyin: nitoriti emi kò wá nkan nyin, bikoṣe ẹnyin tikaranyin: nitoriti kò tọ́ fun awọn ọmọ lati mã tò iṣura jọ fun awọn õbi wọn, bikoṣe awọn õbi fun awọn ọmọ wọn. Emi ó si fi ayọ̀ náwo, emi ó si ná ara mi fun ọkàn nyin nitõtọ; bi mo tilẹ fẹ nyin lọpọlọpọ, diẹ li a ha fẹran mi? Ṣugbọn o dara bẹ̃, ti emi kò dẹruba nyin: ṣugbọn bi ọlọgbọn, emi nfi ẹ̀rọ mu nyin. Emi ha rẹ́ nyin jẹ nipa ẹnikẹni ninu awọn ti mo rán si nyin bi? Mo bẹ̀ Titu, mo si rán arakunrin kan pẹlu rẹ̀; Titu ha rẹ́ nyin jẹ bi? nipa ẹmí kanna kọ́ awa rìn bi? ọ̀na kanna kọ́ awa tọ̀ bi? Ẹnyin ha rò pe ni gbogbo akoko yi àwa nṣe àwíjàre niwaju nyin? awa nsọ̀rọ niwaju Ọlọrun ninu Kristi: ṣugbọn awa nṣe ohun gbogbo, olufẹ ọwọn, lati mu nyin duro. Nitori ẹru mba mi pe, nigbati mo ba de, emi kì yio bá nyin gẹgẹ bi irú eyi ti mo fẹ, ati pe ẹnyin ó si ri mi gẹgẹ bi irú eyi ti ẹnyin kò fẹ: ki ija, owu-jijẹ, ibinu, ipinya, isọrọ-ẹni-lẹhin, ijirọsọ, igberaga, irukerudo, ki o má ba wà: Ati nigbati mo ba si pada de, ki Ọlọrun mi má ba rẹ̀ mi silẹ loju nyin, ati ki emi ki o má bã sọkun nitori ọpọlọpọ awọn ti o ti ṣẹ̀ na, ti nwọn kò si ronupiwada ẹ̀ṣẹ ìwa-ẽri, ati ti àgbere, ati ti wọ̀bia ti nwọn ti dá.
II. Kor 12:1-21 Yoruba Bible (YCE)
Ó yẹ kí n fọ́nnu. Rere kan kò ti ibẹ̀ wá, sibẹ n óo sọ ti ìran ati ìfarahàn Oluwa. Mo mọ ọkunrin onigbagbọ kan ní ọdún mẹrinla sẹ́yìn. Bí ó wà ninu ara ni o, bí ó rí ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé ọkunrin yìí lọ sí ọ̀run kẹta. Mo mọ ọkunrin yìí, bí ninu ara ni o, bí lójú ìran ni o, èmi kò mọ̀–Ọlọrun ni ó mọ̀. A gbé e lọ sí Paradise níbi tí ó gbé gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí kò ṣe é sọ, ọ̀rọ̀ àṣírí tí kò gbọdọ̀ jáde lẹ́nu eniyan. N óo fọ́nnu nípa irú ọkunrin bẹ́ẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò ní fọ́nnu nípa ara tèmi ati nípa àwọn àìlera mi. Bí mo bá fẹ́ fọ́nnu, kò ní jẹ́ ọ̀rọ̀ aṣiwèrè ni n óo sọ; òtítọ́ ni n óo sọ. Ṣugbọn n kò ní ṣe bẹ́ẹ̀, kí ẹnikẹ́ni má baà rò nípa mi ju ohun tí ó rí ninu ìwà mi ati ohun tí ó gbọ́ lẹ́nu mi lọ. Nítorí náà, kí n má baà ṣe ìgbéraga nípa àwọn ìfihàn tí ó ga pupọ wọnyi, a fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ẹ̀gún yìí jẹ́ iranṣẹ Satani, láti máa gún mi, kí n má baà gbéraga. Ẹẹmẹta ni mo bẹ Oluwa nítorí rẹ̀ pé kí ó mú un kúrò lára mi. Ìdáhùn tí ó fún mi ni pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ. Ninu