II. Kor 11:3-4
II. Kor 11:3-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn ẹru mba mi pe, li ohunkohun, gẹgẹ bi ejò ti tàn Efa jẹ nipasẹ arekereke rẹ̀, ki a maṣe mu ero-ọkàn nyin bajẹ kuro ninu inu kan ati iwa mimọ́ nyin si Kristi. Nitori bi ẹniti mbọ̀ wá ba nwãsu Jesu miran, ti awa kò ti wasu rí, tabi bi ẹnyin ba gbà ẹmí miran, ti ẹnyin kò ti gbà ri, tabi ihinrere miran, ti ẹnyin kò ti tẹwọgbà, ẹnyin iba ṣe rere lati fi ara da a.
II. Kor 11:3-4 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀rù ń bà mí pé kí ẹ̀tàn má wọ inú ọkàn yín, tí ẹ óo fi yà kúrò ninu òtítọ́ ati ọkàn kan tí ẹ fi wà ninu Kristi, bí ejò ti fi àrékérekè rẹ̀ tan Efa jẹ. Nítorí ẹ̀ ń fi ààyè gba àwọn ẹlòmíràn tí wọn ń wá waasu Jesu yàtọ̀ sí bí a ti waasu rẹ̀, ẹ sì ń gba ìyìn rere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti kọ́ gbà.
II. Kor 11:3-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìhìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.