àìlera rẹ ni agbára mi di pípé.” Nítorí náà ninu àwọn ohun tí ó jẹ́ àìlera fún mi ni mo ní ayọ̀ pupọ jùlọ, àwọn ni n óo fi ṣe ìgbéraga, kí agbára Kristi lè máa bá mi gbé. Nítorí èyí mo ní inú dídùn ninu àìlera mi, ati ninu àwọn ìwọ̀sí, ìṣòro, inúnibíni ati ìpọ́njú tí mo ti rí nítorí ti Kristi. Nítorí nígbà tì mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára. Mo ti di aṣiwèrè! Ẹ̀yin ni ẹ sì sọ mí dà bẹ́ẹ̀. Nítorí ìyìn ni ó yẹ kí n gbà lọ́dọ̀ yín. Nítorí bí n kò tilẹ̀ jẹ́ nǹkankan, n kò rẹ̀yìn ninu ohunkohun sí àwọn aposteli yín tí ẹ kà kún pataki. Àwọn àmì aposteli hàn ninu iṣẹ́ mi láàrin yín nípa oríṣìíríṣìí ìfaradà, nípa iṣẹ́ abàmì, iṣẹ́ ìyanu, ati iṣẹ́ agbára. Ọ̀nà wo ni a fi ba yín lò tí ó burú ju ti àwọn ìjọ ìyókù lọ; àfi ti pé èmi fúnra mi kò ni yín lára? Ẹ forí jì mí fún àṣìṣe yìí! Ẹ wò ó! Ẹẹkẹta nìyí tí mo múra tán láti wá sọ́dọ̀ yín. N kò sì ní ni yín lára. Nítorí kì í ṣe àwọn nǹkan dúkìá yín ni mo fẹ́ bíkòṣe ẹ̀yin fúnra yín. Nítorí kì í ṣe àwọn ọmọ ni ó yẹ láti pèsè fún àwọn òbí wọn. Àwọn òbí ni ó yẹ kí ó pèsè fún àwọn ọmọ. Ní tèmi, pẹlu ayọ̀ ni ǹ bá fi náwó-nára patapata fún ire ọkàn yín. Bí èmi bá fẹ́ràn yín pupọ, ṣé díẹ̀ ni ó yẹ kí ẹ̀yin fẹ́ràn mi? Ẹ gbà pé n kò ni yín lára. Ṣugbọn àwọn kan rò pé ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́ ni mí, ati pé ẹ̀tàn ni mo fi mu yín. Ninu àwọn tí mo rán si yín, èwo ni mo lò láti fi rẹ yín jẹ? Mo bẹ Titu kí ó wá sọ́dọ̀ yín. Mo tún rán arakunrin wa pẹlu rẹ̀. Ǹjẹ́ Titu rẹ yín jẹ bí? Ṣebí Ẹ̀mí kan náà ni ó ń darí wa? Tabi kì í ṣe ọ̀nà kan náà ni a jọ ń ṣiṣẹ́? Ṣé ohun tí ẹ ti ń rò ni pé à ń wí àwíjàre níwájú yín? Rárá o! Níwájú Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ ni à ń sọ̀rọ̀. Ẹ̀yin àyànfẹ́ mi, gbogbo nǹkan tí à ń ṣe, fún ìdàgbàsókè yín ni. Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà ti mo bá dé, mo lè má ba yín ní irú ipò tí mo fẹ́, ati pé ẹ̀yin náà lè rí i pé n kò rí bí ẹ ti ń rò. Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ohun tí n óo bá láàrin yín má jẹ́ ìjà ati owú jíjẹ, ibinu ati ìwà ọ̀kánjúwà, ọ̀rọ̀ burúkú ati ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga ati ìrúkèrúdò. Ẹ̀rù ń bà mí pé nígbà tí mo bá tún dé, kí Ọlọrun mi má dójú tì mí níwájú yín, kí n má ní ìbànújẹ́ nítorí ọpọlọpọ tí wọ́n ti ṣẹ̀ tẹ́lẹ̀ tí wọn kò ronupiwada kúrò ninu ìṣekúṣe, àgbèrè ati ìwà wọ̀bìà tí wọ́n ti ń hù.
II. Kor 12:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èmi kò lè ṣàì ṣògo bí kò tilẹ̀ ṣe àǹfààní, nítorí èmi ó wà sọ nípa ìran àti ìṣípáyà ti Olúwa fihàn mí. Èmi mọ ọkùnrin kan nínú Kristi ní ọdún mẹ́rìnlá sẹ́yìn, yálà nínú ara ni, èmi kò mọ̀; tàbí kúrò nínú ara, èmi kò mọ̀; Ọlọ́run mọ̀: a gbé irú ẹni náà lọ sí ọ̀run kẹta. Bẹ́ẹ̀ ni èmi mọ irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀, yálà ní ara ni, tàbí kúrò nínú ara ni, èmi kò mọ̀: Ọlọ́run mọ̀. Pé a gbé e lọ sókè sí Paradise, tí ó sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí a kò sì lè sọ, tí kò tọ́ fún ènìyàn láti máa sọ. Nípa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni èmi ó máa ṣògo: ṣùgbọ́n nípa ti èmi tìkára mi èmi kì yóò ṣògo, bí kò ṣe nínú àìlera mi. Nítorí pé bi èmi tilẹ̀ ń fẹ́ máa ṣògo, èmi kì yóò jẹ́ òmùgọ̀; nítorí pé èmi yóò sọ òtítọ́: ṣùgbọ́n mo kọ̀, kí ẹnikẹ́ni máa bà à fi mí pè ju ohun tí ó rí tí èmi jẹ́ lọ, tàbí ju èyí tí ó gbọ́ lẹ́nu mi, àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣípayá, kí èmi má ba à gbé ara mi ga rékọjá, a sì ti fi ẹ̀gún kan sí mi lára, ìránṣẹ́ Satani láti pọ́n mi lójú, kí èmi má bá a gbéraga rékọjá. Nítorí nǹkan yìí ni mo ṣe bẹ Olúwa nígbà mẹ́ta pé, kí ó lé e kúrò lára mi. Òun sì wí fún mi pé, “Oore-ọ̀fẹ́ mi tó fún ọ: nítorí pé a sọ agbára mi di pípé nínú àìlera.” Nítorí náà tayọ̀tayọ̀ ni èmi ó kúkú máa fi ṣògo nínú àìlera mi, kí agbára Kristi lè máa gbé inú mi. Nítorí náà èmi ní inú dídùn nínú àìlera gbogbo, nínú ẹ̀gàn gbogbo, nínú àìní gbogbo, nínú inúnibíni gbogbo, nínú wàhálà gbogbo nítorí Kristi. Nítorí nígbà tí mo bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára. Mo di òmùgọ̀ nípa ṣíṣògo; ẹ̀yin ní ó fi ipá mú mi ṣe é: nítorí tí ó tọ́ tí ẹ bá yìn mí: nítorí tí èmi kò rẹ̀yìn lóhunkóhun sí àwọn àgbà aposteli bí èmi kò tilẹ̀ jámọ́ nǹkan kan. Ohun kan tí ó ṣe ààmì aposteli, iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ agbára ni wọ́n ṣe ní àárín yín pẹ̀lú sùúrù tó ga. Nítorí nínú kín ni ohun tí ẹ̀yin ṣe rẹ̀yìn sí ìjọ mìíràn, bí kò ṣe ní ti pé èmi fúnra mi kó jẹ́ oníyọnu fún yín? Ẹ dárí àṣìṣe yìí jì mí. Kíyèsi i, ìgbà kẹta yìí ni mo múra tan láti tọ̀ yín wá: èmi kì yóò sì jẹ́ oníyọnu fún yín nítorí tí èmi kò wá nǹkan yín, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnrayín; nítorí tí kò tọ́ fún àwọn ọmọ láti máa to ìṣúra jọ fún àwọn òbí wọn, bí kò ṣe àwọn òbí fún àwọn ọmọ wọn. Èmi ó sì fi ayọ̀ ná ohun gbogbo tí mo bá ní, èmi ó sì ná ara mi fún ọkàn yín nítòótọ́; bí mo bá fẹ́ yín lọ́pọ̀lọpọ̀, ó ha tọ́ kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn mi díẹ̀ bí? Ṣùgbọ́n ó dára bẹ́ẹ̀ tí èmi kò dẹ́rùbà yín: ṣùgbọ́n bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn, èmi ń fi ọwọ́ ẹ̀rọ̀ mú yín. Èmi ha rẹ́ yín jẹ nípa ẹnikẹ́ni nínú àwọn tí mo rán sí yín bi? Mo bẹ Titu, mo sì rán arákùnrin kan pẹ̀lú rẹ̀; Titu ha rẹ́ yín jẹ bí? Nípa ẹ̀mí kan náà kọ́ ni àwa rìn bí? Ọ̀nà kan náà kọ́ ni àwa tọ̀ bí? Ẹ̀yin ha rò pé àwa ń sọ nǹkan wọ̀nyí láti gbèjà ara wa níwájú yín bí? Ní iwájú Ọlọ́run ni àwa ń sọ̀rọ̀ nínú Kristi; ṣùgbọ́n àwa ń ṣe ohun gbogbo, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, láti gbé yín ró ni. Nítorí ẹ̀rù ń bà mí pé, nígbà tí mo bá dé, èmi kì yóò bá yín gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí mo fẹ́, àti pé ẹ̀yin yóò sì rí mi gẹ́gẹ́ bí irú èyí tí ẹ̀yin kò fẹ́: Kí ìjà, owú jíjẹ, ìbínú, ìpinyà, ìṣọ̀rọ̀-ẹni-lẹ́yìn, òfófó, ìgbéraga, ìrúkèrúdò, má ba à wà. Àti nígbà tí mo bá sì padà dé, kí Ọlọ́run mí má bà à rẹ̀ mí sílẹ̀ lójú yín, àti kí èmi má ba à sọkún nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó tí ṣẹ̀ náà tí kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ìwà èérí, àgbèrè, àti wọ̀bìà tí wọ́n ti hù.